Sanwo-Olu la Jandor àti Vivour-Rhodes mọ́lẹ̀, ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ lórí èsì ìdìbò Gómìnà Èkó kéde

Aworan awọn oludije ipo Gomina ninu idibo ọdun 2023

Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣi ni ẹni to jaweolubori ninu idibo Gomina ipinlẹ Eko to waye.

Eyi ni idajọ ti igbimọ to n gbẹjọ lori awuyewuye to wa latari idibo ipinlẹ Eko gbe kalẹ ni ilu Eko lọjọ Aje.

Adajọ Mikhail Abdullahi to lewaju igbimọ to gbẹjọ tawọn oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Olajide Olaniran taa mọ si Jandor ati Gbadebo Rhodes-Vivour ti Labour Party gbe wa sọ pe oun lo jaweolubori ninu idibo to waye.

Koko pataki tawọn to pẹjọ gbe wa ni pe Sanwo-Olu ko kaju oṣunwọn lati kopa ninu idibo to waye nitori pe ẹgbẹ oṣelu rẹ APC ko jan loontẹ gẹgẹ bi oludije wọn

Igbimọ sọ pe eyi ko si lara nkan ti igbimọ le dajọ le lori.

Ìgbìmọ̀ olùgbẹ̀jọ́ ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko yọ orúkọ Gbadebo Rhodes-Vivour kúrò ninú ìpẹ́jọ̀ Jandor ẹgbẹ́ PDP

Igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye to tibi esi idibo Gomina ipinlẹ Eko wa ti yọwọ oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party ninu ipẹjọ to jumọ pe pẹlu oludije ẹgbẹ Peoples Democratic Party.

Gbadebo Rhodes-Vivour loludije ẹgbẹ LP ti Olajide Olaniran taa mọ si Jandor si jẹ oludije ẹgbẹ PDP.

Igbimọ naa to n joko lati gbe idajọ sita ni ilu Eko sọ pe ẹni to ba fidirẹmi ati ẹni to jaweolubori nikan lo le jumọ pawọpọ pe igbẹjọ itako.

Adajọ Mikail Abdullahi sọ pe kii ṣe bi ki eeyan meji to fidirẹmi bii Gbadebo Rhodes-Vivour ati Olajide Olaniran Jandor jọ gbe igbẹjọ wa papọ.

Tori naa adajọ yọ orukọ Rhodes-Vivour ti ẹgbẹ Labour Party kuro to si gbẹjọ lori ti Jandor nikan.

Nibi ti ọrọ de duro bayii, gbogbo ẹri ti Rhodes Vivour gbe wa siwaju igbimọ naa ni wọn ti fọwọ rọ danu.

Akọroyin wa to wa ni ibi ti igbimọ naa tin n palẹmọ lati gbe idajọ kalẹ tun jabọ pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ Obafemi Hamzat ko le jẹjọ lọtọọtọ tori pe wọn kii ṣe oludije ọtọtọọtọ.

Ilé-ẹjọ́ yóò dájọ́ lọ́la lórí awuyewuye tó wáyé lẹ́yìn èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko
Sanwo-Olu/Rhodes-Vivou/Jandor

Oríṣun àwòrán, Sanwo-Olu/Rhodes-Vivou/Jandor

Ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye lori ibo gomina ipinlẹ Eko yóò gbé idajọ rẹ kalẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan an.

Oludije ipo gomina f'ẹgbẹ oṣelu PDP, Olajide Adediran ti ọpọ mọ si Jandour àti Gbolahan Rhodes-Vivour, ti ẹgbẹ LP lo pe Gomina Babajide Sanwo-Olu lẹjọ pe ko wolẹ ibo gomina ipinlẹ Eko.

Adajọ Arum Ashom ni yoo dari awọn adajọ mii lati gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Aje.

Lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta ọdun yii ni ibo gomina waye nipinlẹ Eko.

Lẹyin idibo naa ni ajọ eleto idibo, INEC, ti kede Sanwo-Olu gẹgẹ bii oludije to jawe olubori ninu eto idibo naa.

Sanwo-Olu ri ibo 762,134 lati la Rhodes-Vivour, to ni ibo 312,329 mọlẹ.

Jandour ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 62,449 nigba ti Oludije APM, Funmilayo Kupoluyi, ṣe ipo kẹrin pẹlu ibo 884.

Amọ ṣa lẹyin eto idibo naa ni awọn ẹgbẹ mejeji gba ile ẹjọ lọ pe awọn kudiẹkudiẹ kan waye lasiko eto dibo ọhun.

Lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii ni awọn agbẹjọro sọ awijare wọn to kẹyin ṣaaju idajọ.