Ẹ máa yìnbọn pa àwọn jàǹdùkú tó bá dojú ìjà kọ àwọn agbófinró – Ìjọba Kenya

Kenya military

Oríṣun àwòrán, getty images

Minisita eto abo lorilẹ-ede Kenya, Kithure Kundiki, ti pàṣẹ fáwọn agbofinro lati maa yìnbọn pa awọn janduku to ba n doju kọ awọn agbofinro lagbegbe Ariwa iwọ oorun orilẹ-ede naa.

Nibi ifilọlẹ ipagọ to niṣe pẹlu eto abo ni Silale, ni Kundiki ti sọrọ yii.

O ni "ẹnikẹni to ba lo ohun ija oloro lati ṣe awọn ọlọpaa ni ijamba ni yóò kọkọ dero ọrun.

“Kii ṣe pe ijọba kan maa ṣadeedee fẹsun ọdaran kan awujọ kan.

“Awọn ọlọpaa yoo máa tẹle ofin ninu gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe.

“Awọn to jẹ ọdaran nìkan ninu awọn eeyan láwùjọ l'awọn agbofinro n wa."

Minisita naa kilọ fun awọn to ba n ṣe atilẹyin fawọn agbesunmọmi lẹkun naa pe ki wọn so ewe agbejẹ mọwọ.

Bakan naa lo ke pe awọn agbofinro lati fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba n sagbatẹru igbesunmọmi.

Kithure tun sọ fawọn ọlọpaa lati gba gbogbo ẹran ọsin tàwọn janduku naa ti ji ko lọ pada.

O tun pàṣẹ fáwọn agbofinro lati fọwọ ofin mu awọn ole to n ji ẹran ọsin gbe ki wọn si foju ba ile ẹjọ.

Ìkìlọ yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti minisita naa ti pinnu lati ko awọn agbofinro lọ sí apa Ariwa Kenya ati ni ẹkun tàwọn agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ.

Awọn ẹkun miiran bẹẹ naa ni Lami ati Odo Tana, nibi ti ikọlu awọn agbesunmọmi ti n pọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

Awọn agbesunmọmi at'awọn ole to n ji ẹran ọsin ti n ṣọṣẹ lapa Ariwa Kenya ati l'awọn ẹkun mii lorilẹ ede naa fún ọpọlọpọ ọdun.