Naira Marley àti Sam Larry fojú balé ẹjọ́, wọn yóò wà ní àhámọ́ ọ́gbà ẹ̀wọ̀n f‘ọ́sẹ̀ mẹ́ta

Naira Marley ati Sam Larry n jade nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Naira Marley àti Sam Larry fojú hàn nílé ẹjọ́, wọn yóò wà ní àhámọ́ ọ́gbà ẹ̀Àwọn èèyàn méjì tí ẹnu ń kùn lórí ikú gbajúmọ̀ akọrin takasufe nnì, Ilerioluwa Aloba, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Mohbad, tí fojú ba ilé ẹjọ́ loni.

Àwọn afurasi mejeeji naa ni gbajúmọ̀ akọrin takasufe kan, tí Mohbad gbé àwo orin ni iléeṣẹ́ rẹ, Azeez Fashola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Naira Marley.

Ẹni kejì ni gbajúmọ̀ kan n'ilu Eko ti orúkọ rẹ ń jẹ Samson Balogun Eletu, ti wọn tún ń pè ní Sam Larry, ẹni to sunmọ Naira Marley pupọ.

Ọsẹ to kọjá ní Sam Larry de láti oke okun to lọ, ti ọwọ́ ọlọ́pàá si tẹ ẹ, tí wọn sì fi sì àhámọ́ fún ifọrọwanilẹnuwo.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá beere fun ọjọ mọkanlelogun láti ṣe iwadi lọwọ Naira Marley ati Sam Larry nipa ikú tó pa Mohbad

Àmọ́ alẹ ọjọ Isẹgun ni Naira Marley de si Naijiria lati ilu London to wa, tó sì lọ jọ̀wọ́ ara rẹ silẹ fún àwọn ọlọ́pàá.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nipinlẹ Eko lo ti pe ẹjọ́ lọ siwaju ile ẹjọ magisireti to wa ni Yaba n'ilu Eko, ti wọn si n rọ ile ẹjọ naa lati fun awọn ni àṣẹ láti fi àwọn méjèèjì àhámọ́ fún ọsẹ mẹta gbáko.

Akoko yii ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní òun yóò lo láti fi ṣe iwadi ti oun gunle, lọ́nà àti mọ irú ikú tó pa Mohbad.

Nigba to n gbe àṣẹ rẹ kalẹ, adajọ Magisireti Adeola Olatunbosun pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fi àwọn méjèèjì naa si àhámọ́ fún ọjọ́ mọ́kànlélógún gbáko

À ń wá Primeboy lórí ikú Mohbad, N1m ni á fún ẹni tó bá sọ ibi tó wà fún wa - Ọlọ́pàá

Mohbad ati Primeboy

Oríṣun àwòrán, Collage

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti kede pe oun n wa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ ń jẹ Ibrahim Owodunni, tí inagijẹ rẹ ń jẹ Primeboy.

Ìkéde kan tí agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fisita lójú òpó X rẹ lo ṣàlàyé bẹẹ.

Atẹjade náà ni ìkéde Primeboy gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí àwọn ọlọ́pàá lo nii ṣe pẹlu ikú gbajúmọ̀ akọrin takasufe nnì, Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sì Mohbad.

Atẹjade náà fikùn pé iléeṣẹ́ olopa ti ránṣẹ́ pé Primeboy ni àìmọye ìgbà láti yọjú sì wọn, kò le sọ tẹnu rẹ lórí ikú Mohbad àmọ́ tó kọ, tí kò yọjú.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìdí rèé tí òun ṣe kéde pé òun ń wá Primeboy náà.

Mohbada ati atẹjade ileesẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @BenHundeyin

Atẹjade náà wá kéde mílíọ̀nù kan Naira gẹ́gẹ́ bíi owó ẹ̀bùn fún ẹnikẹ́ni tó bá lè tú àṣírí ibi tí Primeboy wá fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá.

