Lórí ikú Mohbad,ẹgbẹ́ nọ́ọ̀sì Eko sọ̀rọ̀ lórí afurasí ''Auxillary Nurse'' tó wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Kii ṣe ara wa rara ati rara.
Gbolohun yi ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nọọsi ẹka ti ipinlẹ Eko fi sita lori afurasi nọọsi ti awọn ọlọpaa mu lori iku gbajugbaja akọrin Mohbad.
Nọọsi auxillary yi gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ti ṣe sọ ko le jẹ ara awọn nitori ijọba ko faramọ apejuwe auxillaruy nọọsi ninu awọn to n ṣe iṣẹ itọju alaisan lorileede Naijiria.
Akọwe ẹgbẹ naa arakunrin Toba Odumosu lo ṣalaye ọrọ yi ninu ifọrọwerọ to ni pẹlu akọroyin BBC Yoruba.
Arakunrin Toba sọ pe awọn kan si ileeṣẹ ọlọpaa lati le mọ iru ẹni ti awọn agbofinro sọ pe o wa ni akasọ awọn.
O ni nigba tawọn debẹ tawọn si fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo,gbangba lo han pe kii ṣe ẹni to kawe gboye nilana ẹgbẹ awọn tori naa kii ṣe ojulowo nọọsi.
''Ninu isori awọn to wa ninu ẹgbẹ wa, a ko ni nkankan ti a le pe ni auxillary nọọsi.Ki eeyan to le gba orukọ nọsi, yoo ti kawe bẹẹ si ni wọn yoo ti ṣe awọn idanwo lati fi mọ boya o kaju oṣunwọn.Ẹni taa n wi yi ko ṣe nkankan ninu awọn alakalẹ yi tori naa kii ṣe ara wa''
Ẹ ma ta epo si aṣọ aala wa
Arakunrin Toba ni ẹgbẹ awọn Nọọsi ba mọlẹbi Mohbad kẹdun iku ọmọ wọn bẹẹ lo si kesi awọn eeyan lati ye da luru pọmọ ṣapa lori eyikeyi ọrọ to baa n lọ lode.
O ni o ṣe pataki ki awọn eeyan ṣe iwadii to peye ki wọn to pe eeyan ni oṣiṣẹ ilera Nọọsi nitori iṣe nla leeyan yoo ṣe ko to le de ipo naa.
''Ni Naijiria ki wọn to le pe eeyan ni nọọsi yoo ka iwe ọdun marun un gbako ni ile ẹkọ fasiti ti yoo si tun ṣe ọdun kan gẹgẹ bi ikọsẹ ki wọn to le ka a si nọọsi''
O ni orukọ Auxillary Nurse tawọn eeyan n ran lẹnu kii ṣe apejuwe eeyan gẹgẹ bi nọọsi.
''Yala ki eeyan jẹ ojulowo tabi ko jẹ gbarọgudu, ko si adape kankan to n jẹ auxillary nurse''
Bi a ko ba gbagbe baba Mohbad lo kọkọ ba ileeṣẹ iroyin Naijiria kan sọrọ to si ni awọn fura si pe nọọsi abẹle kan lo fun Mohbad ni abẹrẹ ṣugbọn awọn ko le s boya akọṣẹmọṣẹ ni tabi ko mọ iṣẹ naa daju.
Eyi lo mu ki awọn ọmọ Naijiria kesi awọn agbofinro lati tọ pinpin ẹni naa ki wọn si mọ iru abẹrẹ to fun Mohbad ṣaaju ko to gbẹmi mi.
Iwadii iku Mohbad ṣi n tẹsiwaju lẹyin ti awọn agbofinro hu oku rẹ jade lati ṣe ayẹwo ti yoo tọka ohun to ṣokunfa iku rẹ eyi taa mọ si Autopsy lede Gẹẹsi.
Mohbad: Ìdí tí a ṣe fi gáàsì tajútajú tú àwọn tó ń ṣe ètò ìdágbáre ‘candlelight’ ká rèé – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko

Oríṣun àwòrán, bbc/ben hundeyin
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣalaye eredi to ṣe fi gaasi tajutaju le awọn to n ṣe iwọde idagbere ‘candlelight’ fun olorin takasufe to dagbare faye, Mohbad, ni iloro lekki Toll Gate.
Alukoro ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin ṣalaye ninu atẹjade kan loju opo X rẹ pe awọn eeyan naa kọja aye wọn lo jẹ ki awọn fi gaasi tajutaju le wọn.
Gẹgẹ bii laaye rẹ, aago mẹjọ alẹ ni eto naa yoo dopin lagbegbe Muri Okunola, gẹgẹ bii adehun ti awọn to ṣagbatẹru eto naa ni pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa.
Amọ pupọ ninu awọn to kopa ninu eto naa kọ lati pada sile wọn lẹyin aago mẹjọ ti wọn fẹnuko si.
Kaka ki wọn pada sile wọn, ṣe wọn n korajọ lagbegbe Lekii Toll Gate naa, eyii to n fa sunkẹrẹfakẹrẹ ọkọ, ti wọn si fẹ sọ eto ọhun di iwọde ni iloro naa lodi si adehun to wa nilẹ ṣaaju.
Hundey ni awọn eeyan ọhun kọja agbegbe ti wọn sọ pe awọn yoo ti ṣe eto idagbere, wọn si di irinkerindo ọkọ lọwọ ni iloro ọhun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
“A ko yin ibọn, ko si ẹni ṣeṣe tabi ku”
O ni “Gbogbo eeyan lo mọ pe ko yẹ ki wọn lọ si Lekki Toll Gate nitori ọpọ ero to maa n lo ọna naa ni gbogbo igba.”
“Nitori naa, ninu ipinnu wa lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu, ki a si bẹgi dina iwa ọdaran, a fi gaasi tajutaju tu wọn ka lai lo agidi pẹlu wọn.”
“A ko yin ọta ibọn kankan si wọn, ọna igbalode to ṣe itẹwọgba ni a fi tu wọn ka, ko si ẹmi ẹnikẹni to sọnu, beẹni ko si ẹnikẹni to ṣẹṣe.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Hundeyin sọ pe ko yẹ ki awọn kọlọrọsi ẹda kan maa pin iroyin ẹlẹjẹ nipa ohun to ṣẹlẹ ni iloro naa ka lọna ati ba orukọ ileeṣẹ ọlọpaa jẹ.
Yatọ si ohun ti Hundeyin sọ, akọroyin BBC Yoruba foju ri awọn fidio ibi ti awọn ọlọpaa ti n parọwa si awọn eeyan naa ki wọn maa lọ sile wọn lẹyin ti eto naa pari tan amọ ti wọn kọ eti ikun si ọrọ ọlọpaa.
Bẹẹ naa ni awọn kan lara awọn to ṣagbatẹru eto ọhun tun parọwa si wọn ki wọn maa lọ sile ṣugbọn ti wọn kọ jalẹ, ki ọlọpaa to fi tajutaju tu wọn ka.












