'Mo máa ń jẹ́ kí òkú rẹwà gidi tí mo bá ya fọ́tò fún un'

Richard Kennady

Oríṣun àwòrán, Richard Kennady

Àkọlé àwòrán, Lati ọmọ ọdun mẹsan an ni Richard Kennady ti n ya fọto oku eeyan.
    • Author, Pramila Krishnan
    • Role, BBC World Service

Ikilọ: Aworan oku eeyan wa ninu iroyin yii

''Iṣẹ mi ni lati gbe oku eeyan sori aga ki n si jẹ ki o dun un wo lati ya fọto,'' Ravindran lo sọ bẹẹ nipa ọjọ kinni to bẹrẹ iṣẹ.

Ọmọ ọdun mẹrinla pere nii ṣe lọdun 1972 nigba ti baba rẹ Srinivasan to ni ileeṣẹ fọto ran niṣẹ.

Richard Kennady naa ni irufẹ iriri yii nigba to wa ni ọdun mẹsan an.

Aṣọ funfun ni wọn ki Kennady mu dani lẹyin aga ti wọn gbe oku si.

O sọ fun BBC pe ẹru ba oun, koda oun ko le sun.

Bakan naa lo sọ pe niṣe ni oun n la alakala nibi ti oun ti n ri oku loju orun.

Awọn eeyan mejeeji yii lo ṣiṣẹ fọto tori iṣẹ baba wọn ni.

O kere tan, awọn mejeeji ti ya fọta oku to le ni ẹgbẹrun kan.

Wọn wa lara awọn oluyafọto awọn oku nipinlẹ Tami Nadu lorilẹede India.

Wọn ba BBC sọrọ lori iṣe wọn eleyii ti o lowo lori nibi ogoji ọdun sẹyin.

Kikoju ẹru

Ko to di aipẹ yii ti nkan bẹrẹ si ni yatọ, ọpọ awujọ nipinlẹ Tamil Nadu gbagbọ pe ẹmi eeyan le ma gun ti o ba n ya fọto.

Eyi tumọ si pe ọpọ eeyan ya fọto fun igba akọkọ lẹyin ti wọn ku.

Ravindran ati baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Ravindran

Àkọlé àwòrán, Ravindran (akọkọ lati apa ọtun) ni oun ri owo nla lori fọto yiya fun oku

Ravindran wa lati Karaikudi lapa guusu ilu Chennai tii ṣe olu ilu ipinlẹ Tamil Nadu.

Iṣẹ yii le ma jẹ iru iṣẹ ti ọdọmọkunrin le nifẹ si, koda o fẹ da ile ẹkọ rẹ duro.

Ravindran ni ''lẹyin ti oun ti tẹle baba oun fun igba diẹ, oun bẹrẹ si ni lọ ya fọto awọn oku fun ra oun.

Kẹrẹ kẹrẹ, Ravindran bẹrẹ si ni gbọrẹgẹ jigẹ ninu iṣẹ fọto yiya.

O ni oun ṣẹgun ẹru, bayii ni oun si bẹrẹ si fẹran iṣẹ oun.

O ni oun maa n jẹ ki fọto oku rẹwa ti oun ba ya fọto wọn tan.

Awọn akori to ba ni lọkan jẹ

Richard tete bẹrẹ iṣẹ fọto yiya.

O ni oun maa n tẹle baba oun lọ si ibi iṣẹ lori oke Yercaud lapa iwọ oorun ilu Chennai.

Iriri rẹ to lagbara julọ ni yiya fọto fun oku ọmọde.

''Inu awọn obi rẹ bajẹ gidi gan an, iya ọmọ naa wẹ fun oku ọmọ rẹ, o si wọ aṣọ fun un, bakan naa ni o kun atike fun oku ọmọ naa.

Lẹyin naa ni iya ọmọ yii gbe sori ẹsẹ rẹ ti mo si ya fọtọ fun oku ọmọ naa.

Niṣe lo kan dabi ẹni pe ọmọ naa n sun, nkan to bani lọkan jẹ ni,'' Richard lo sọ bẹẹ.

Awọn to yika oku ninu posi

Oríṣun àwòrán, Richard Kennady

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ẹbi to ya fọto pẹlu oku eeyan wọn

Bakan naa ni wọn tun maa n ya fọto igba ti wọn n wẹ oku ti wọn si n fi ododo si i lara.

Ravindran ni ''mo ti lọ fọto bi wọn ṣe gbe oku eeyan sinu koto.''

