Alhaji Weds Prophetess: Tọkọtaya tó jẹ́ Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì ṣe àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó

Àkọlé fídíò, Alhaji Weds Prophetess: Tọkọtaya tó jẹ́ Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì ṣe àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó

Ni orilẹede Naijiria, lemlemọ ni ija ẹsin maa n waye laarin awọn Musulumi, Kiristẹni atawọn ẹlẹsin ibilẹ, eyi to maa n mu ẹmi lọ.

Bi o tilẹ jẹ pe asamọ ọrọ Yoruba kan lo ni ẹsin ko fa ija, amọ ọpọ awọn eeyan ni kii fẹ ki ọmọ wọn lọkunrin tabi lobinrin fẹ ẹlẹsin ti kii ba se ẹsin tiwọn.

Sugbọn iyalẹnu nla lo jẹ lati pade awọn baba ati iya agba ti wọn ti gbe papaọ ninu idile alayọ fun odidi aadọta ọdun ninu igbeyawo.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba fọrọ wa Alhaji àti Wòlíì Jamiu àti Fadekemi Olaleye lẹnu wo, awọn mejeeji si jẹ tọkọtaya tó jẹ́ Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì.

Koda, Wolii obinrin to da ijọ silẹ ni iyawo nigba ti ọkọ si jẹ agba Musulumi.

A fẹ́ mọ bí wọn ṣe gbé papọ̀ láì náání ìyàpa ẹ̀sìn ikọọkan wọn fún àádọ́ta ọdún nínú ìgbéyàwó.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn mejeeji ni ọjọ kẹfa osu kinni ọdun 1972 ni awọn se igbeyawo, eyi to ti le ni ọdun mọkanlelaadọta bayii.

Bakan naa ni wọn salaye bi wọn se pade ati iha ti obi ikọọkan wọn kọ si ọrọ ifẹ wọn.

Nigba ti wọn n sọrọ lori ihuwasi wọn nidi ẹsin, tọkọtaya naa ni awọn maa n karamaasiki ara awọn ti ọdun Kristiẹni ati ti Musulumi ba de.

"Imaamu Mọsalasi lo kọkọ wa sure fun wa lọjọ ti a ba n se ajọdun ni sọọsi, ti inu awọn ọmọ wa si maa n dun lasiko Ileya ati Keresimesi.

Bi emi ba lọ fun adura owurọ ni sọọsi, ọkọ mi yoo lọ kirun aarọ ni Mọsalasi.

Ẹsin ko fa ija nile wa fun aadọta ọdun ta ti n gbe papọ."