Oba Samuel Adeniran Asusumasa Atewogboye II: Alaaye ti Efon Alaaye tí wọ́n yẹgi fún lọ́dún 1949

Ade ọba nilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba ni ẹni ti a ni ko ki ni lẹyin, ko yẹ ko fi ẹgun sọwọ, bẹẹ ni ẹni ti a ni ko fẹ ni loju, ko gbọdọ fi ata sẹnu.

Amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu Ọba alaye kan nilẹ Yoruba, ti araalu fẹyin ti, to ja wọn lẹyin kulẹ, ti wọn gboju okun le, amọ ti ko jọ ẹni agba.

Gẹgẹ bẹẹ se mọ pe alasẹ ekeji orisa ni awọn Ọ́ba alaye nilẹ Yoruba, awọn si ni araalu ri bi igbakeji orisa, ti wọn gbọkan wọn le.

Sugbọn nilu Efon Alaaye, eyi ko ri bẹẹ o, gẹgẹ bi a se ri ka loju opo itakun agbaye nigba ti Ọba alaye ibẹ ja awọn eeyan rẹ kulẹ, to si ja igbẹkẹle ti wọn ni ninu rẹ si asan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ki lo sẹlẹ nilu Efon Alaaye lọdun 1949?

Ọjọ nla ni ọjọ Kẹwaa, osu Kinni, ọdun 1949 nigba ti isẹlẹ nla kan waye nilu Efon Alaaye, to wa nipinlẹ Ekiti bayii

Ọmọdebinrin kan to n jẹ Adediwura Adejolu Ojo ọmọ Abaluo, tii se ọmọ ọdun kan ati osu mẹta, lo saadede poora ninu agbala baba rẹ to ti n sere ni adugbo Ilu gbeku.

Ere ni, awada ni, wọn wa ọmọ naa titi, ti ilẹ fi su, amọ wọn ko ri eegun tii jẹ Ajikẹ, iya Adediwura sunkun titi, oju ni oun ko ran-an nisẹ.

Baba rẹ naa atawọn ọrẹ pẹlu aladugbo gan an gbarata, wọn daamu, ikun imu ọtun wọn bọ si toi si, amọ ofuutu-fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kahun ni gbogbo wahala rẹ.

Koda, wọn mu isẹlẹ naa to Ọba Alaaye tilu Efon Alaaye leti nigba ti aayan wọn lati wa ọmọ naa ni gbogbo arọko to sunmọ wọn ja si pabo.

Bakan naa, Ọba Samuel Adeniran Asusumasa Atewogboye keji, Alaaye tilu Efon Alaaye lasiko naa, tun gbe awọn gende dide lati wa Adediwura, sugbọn ẹja ni ọrọ naa, kii se akan rara.

Lasiko ti a n sọrọ rẹ yii, awọn eebo amunisin lo n dari akoso ilẹ yii, ko si si ohun to n jẹ orilẹ-ede Naijiria, ti ileesẹ ọlọpaa si wa labẹ akoso wọn.

Abẹ akoso Ọba Gẹẹsi, King George IV la wa, ti ko si si ẹni to ga ju ofin lọ nigba naa, Lloyd Crow si lo n soju awọn eebo fun igbẹjọ.

Wọn fi ọrọ naa to awọn ọlọpa leti, tawọn naa si fi isẹlẹ ọhun to olu ileesẹ wọn leti nitori igba akọkọ ree ti iru isẹlẹ ijọmọgbe bẹẹ yoo waye.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Iwadii ti ileesẹ ọlọpaa se lati se awari bi Adediwura se poora:

Ọrọ yii ko lojutu titi di ọjọ Kẹwaa, osu Keji, ọdun 1949, iyẹn nigba to pe osu kan gbako ti Adediwura poora.

Ọjọ naa si ni awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ mẹrin, ti orukọ wọn n jẹ Insipẹkitọ Aruah, Sajẹnti Olawaiye ati Sule Agbabiaka pẹlu Kọburu Ariyo ya bo ilu Efon Alaaye lati finmu-finlẹ nipa ibi ti Adediwura wọlẹ si.

Laarin ọjọ meji pere, awọn ọlọpaa to dantọ naa fidi rẹ mulẹ pe awọn afọmọ setutu lo gbe ọmọde yii lọ.

Nigba ti yoo si fi di ọjọ Kẹrinla, osu Keji, ọdun 1949, okiki ọrọ naa ti gba ilu kan, tawọn iwe iroyin si ti kede rẹ, bẹẹ ni ijọba eebo tutọ soke, foju gbaa, lori isẹlẹ laabi naa.

Nigba ti iwadii wọn tẹsiwaju, paapaa lori awọn akinkanju oloogun to wa ninu ilu naa, ọwọ tẹ awọn Babalawo mẹta.

Orukọ awọn onisegun ọhun ni Daniel Ojo, Enoch Falayi ati Gabriel Olabinrinjo, Falayi si lo jẹ babalawo si Alaaye tilu Efon naa.

Nigba to di osu Kẹrin, ọdun 1949, igbimọ olugbẹjọ dide ni gbọngan Obokunbusi to wa nilu Ilesa, eyi ti adajọ Majisireti WO Egbuna ko sodi.

Ọrọ ko pariwo rara nigba ti ọkan lara awọn afurasi to wa ni ahamọ ọlọpaa lori isẹlẹ yii ka boroboro nipa ohun ti wọn se, ti ile fi jona.

