Akeredolu ṣèlérí láti fi ìyá òfin jẹ alága APC tó lú Kọmísọ́nnà

Aworan Ibi ti ija ti waye

Oríṣun àwòrán, TVC

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba ibilẹ guusu Akoko ni wọọdi kini, Olumide Awolumate to si ọwọ lu kọmisọna to n risi ọrọ obinrin ni ipinlẹ Ondo, Olubnunmi Osadahun.

Gomina kede ọrọ ninu atẹjade ti Kọmisọna fun ọrọ iroyin, Bamidele Ademola Olateju, Akeredolu ni igbesẹ Awolumate ni o da bi pe eeyan si ọwọ lu ijọba, ti ijọba rẹ ko si le fi aye gba irufẹ iwa bẹ.

Saaju fọnran kan jade lori ayelujara ni bi ti alaga ọhun ti ọpọ mọ si Cuba si ọwọ na Kọmisana lasiko ti wọn pin eto iranwọ ti ijọba pese fun araalu.

Ninu fọnran ti ko to isẹju aya lo safihan bi alaga ṣe n fi aga ijoko gba ori kọmisana, ti ori rẹ si hu.

Akeredolu ni gbogbo ọna ni oun yoo fi ripe ofin fi iya jẹ Cuba lori igbesẹ rẹ.

“A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe ofin ipinlẹ Ondo lodi si iwa panle ati fifi iya jẹ eeyan.

“Ọna mii wa ti a le ba arawa sọrọ yatọ jadijagan.

“A ko ni dẹkun pepese ohun iranwọ fun awọn eeyan ipinlẹ Ondo”

Bawo lo ṣe waye?

Ọjọkẹtadinlogun oṣu kẹsan an ni ija bẹ silẹ ni ijọba ibilẹ Ariwa Akoko ni ijọba ibilẹ Ondo lẹyin ti alaga ẹgbẹ APC lati ijọba ibilẹ Guusu Akoko, Olumide Awolumate gba aga idoko mọ Kọmisana to rin ọrọ obinrin nipinlẹ Ondo, Olubunmi Osadahun lori.

Isẹlẹ to fa gbọmisionioto yii lo waye ni ile alaga APC ni wọọdi naa.

Nigba ti alaga Awolumate n sọrọ, o ni Kọmisana lo ṣe ikọlu si oun pẹlu ọmọ rẹ niwaju ọlọpaa.

“Mo wa ni ile mi mo n gba Ludo ni mo sadede ri Kọminsana ati ọmọ rẹ ọkunrin, ọkunrin mii ati ọlọpaa.

“Nigba ti ọlọpa de ọdọ mi, o ni wọn nilo ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Oke-Agbe. Ki n to dide, ọmọ Kọmisana fọ mọ mi to bẹre si ni ma ba mi ja. O ya asọ mi.

“Iya rẹ naa darapọ mọ lati na mi. Gbogbo eleyi lo waye niwaju Ọlọpaa ti wọn mu wa lati wa mu.”

Ẹgbẹ oṣelu APC fofin de Alaga Awolumate

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo ti kede pe awọn yoo fi ofin de Olumide Awolumate to siwọ na kọmisana .

Alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimehin lo koroju si iwa naa, to si ni ẹgbẹ oṣelu APC ko ni fi aye gba iwa naa.

“ A ko le fi aye gba iwa yii ninu ẹgbẹ wa. A yoo fofin de alaga yii fun iwa itiju yii.

“Mo ti palasẹ ki awọn alaga nijọba ibilẹ fun APC ko gbogbo eeyan wasi Akure lati jiroro lori igbesẹ ti a yoo gbe sugbọn a yoo fofin de Alaga.”