"Primeboy jẹ ọkùnrin tó ga níwọ̀n ẹ̀ṣẹ bàtà 1.64, ó dúdú, tó sì ni ìlà kọọkan lójú, ó sì jẹ ọmọ bibi ilẹ̀ Yorùbá.

Ẹnikẹni to bá rí, kò kan sì agọ ọlọ́pàá tó bá sùn mọ itosi rẹ tàbí kó pé nọ́mbà fóònù yii: 08036885727.

Bakan naa ni kọmisana ọlọ́pàá nipinlẹ Eko, Idowu Omohunwa kéde ẹ̀bùn owó mílíọ́nù kan Naira gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀bùn fún ẹnikẹ́ni tó bá mọ bí a ṣe le è rí.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ta ni Ibrahim Owodunni tó ń jẹ Primeboy tí ọlọ́pàá ń wá, báwo ló ṣe jẹ́ sí Mohbad?

Ibrahim Owodunni

Oríṣun àwòrán, primeboynewz1/Instagram

Akọrin takasufe ni Ibrahim Owodunni tó ń jẹ Primeboy tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde pé àwọn ń wa.

Kódà, ọrẹ timọtimọ lo jẹ pẹlu Mohbad láti ìgbà kekere, tí wọn sì di jọ máa ń tẹle ara wọn kiri.

Kódà, Primeboy lo ṣe fídíò láti kọ́kọ́ kéde ikú Mohbad lọ́jọ́ tí Mohbad kú.

Ti ẹ kò bá gbàgbé, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ní Mohbad jáde láyé, tí ikú rẹ̀ sì ti ń fà awuyewuye yíká Naijiria ati lókè òkun.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sì ti gbé ìgbìmọ̀ oluwadi kan kalẹ láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú Mohbad náà, tí ìgbìmọ̀ náà sì ti ránṣẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn láti wá sọ tẹnu wọn lórí ikú akọrin náà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn sì lọ ń naka ẹ̀sùn sì Primeboy pe o gbọ́dọ̀ mọ nípa ohun tó pá Mohbad.

Primeboy sì ṣe fídíò miran síta lẹ́yìn náà pé ọrẹ kori-kosun òun ni Mohbad, òun kò sì le ṣe ijamba fún láéláé.

Àmọ́ títí di àkókò yìí, Primeboy ko tii yọjú sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti sọ ohun tó mọ nípa ikú ọrẹ rẹ náà, Mohbad.

Naira Marley ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ikú MohBad

Aworan Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Naira Marley/X

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe olorin takasufe Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ti wa ni ahamọ wọn fun ifọrọwanilẹnuwo lori iku Mohbad.

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ṣalaye sọ loju opo X rẹ pe Marley yoo sọ tẹnu rẹ lori ohun to mọ nipa iku Mohbda.

Mohbad ku ni ọjọ kejila oṣu kẹsan an ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Iku ọdọmọde olorin naa ni o dun awọn ọmọ Naijiria gan an eleyii ti wọn si ti n pe fun idajọ ododo lori ohun to ṣe iku pa a.

Ọpọ lo si ti n pe fun Naira Marley lati wa wu tẹnu rẹ latari wi pe ileeṣẹ rẹ Marlian records ni Mohbad wa tẹlẹ.

Ṣaaju lọjọ Iṣẹgun kan naa yii ni Naira ti kọkọ sọrọ loju opo ayelujara X rẹ ti ọpọ mọ si Twitter tẹlẹ pe oun ti de lati irinajo pada si ilu Eko.

O ni oun ṣetan lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ pẹlu iwadii ti wọn n ṣe lori iku to pa ọdọmọde olorin Mohbad to di oloogbe.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

''O ṣe pataki fun mi lati ṣe ipa temi naa fun Imole.

Mo maa sẹ ipade pọ pẹlu awọn ọlọpaa pẹlu igbagbọ pe eleyii to jẹ otitọ ati ododo yoo farahan lori iku Mohbad,'' Naira Marley lo ṣalaye bẹẹ.