Wo bí iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì ṣe gbẹ̀mí ọkọ, ìyàwó pẹ̀lú ọmọ méjí ní Taraba

Raymond Nfonnbok iyawo ati ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Raymond Nfonnbok

Ina ẹlẹntiriki ti ran Baba, iya atawọn ọmọ meji lọ sọrun alakeji ni ipinlẹ Taraba.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to fi idi rẹ mulẹ pe idile ẹlẹni mẹrin naa nnkan bii aago mẹsan aarọ, ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Dinyawo niluu Jalingo.

Ohun ti a gbọ ni pe o ti pẹ diẹ ti ko ti si ina mọnamọna lagbegbe naa ki wọn to tun mu u de ni ọjọ Aje.

Lọgan ti ina naa de, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni ẹrọ amunawa tiransifọma agbegbe naa lana lojiji, to si ṣe akoba fun ọpọ ile to wa lagbegbe ọhun.

Eyi lo si pada gba ẹmi idile ẹlẹni mẹrin ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Wọnyii ni ohun ti Arabinrin Gambo Tibwa to jẹ alamulegbe Raymond Nfonnbok ba akọroyin BBC sọ lẹyin ti idile ẹlẹni mẹrin naa gan mọ ina lọjọ Aje.

Raymond lo kọkọ ṣekil fawọn aladugbo nipa ina lile ti ileeṣẹ amunawa mu wa

Awọn mọ tọkọtaya nnfonnbok

Oríṣun àwòrán, Raymond Nfonnbok

Raymond Ofonbuk, ẹni ọdun mẹrinlelogiji to jẹ baba; Mfonbong iyawo rẹ; awọn ọmọ wọn, Hevean Raymond, ọmọ ọdun mẹẹdogun; ati First Raymond, toun jẹ ọmọ ọdun mẹtala ni awọn mẹrin to ba iṣẹlẹ ijamba ina mọnamọna ọhun lọ.

Obinrin naa sọ pe nigba ti ina mọnamọna kọkọ de ni nnkan bi aago mẹwaa aarọ, Raymond lo kọkọ sare jade, to si n pariwo pe ki gbogbo araale pa ina ati gbogbo ohun to n lo ina ninu ile wọn, nitori pe ina ti wọn mu de lewu pupọ.

Gambo jẹ ko di mimọ pe ko pẹ ti Raymond pada sinu yara rẹ ni awọn gbọ ti ẹrọ amunawa tiransifọma dun ‘gbau’, to si gbina.

“A pariwo Raymond titi, ko si ẹnikẹni to da wa lohun. Igba to ya la n gbọ ti abigbẹyin wọn n pariwo ‘mama mi, mama mi’. Bayii l’awọn eeyan ṣe lọ ja ilẹkun wọ inu ile wọn. A ba oku Raymond, iyawọ rẹ, atawọn ọmọ wọn meji ninu yara.”

Obinrin kan lo jẹ ka mọ pe abigbẹyin awọn oloogbe yii ko si ninu yara lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, idi ree ti ori fi ko o yọ lọwọ iku ojiji.

Ko si ẹni lee sọ ohun to ṣokunfa ijamba ina naa ni pato

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aladugbo ati ileeṣẹ ọlọpaa ni ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ohun gan to fa ijamba iku ina naa.

Arabinrin Gambo ni o ko jẹ pe Raymond lo gan mọ ina pẹlu ẹrọ kọmputa alagbeeka to wa lori ẹsẹ rẹ, ko si wa jẹ pe asiko ti iyawo ati awọn ọmọ n gbiyanju lati doola ẹmi rẹ ni awọn naa gan pẹlu, nitori pe ẹgbẹ ara wọn ni awọn mẹrẹẹrin wa.

Ṣẹgun ni latigba naa ni Mfon ti n ba Raymond sọrọ lati maa gbe nibẹ nitori awọn nnkan amuṣọrọ toun ba pade nibẹ, to si ni idi pataki niyẹn ti Raymond naa fi gba lati darapọ nibẹ.

“Ṣọọṣi International Praise Chapel Church Jalingo ni wọn ti ṣe igbeyawo. Igba to ya ni wọn lọ darapọ mọ ijọ Living Faith Church, ko to tun di pe wọn bẹrẹ sii lọ si Grace and Truth Liberation Ministry aka Carpenter's House to wa ni inu ọgba Nigeria Labour Congress House, Mile Six.”

BBC gbọ pe iṣẹ ayaworan ati fọnran ni Raymond n ṣe, to si tun n ṣe awọn to n fi ọwọ ya aworan. Ileeṣẹ rẹ lo pe ni Rayfons Galleria, ko to di pe o jade laye.