Àkọlé fídíò, Lady Mechanic: Ajayi Oluwatosin ní a kò nílò láti ṣe yẹsà fún ẹnikẹ́ni, ká tó débi gíga

Alaye aṣiri tu nipa bi Adediwura se di awati ree:

Bi ọkan lara awọn afurasi naa se tu asiri yii, ni awọn iwadii miran ati ọpọ asiri miran bẹrẹ si ni tu nipa bi ọmọde naa se di awati.

Iwadii fihan pe babalawo Falayi to n kọja lọ, lo ri Adediwura nibi to ti n sere ninu agbala baba rẹ.

Nigba to si wo firi, ti ko ri ẹnikẹni nitosi, lo ba he ọmọ naa lapa, to si gbe e bọ abẹ agbada rẹ lọ sile rẹ.

Falayi pasẹ fun iyawo rẹ nigba to dele pe ko pọn ọmọ naa sẹyin lọ sile ẹnikan to darukọ fun-un.

Amọ nigba ti wahala wiwa ọmọ naa peleke, Falayi tun gbe Adediwura kuro nibẹ, to si gbe e lọ sile Ọba Asusumasa Atewogboye.

Aafin ọba naa si ni wọn ti kun ọmọde naa bii ẹni kun ẹran, lati fi se etutu fun Ọba Alaaye.

Wọn yọ oju ọmọ naa mejeeji, pẹlu ahọn rẹ, wọn ko o sinu agolo siga, ti wọn si kun iyoku ara ọmọ naa wẹlẹwẹlẹ.

Lẹyin eyi ni ọkọọkan awọn eeyan to sisẹ ibi naa wa bura pe ki ilẹ gbe ẹnikẹni to ba tu asiri awo to wa laarin wọn mi.

Wọn gbe oku ọmọ naa lọ sinu igbo kijikiji to wa lẹba ile ijọsin CMS, ti wọn si sin in nibẹ.

Àkọlé fídíò, Alhaji Weds Prophetess: Tọkọtaya tó jẹ́ Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì ṣe àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó

Igbẹjọ ati idajọ iku fun awọn ọdaran ajọmọgbe:

Ọkan lara awọn ẹlẹrii ninu igbẹjọ yii ni Aina Ola, ẹni to fọwọ gbaya pe Falayi lo ji Adediwura gbe sabẹ agbada rẹ.

Bakan naa ni ọkan lara awọn ẹlẹrii tọka si Ọba Asusumasa Atewogboye pe, oun lo ran wọn nisẹ ipaniyan naa, ti wọn si lọ mu Ọba si atimọle lọgan.

Wọn gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ giga tilu Akure labẹ adajọ NS Pollard, ti awọn ẹlẹrii mọkanlelogun si yọju siwaju rẹ.

Bakan naa ni iyawo babalawo yii, Owomobi jẹrii pe inu ile awọn ni ọmọde naa wa titi di aajin, ti ọkọ oun kan an nipa fun oun lati pọn ọmọ naa sẹyin lọ sile afurasi keji, Gabriel Olabirinjo.

Agbẹjọro fun Ọba Asusumasa Atewogboye ni Oloye Obafemi Awolowo nigba ti Bode Thomas jẹ agbẹjọro fun ikọ olujẹjọ yoku, tii se awọn babalawo.

Awọn mejeeji ja fitafita lati jẹ ki ẹjọ ọhun gbe awọn onibara wọn, amọ awọn ẹri to wa niwaju ile ẹjọ fihan pe ẹpa ko boro mọ.

Asẹyinwa-asẹyinbọ, ileẹjọ kede pe Kabiyesi Ọba Samuel Adeniran Asusumasa Atewogboye Keji, Alaaye kẹtalelogoji nilu Efon Alaaye ati babalawo rẹ, awọn iransẹ ati Gabriel Olabinrinjo jẹbi ẹsun ijọmọgbe ati ipaniyan.

Ileẹjọ ni ki wọn yẹgi fun gbogbo wọn, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara wọn, ọdun 1949 si ni awọn ọdaran naa dagbere faye.

Àkọlé fídíò, Orisabunmi Olasanya: Pásítọ̀ àti Alfa ń wá ṣe òògùn lọ́dọ̀ bàbá mi

Ẹ́kọ́ wo la ri kọ́ nipa isẹ̀lẹ̀ yii?

Ọ́pọ́ igba lo maa n jẹ pe awọn ti a ba gbọkan le kii gba eeyan duro nitori ibi ti a ba foju si, ọna le ma gba ibẹ lọ.

Igba miran, eni to ba n fẹ eeyan kan le maa se oju aye lasan to jẹ pe o n fi ẹjẹ sinu tu itọ funfun sita ni.

Ifura ni oogun agba titi di aye ode oni, gbogbo igba ni ki a maa gbọ ohun ti ara ba n sọ fun wa.

Asiko ti to ki igbẹjọ maa lọ bi o ti yẹ lai segbe fun ẹnikẹni ni Naijiria mọ́.

Ofin ti a ba tori ẹru se ni a ko gbọdọ de ori ọmọ ki a wa yii pada.

Ati pe ika to ba sẹ̀ ni ki agbara ofin maa ge lai bọwọ fun ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, So Láyà: Mr Latin, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kópa nínú ìdánwò nípa àṣà àti èdè Yorùbá