Ilé ẹjọ́ fún Tani Olohun ní béèlì, àmọ́...

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun
Ile ẹjọ Upper Area Court to wa niluu Ilorin ti gba beeli Adegbola Abdulazeez, ti ọpọ mọ si Tani Olohun.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nile ẹjọ lasiko igbẹjọ ọhun jabọ pe ile ẹjọ naa ka awọn nnkan marun un to gbọdọ ṣe ki beeli rẹ le pe.
Gẹgẹ bii amofin Ademola Abdulkadri Ajasa, tii se agbẹjọro fun Alfah Okutagidi to pe Tani Olohun lẹjọ se sọ fun BBC Yoruba, ohun akọkọ to gbọdọ ṣe ni pe ko lọ wa oniduro meji wa.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post, 1
Awọn ohun ti Tani Olohun gbọdọ ṣe ki beeli rẹ le pe
Agbẹjọro naa wa salaye ikọọkan igbesẹ mẹrin to rọ mọ gbigba beeli Tani Olorun
- “Awọn oniduro naa gbọdọ jẹ ẹni to ṣe e fọkan tan, aki wọn si ṣafihan pe ẹnikọọkan wọn ni owo ti iye rẹ to miliọnu marun un naira ninu apo iṣuna ile ifowopamọ wọn.”
- “Ohun keji to gbọdọ ṣe ni pe awọn oniduro naa gbọdọ jẹ ẹni to n gbe lagbegbe ibi ti ile ẹjọ naa wa, to tumọ si pe wọn gbọdọ maa gbe niluu Ilorin.”
- “Ẹlẹẹkẹta nibẹ ni pe ọkan ninu awọn oniduro mejeeji naa gbọdọ jẹ ẹni to ni ilẹ tabi ile, ti ile tabi ilẹ naa si ni iwe ontẹ ijọba ‘C of O’ niluu Ilorin.”
- “Ohun kẹrin ni pe wọn gbọdọ pese olori agbegbe bii Alangua, Mogaji, Dauda tabi Baalẹ niluu Ilorin.”
Ajasa sọ siwaju sii pe eyikeyi ninu awọn oniduro olujẹjọ naa lo le ni ilẹ tabi ile, ẹni naa tun le jẹ olori agbegbe niluu Ilorin.
“Ẹlẹẹkarun un ni pe ẹnikan ninu awọn oniduro naa gbọdọ ni ẹri pe o n san owo ori fun ijọba ipinlẹ Kwara lati ọdun meje sẹyin.”
"Tani Olohun yoo ṣi wa ni atimọle"
Agbẹjọro Ademola Ajasa teṣiwaju pe Tani Olohun yoo ṣi wa ni atimọle.
O ni bi olujẹjọ naa ba ṣe gbogbo nnkan to yẹ ki beeli rẹ nile ẹjọ Upper Area Court le pe, yoo ṣi wa ni ahamọ ofin titi ti yoo fi gba beeli nile ẹjọ majistreeti to ti n jẹjọ keji.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post, 2
O ni “Niwọn igba ti wọn ti le ni ki wọn da pada si ọgba ẹwọn titi di ọjọ karun un, oṣu Kẹwaa, ti ile ẹjọ majistreeti si kọ lati gba beeli rẹ nibẹ, ko ni le jade bo ba tilẹ ṣe ohun gbogbo to yẹ fun beeli ile ẹjọ Upper Area.”
“O di igba ti awọn agbẹjọro rẹ ba lọ pe ẹjọ kotẹmilọrun nile ẹjọ naa ti wọn si gba beeli rẹ nibẹ.















