Àwọn ọ̀rẹ́ ló kọ́ mi láti fa ìfàkufà lásìkò tí ìṣòro dé, mo sì kábàámọ̀ - Toyin Abraham

Àkọlé fídíò, Toyin Abraham: Ìgbà kìí ṣábà dùn fáwa òṣèré, tí kọ́bọ̀ kò sì ní sí lọ́wọ́ wa, à ń jẹ ìyà
Àwọn ọ̀rẹ́ ló kọ́ mi láti fa ìfàkufà lásìkò tí ìṣòro dé, mo sì kábàámọ̀ - Toyin Abraham

Gbajumọ osere tiata ni ede Yoruba ati Oyinbo ni Toyin Abraham jẹ, to si jẹ ẹni ti o lokiki lawujọ, paapaa ni ẹka amuludun ilẹ wa.

Toyin Abraham ti wa ba BBC Yoruba sọrọ lori igbe aye awọn osere tiata, isẹ tiata lapapọ, bo se nira lati tọ awọn ọdọ si oju ọna ati awọn ohun to ti la kọja sẹyin.

Toyin Abraham, ti ọpọ ololufẹ rẹ n pe ni Mama Ire salaye pe oju oun ti ri to lagbo tiata, o si ni ọpọ iriri naa ko ni ko se fi ẹnu sọ.

Bakan naa ni o tun salaye nipa awọn sinima to nira fun pupọ lati kopa nitori awọn ohun ti oju rẹ ri nibẹ.

Toyin Abraham

“Igba kii fi gbogbo ara dun fun awa osere, A n jẹ sanabọn iya”

Nigba to n sọrọ lori oju ti ọpọ araalu fi maa n wo awọn osere tiata pe olowo ni wọn, Toyin Abraham ni eyi ko ri bẹẹ rara.

Toyin ni nigba miran, kii se gbogbo igba ni owo maa n wa lọwọ awọn, koda, igba miran wa ti awọn kiini kọbọ lọwọ.

O ni ọpọ awọn osere lo n jẹ sanabọ iya sugbọn nitori pe ọ̀pọ eeyan mọ awọn ni wọn se n fi oju olowo wo awọn.

“A maa n mu ki aworan wa dun wo, lati jẹ oju ni gbese ni, tawọn eeyan yoo si ro pe asọ olowo nla la n wọ.”

Eyi si lo ni o mu ki wọn maa fi oju ọlọrọ wo awọn.

Bakan naa lo fi kun pe o ti pe ogun ọdun ti oun ti n sisẹ tiata amọ ko tii pe ọdun mẹfa ti oun n ri owo ninu isẹ naa.

“Awọn ọrẹ ti mo ni kọ mi lati maa fa ifakufa lasiko isoro, mo ti se awọn nnkan kan ti mo kabamọ”

Toyin Abraham tẹsiwaju pe oun ni awọn iriri kan ti ko se fẹnu sọ lagbo tiata, ti oun si ti se awọn nnkan ti kii se ẹjọ oun.

“Awọn ọrẹ mi kọ mi lati maa fa orisirisi ifakufa nigba ti isoro de amọ kii se ẹjọ mi.

Aimọye nnkan miran ti n ko le sọ nitori o le bi ibikubi jade.

Inu mi ko dun si igbe aye mi lakoko naa nitori idile onigbagbọ ni mo ti wa.”

Bakan naa lo fikun peo nira lati pe ọmọ to ba n fa ifakufa pada pẹlu imọran lasan amọ ki awọn obi maa gbadura, ki wọn si maa tọ awọn ọmọ naa sọna.

O tun ni oun kabamọ pe oun ya tatoo si ara oun eyi ti oun fẹ nu danu nitori o tako ẹsin igbagbọ.

Toyin Abraham

“Sinima Elevator Baby, Ijakumọ ati Malaika lo gbo mi julọ, mo n sunkun laidakẹ ninu Malika nitori idaduro ọrọ ọmọ bibi”

Gbajumọ osere tiata naa salaye pe awọn sinima mẹta kan lo mi oun lomi julọ lati igba ti oun ti n sisẹ tiata.

Awọn sinima naa ni Elevator Baby, Ijakumọ ati Malaika.

“Mo ni oyun osu mẹj nigba ti mo bawọn kopa ninu sinima Elevator Baby yii amọ wọn tọju mi.

Sugbọn nigba ta n ya sinima Malaika ti ko ni pẹ jade yii, se ni mo n sọkun laidakẹ, ti wọn ba ti ni ka bẹrẹ ere sise naa.

Idi ni pe oun to ti sẹlẹ si mi ri ni eyi to nii se pẹlu idaduro ọmọ bibi, ọpọ obinrin si lo n la iriri naa kọjha lai ri ohun ti wọn le se si.”

“Omotola Jolaade Ekeinde ni Awokọse mi lagbo tiata, o ni ọkọ, o bimọ, igbeyawo rẹ ko si daru”

Toyin Abraham salaye pe ni Naijiria , agba osere tiata lobinrin, Omotola Jolaade Ekeinde ni awokọse oun amọ ni agbaye, Angelina Jolie ni.

Osere tiata naa ni oun fi Omotola, ti ọpọ eeyan mọ si “Omo Sexy” se awokọse, ti oun kii si tiju lati sọ fun ọpọ eeyan.

“Omotola ni idile alayọ, o ni ọkọ, o tun bimọ, bi emi naa se fẹ niyi nitori isẹ kekere kọ ni ki eeyan jẹ gbajumọ osere tiata, ko si tọju awn ọmọ lai yawọ.