Ẹ múra o! Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá yóò tẹ̀síwájú títí di Oṣù Kẹjọ - Ìjọba Eko

Aworan

Ijọba ipinlẹ Eko ti ke si awọn ara ipinlẹ Eko lati di ara wọn mu daradara nitori ọjọ arọọrọda yoo tẹsiwaju di osu kẹjọ, ọdun 2022.

Oṣu kẹrin ọdun ni ijọba ti kọkọ fi ikilọ naa lede pe ki awọn araalu miran nitori mita to kun ju ẹgbẹrun kan, 1,750mm ni omi naa yoo jẹ.

Amọ lẹyin iṣẹlẹ omiyale ati agbara ya ṣọọbu to mu ẹmi eniyan lọ ni Ọjọ Satide ni ijọba ọhun tun fi ikilọ miran jade.

Wọn ni oju popo Oko-Oba ti wọn n ṣe lọwọ lo mu ki ọjọ to rọ fun wakati mẹwaa ṣe akoba fun awọn eniyan .

Ijọba ipinlẹ Eko ni ki awọn eniyan ranti pe agbegbe omi ni ipinlẹ Eko

Ijọba ni awọn n ṣe oju ọna naa lati fi opin si agbara ojo to n fa omiyale ni agbegbe naa.

Bakan naa ni wọn rọ awọnm awakọ ati araalu lati ṣe jẹjẹ ti wọn ba n gba agbegbe ti omi nla pọsi nitori ewu to wa nibe.

Ijọba ipinlẹ Eko ni ki awọn eniyan ranti pe agbegbe omi ni ipinlẹ Eko nitori naa ajo yoo pọ nipinlẹ Eko, ti yoo si fa omiyale alailopin.

‘’Gbogbo awọn eniyan to n gbe ni agbegbe to jin si isalẹ gbọdọ ṣọra ni asiko ojo yii nitori yoo tẹsiwaju di Oṣu kẹjọ.’’

Wọn ṣi n wa eniyan meji to sọnu lẹyin ti arọrọda ojo gbe ọkọ wọn lọ ni agbegbe Oko-Oba , Agege, nipinlẹ Eko.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni canal to wa ni agbegbe naa ni ọkọ Lexus ọhun bọ si, ti enikan ninu awọn mẹta to wa ninu ọkọ naa si moribọ, amọ wọn ko ri awọn meji to ku.

Omi gbé èèyàn méjì lọ, àwọn mẹ́ta móríbọ̀ lẹ́yìn òjò àrọ̀rọ̀dá nílùú Eko

Flooding

Oríṣun àwòrán, @AdetayoDaniel12

Eeyan mẹta ti moribọ, nigba ti awọn meji mii di awati lagbegbe Oko Oba, niluu Eko lẹyin ojo arọrọda kan lọjọ Abamẹta.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA sọ pe ẹnikan ninu awọn eeyan naa fo jade lati inu ọkọ ayọkelẹ ti wọn wa, nigba ti awọn oṣiṣẹ awọn yọ awọn meji to ku ninu agbara ojo to n gbe wọn lọ.

Adari ajọ NEMA ni iha Guusu iwọ oorun Naijiria, Ibrahim Farinloye ṣalaye pe apapọ awọn ti awọn doola jẹ mẹrin, amọ wọn ṣi n wa awọn meji mii.

Awọn adoola ẹmi lati NEMA ati ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni pinlẹ Eko, LASEMA, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ajọ panapana lo ṣi n wa awọn eeyan naa ti omi gbe lọ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Irroyin ni awọn eeyan mẹfa naa wa ninu ayọkẹlẹ Lexus ati Toyota lasiko ti agbara ojo ọhun gba ọkọ lọwọ wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Awọn eeyan naa kọti ikun si imọran lati yago fun agbegbe ti omi ti gbe wọn

Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan to wa lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ, wọn ri awọn eeyan mẹta naa yọ nitori awọn mọ agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye daadaa.

Wọn ni awọn ti kọkọ kilọ fun awọn eeyan naa ṣaaju ki wọn ma gba ibi ti wọn gba amọ wọn kọti ikun si imọran awọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Oniruru fidio lo ti n lọ kaakiri lori ayelujara nipa iṣẹlẹ naa ati awọn iṣẹlẹ omiyale mii ni ipinlẹ Eko lẹyin ojo oni ọpọ wakati naa.

Iṣẹlẹ omiyale l’Eko

Kii ṣe igba akọkọ ree ti iṣẹlẹ omiyale yoo waye niluu Eko.

Ni n kan bii ọsẹ meji ṣeyin, ọpọ ile ni omi gba ti ọpọ dukia si ṣofo lẹyin ti ojo rọ fun ọpọ wakati.

Lara awọn agbegbe ti ọrọ naa kan ni Ojodu-Berger, Ikosi-Ketu, Gbagada, Surulere, Ikorodu atawọn agbegbe mii.