A kò fẹ́ ọlọ́pàá mọ́! Aráàlú faraya lẹ́yìn tí àwọn ajínigbé pa èèyàn nílùú Alalubosa
Awọn ajinigbe kọlu ilu Alalubọsa ni ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti ṣe ọpọlọpọ ọṣẹ nibẹ.
Nigba ti iji ọṣẹ wọn yoo fi dawọ duro, eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ ti ọpọlọpọ miran si tun fi ara pa yannayanna.
Ohun ti awọn olugbe naa sọ ni pe nnkan bii agogo mẹwaa alẹ ni awọn oniṣẹ ibi naa wọ ilu naa pẹlu ibọn atamatase AK47.
Gẹgẹbi alaye ti wọn ṣe, wọn ni iwo awọn to ṣe ikọlu naa jọ ti awọn Fulani.
Ibọn ti awọn ajinigbe naa n yin kaakiri , la gbọ wi pe, o ba eeyan mẹta kan to joko sita n gba atẹgun lalẹ ọjọ buruku eṣu gbomimu naa.
Ọkan ninu awọn ti ibọna ba naa ti orukọ rẹ njẹ Abdulrasheed pada jade laye.
Awọn meji yoku wa ni ile iwosan ti wọn n gba itju bayii.
Bakan naa lọpọ miran tun fara ṣeṣe loni ran an ran lori iṣẹlẹ naa.
‘Awọn ọlọpaa ko wulo fun wa mọ’
Awọn olugbe ilu naa ṣalaye pe ni kete ti ikọlu naa n waye lawọn ti fi ipe ranṣẹ si awọn agbofinro ṣugbọn ti wọn ni ṣe ni wọn n fi gbigbọ ṣe alaigbọ fun awọn.
Wọn ni awọn fijilante lawọn araalu wa pe to wa koju awọn ajinigbe naa. Nigba ti wọn yoo si fi de ibẹ wọn dana ya awọn ajinigbe naa ti ọwọ wọn si tẹ ọkan ninu wọn.
Isiak Abdulahi to ba BBC sọrọ ṣalaye pe ‘awọn ọlọpaa ko wulo fun awọn mọ lori ọrọ abo lagbegbe naa’
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi rọ awọn eeyan agbegbe naa lati fi iye denu.
O ni ọlọpaa n gbiyanju lori ọrọ abo nibẹ, ‘kii ṣe pe awọn ọlọpaa mọọmọ maa fẹ tete de.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara naa ṣalaye pe aitete mọ agbegbe ti ilu Alalubọsa wa, jijina ilu naa si agọ ọlọpaa agbegbe ọhun, ati pe ko si ọkọ to to oju iwn fun awọn ọlọpaa lagbegbe naa.



