Ẹni ọdun 65 rí ẹ̀wọ̀n gbére he lẹ́yìn tó fi ipá bá ìyàwó baba rẹ̀ ẹ̀ni ọdún 85 lọ̀pọ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Ẹni ọdun marundinlaadọrin ti ri ẹwọn gbere he ni ilu Ado Ekiti lẹyin ti wọn fi ẹsun fifi ipa banilopọ kan an.
Agbẹjọro agba, Monisola Abodunde lo ran an lọ si ẹwọn gbere naa lẹyin to ni o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọmọbinrin iya agba ti wọn fi ipa ba lopọ naa lo sọ bi ọrọ ṣe jẹ ni ileẹjọ.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ree...
Ọmọ iya agba naa ni oun lọ gbe ounjẹ fun iya oun ni oun ba ni ibi ti ara rẹ ko ti balẹ.
Iya naa salaye pe ọmọkunrin naa wa si yara rẹ ni aago kan oru, o fi balm kun ni gbogbo ara to fi mọ oju ara rẹ to si tẹ gbogbo ara rẹ.
O ni lẹyin naa lo bẹrẹ si ni mu ọyan rẹ, ko to fi ipa ba lopọ.
Arabinrin naa ni nigba ti oun bere lọwọ ẹni ti wọn fi ẹsun kan naa, ohun to sọ ni pe iya oun la ala ni.
Lẹyin naa ni wọn gbe ọrọ naa lọ si agọ ọlọpaa ni Ido Ekiti ti iṣẹlẹ naa ti waye, ki wọn to gbe e lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ni ilu Ado Ekiti.
Adajọ naa ni ayẹwọ ileewosan to fi mọ ọrọ ẹni ti wọn fipa ba lọpọ fihan pe loot ni iṣẹlẹ naa waye, ti arakunrin naa si jẹbi ẹsun ifipabanilọpọ.
Lẹyin naa lo ran an lọ si ẹwọn gbere.












