Èèyàn 20 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi tó dojúdé lójú agbami ní Kebbi

Aworan awọn adoola ẹmi loju agbami

Oríṣun àwòrán, Bala Yauri

Igbesẹ ati doola ẹmi awọn eeyan to ri sinu omi lẹyin ti ọkọ oju omi ti wọn wa dojude ni ipinlẹ Kebbi, lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria ṣi n lọ kikankikan bayii.

Gẹgẹbi ọrọ ti ijọba ipinlẹ Kebbi sọ, eeyan mẹtalelogun ni wọn ti fi idi rẹmulẹ pe wọn ti ku lẹyin ti kọ oju omi naa dojude lọjọ Aje

Ontaja lwọn ero inu ọkọ oju omi naa, ọja lọsọọsẹ, Yauri ti wọn maa n na lọjọọjọ Aje ni wọn si n fẹ lọ na nigba ti ijamba naa waye.

Igba kẹta niyi ti irufẹ iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi lọpọ ero bayii yoo maa waye lẹyin ti meji miran waye ni nnkan bi oṣu kan sẹyin ni ipinlẹ Niger.

Atẹjade kan lati ọdọ ijọba ipinlẹ naa ṣalaye pe, “Awọn ero kọ naa gbera ni ileto Kasabo lọ si Yauri lati na ọja ki ijamba naa to waye.”

“A ko lee da Ọlọrun lẹbi, ṣugbọn a ba mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun, a si tun gba adura fun ẹmi wọn lati ri isinmi.”

Ijamba idojude ọkọ oju omi loju agbami ko ṣajeji si Naijiria.

Ero akoju jẹ ọkan gboogi lara awọn ohun to n ṣokunfa ijamba kọ oju omi.

Ni oṣu kẹwaa dun 2022, eeyan mẹwaa lo jade laye lẹyin ti ọkọ oju omi kan to yẹ ko gbe eeyan mejidinlaadọta lọ gbe eeyan marundinlaadọrun to si ko ijamba oju omi ni Onitsha ni ipinlẹ Anambra.

Ọjọ Keje oṣu kẹwaa ni ijamba naa waye.