Ladoja yarí kanlẹ̀ láti ṣàmì ọjọ́ ìbí rẹ̀ bó ṣe pé ẹní ọdún 79 lónìí

Oríṣun àwòrán, Rashidi Ladoja
Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, ti o tun jẹ Ọtun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Rashidi Ladoja, ti fi ọrọ ranṣẹ si ẹbi, ara ati ọrẹ rẹ wi pe ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi fun un lonii ti o pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin.
Saaju asiko yii, lọdọọdun ni ọpọlọpọ awọn eeyan maa n korajọpọ si ile Oloye Ladọja to n bẹ ni 'Ondo street', ni agbegbe Bodija ni gbogbo ọjọ kẹẹdọgbọn ọṣu kẹsan an ọdun, lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi fun eekan oloṣelu naa.
Lati nnkan bii ọdun mẹrindinlogun ti o ti fi apere ijọba silẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo, ni ọpọlọpọ ero ti maa n lọ si ile Ladoja lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi lọdọọdun.
Sugbọn ti ọdun yii yatọ nitori ọlọjọ ibi ni ki ẹnikẹni ma ba oun ṣe ajọyọ lọdun yii.
Alaye ti Gomina tẹlẹri naa ṣe ni pe, ko si ohun ti oun fẹ ṣe ajọyọ ọjọ ibi fun pẹlu bi ọpọlọpọ ọmọ orilẹede Naijira ṣe n koju inira ati iṣoro eto ọrọ aje.
O ni eyi gan ti n mu ko nira fun wọn lati ri ounjẹ jẹ ati lati bọ ẹbi wọn.

Oríṣun àwòrán, Rashidi Ladoja
N kò ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi lọdun yii tori ọpọ ọmọ Naijiria ni iya n jẹ - Ladoja
Ladọja ni wọrọwọ ni oun yoo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ti ọdun yii pẹlu irawọ ẹbẹ si Ọlọrun lati ṣaanu fun Naijiria, awọn eeyan inu rẹ ati awọn adari oṣelu.
O ni, "Ṣiṣe ayẹyẹ ọjọ ibi lasiko ti ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijira ko ni ireti ibi ti wọn a ti ri ounjẹ jẹ yoo jẹ iwa aibikita loju tẹmi.
Nitori naa ni mo fi ke si gbogbo awọn eeyan mi pe ki ẹnikẹni ma ṣe ajọyọ fun ayẹyẹ ọdun kọkandinlọgọrin mi.
Maa fẹ lati da gba adura ki n dupọ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun ẹmi, ki n si beere fun aanu lori orilẹede yii ati awọn adari rẹ".
Ọrọ ti Oloye Ladọja fi lede lo mu ki igbimọ ti o n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi fun un lọdọọdun yi erongba wọn pada fun ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun yii.















