Àràmàǹdà tíṣà kan rèé tó ń fi èdè Yorùbá kọ́ ìmọ̀ ìṣirò "Mathematics" lórí ayélujára

Àkọlé fídíò, Hakeem Adeniran Yoruba Maths: Ìdí ti mo fi bẹ̀rẹ̀ sí ni kọ́ ìsìrò pẹ̀lú èdè Yorùbá nìyí.
Àràmàǹdà tíṣà kan rèé tó ń fi èdè Yorùbá kọ́ ìmọ̀ ìṣirò "Mathematics" lórí ayélujára

Báwo ni ìṣirò yìí: y=7x (g) y =15 ṣe jọ mọ́ èdè Yorùbá rẹ̀ tí tísà sọ, “Ìwáfàyọ”? 🤷‍♀️🤷‍♀️🤦‍♀️.

“Ifẹ to lagbara ti mo ni si ede Yoruba yala ni kikọ ni o ati ni sisọ, lo mu mi ti mo fi bẹrẹ igbesẹ yii”.

Hakeem Adeniyi to jẹ ọmọ ipinlẹ Ekiti ati olukọ imọ isiro ti gbe ilana to n gba kọ ẹkọ naa de ipele giga nipa fifi ede abinibi rẹ, Yoruba kọ isiro.

“Ẹ ni ti ko gbọ ede gẹẹsi, ti mo ba sọ fun un pe 3 ¼ abi “three quartre”, o le maa ronu ko ma tete yee pe ki lo n jẹ bẹẹ”.

Hakeem sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba pe iru ifẹ ti oun ri nipa fifi ede Yoruba kọ imọ isiro lagbara gan.

Hakeem Adeniyan

Ó jọ àwọn èèyàn lójú bí mo ṣe ń fi èdè Yorùbá kọ́ "Mathematics" lórí ayélujára - Tísà Hakeem Adeniyan

Hakeem ni oun gbagbọ pe kikọ imọ isiro pẹlu ede abinibi yoo jẹ o rọrun lati kọ ati pe yoo tun ran akẹkọọ lọwọ lati tete mọ ọ ti ọpọlọ rẹ ṣi nipa imọ ẹkọ ti wọn ti ro pe o nira fun awọn akẹkọọ lati mọ.

Bakan naa, Hakeem mẹnu le awọn ipenija to n koju nipa igbesẹ to gbe yii lati jẹ ko di itẹwọgba kaakiri agbaye.