Sẹ́nétọ̀ Jimoh yan olùrànlọ́wọ́ ọgọ́rùn-ún lórí ìdàgbàsókè ìlú

Aworan amugbalẹgbẹ Sẹnẹtọ

Oríṣun àwòrán, Ondoevents

Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun guusu ipinlẹ Ondo nile igbimọ aṣofin agba nilu Abuja, Ọmọwe Jimoh Ibrahim, lo ti kede awọn to le ni ọgọrun gẹgẹ bii oluranlọwọ lori idagbasoke agbeegbe to n ṣoju fun.

Jimoh lo kede ọrọ yi lakoko to n sami ayajọ ọgọrun ọjọ to bẹrẹ si nii ṣoju awọn eniyan rẹ nile igbimọ aṣofin agba ilẹ yi.

Lasiko to n fun awọn oluranlọwọ tuntun naa ni sọwedowo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ninu ọgba fasiti Fortune ni Igbotako nijọba ibilẹ Okitipupa, aṣofin naa rọ wọn lati fi owo naa ṣe nkan ti yoo mu igbe aye wọn dara ju ti atẹyinwa lọ.

Aṣofin naa wi pe “Mo yan awọn eeyan yii lati le maa moju to awọn iṣẹ akanṣe ti mo fẹẹ maa ṣe jakejado ijọba ibilẹ mẹfẹẹfa ti mo n ṣoju fun.

“Isẹ akanṣe pọ ti mo fẹẹ ṣe lati mayedẹrun fun awọn eniyan mi, mo si nilo awọn ti yoo moju yo iṣẹ ọun ko lee jẹ ojulowo, ko si tun lee pari ni kia.

“Mo n san owo oṣu fun wọn loni ti wọn fẹẹ bẹẹrẹ iṣe ko le jẹ moriya fun wọn, ko si tun le tun aye wọn ṣe.”

Awọn oluranlọwọ ọun ni BBC News Yoruba gbọ pe wọn yoo ma gba ẹgbẹrun lọna aadọta naira loṣu amọ ti Sẹnetọ naa pa owo oṣu mẹfa pọ lẹẹkan fun lọjọ akọkọ ti wọn wọ iṣẹ ki wọn le ri nkan gidi fi owo ọun ṣe.

Sẹnetọ Jimoh Ibrahim to kẹkọ gboye ni ile ẹkọ giga ti Cambridge, Harvard ati Cambridge lo jẹ gbajugbaja oniṣowo lorilẹ ede Nigeria ati nilẹ Africa ko too di aṣofin.

Ọkan lara awọn to jẹ anfani ọun, Ayara Gbenga, juwe sẹnetọ gẹgẹ oloṣelu to yatọ sawọn oloṣelu to ku.

Ayara wi pe oun ko ri sẹnetọ to ni ọgọrun oluranlọwọ ri ati pe oun ti Sẹnetọ Jimoh Ibrahim ti gbeṣe laarin ọgọrun ọjọ to di aṣofin kọja afẹnusọ.