Ki saaba si aye fawọn oluyafọto, akoko perete ni wọn ni lati fọ fọto naa tori ọpọ ẹbi lo maa n fẹ lo fọto naa lọjọ keji lati fi ṣe ikẹdun.

Kamẹra fọtọ dudu ati funfun ni Ravindran ati Richard lo, amọ wọn ṣiṣẹ wọn daadaa.

Ọpọ awọn onibara wọn lo jẹ ẹlẹsin onigbagbọ ati HIndu.

Niṣe ni ọpọ ninu wọn maa n gbe aworan oku ẹbi wọn sinu yara igbadura wọn.

Ravindran ranti pe oun ya irufẹ fọto yi fun ẹlẹsin musulumi meji pere.

Richard ko tiẹ ni iru iriri bẹẹ rara.

Alakala

Richard tun bawọn ọlọpaa ṣiṣẹ.

O tun ya fọto awọn eeyan to gbẹmi ara wọn, atawọn to ku ninu ijamba ọkọ.

Mọlẹbi pẹlu oku wọn

Oríṣun àwòrán, Richard Kennady

Àkọlé àwòrán, Awọn mọlẹbi maa n saaba ya fọto pẹlu oku eeyan wọn

''Nkan to bani ninu jẹ gidi gan an ni.

Nigba mii, n kii le jẹun, mi kii le sun bakan naa,'' Ravindran ṣalaye.

Ọpọ eeyan ni wọn lo fọto to ya gẹgẹ ẹri nile ẹjọ.

Irufẹ fọto yii lawọn ayafọto maa n ri gegere nibẹ.

Koda awọn ẹbi oloogbe naa tun maa n bun wọn lowo.

Amọ, awọn eeyan kan maa n foju tika tẹgbin wo awọn to ba n ya fọto fun oku.

Richard awọn onibara mii kii fẹ saaba pe oun fun iṣẹ miiran yatọ si yiya fọto fun oku.

Koda, awọn ẹbi Ravindran to jẹ ẹlẹsin Hindu maa n wo ibi kibi ti oku wa gẹgẹ bi ibi ti ko mọ.

Nitori naa, Ravindran gbọdọ fọ ara rẹ mọ ki o to le wọle tabi wọ yara iyaworan.

Widespread practice

Yiya fọto oku wọpọ laye igba kan lọpọlọpọ orilẹede.

Ọkunrin kan to n wom oku ọmọdebinrin

Oríṣun àwòrán, Heritage Art/Getty

Àkọlé àwòrán, Yiya fọto oku wọpọ laye igba kan lọpọlọpọ orilẹede - ayaworan ọmọ orilẹede Faranse lo ya fọto yii lọdun 1850.

Bi bii ọgọrun ọdun sẹyin, ọpọ ẹbi to n ṣọfọ lo maa n ya fọto pẹlu oku eeyan wọn.

Fọto yiya jẹ ọna kan tawọn ẹbi fi maa n ranti eeyan wọn papaa julọ lasiko ti fọto yiya wọn gogo.

Ati pe ọpọ eeyan ni ko ya fọto ara wọn nigba ti wọn wa laaye.

Fun apẹẹrẹ, lorilẹede Amẹrika, awọn eeyan maa n ya fọto oku ti wọn gbe si ori yinyin ninu yara.

Lawọn ilu ti oriṣiiriṣii arun n ba finra, igba kugba ni iku le de.

Ọpọ awọn eeyan yii si ni wọn kii saaba ya fọto ri nigbati wọn wa laye.

Fọto ti wọn ba ya lẹyin ti wọn ba ku tan lawọn eeyan wọn maa n saba ri wo.

Ravindran pẹlu ẹrọ kamẹra lọwọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Ravindran

Àkọlé àwòrán, Ravindran pasa ya fọto nile ẹkọ ati awujọ naa

Diẹ diẹ aṣa yii ku papaa julọ pẹlu bi eto ilera ṣe n gberu si.

Amọ, aṣa yii pẹ ni ipinlẹ Tamil Nadu atawọn ipinlẹ bii West Bengal ati Odisha ni ilẹ mimọ ilu Varanasi ni India.

Richard sọ pe ki fọto to de, awọn olowo maa n pe awọn ayaworan lati ya wọn.

O ni awọn olowo nikan lo le sanwo fawọn ayaworan lati ya wọ, amọ ati olowo ati mẹkunnu lo n ya fọto.

Nigba ti opin n de

Ni nkan bi ogoji ọdun sẹyin, kamẹra kekeke lu ọja pa, ẹru ati maa ya fọto si bẹrẹ si ni lọ diẹ diẹ.

Richard n ṣafihan fọto awọn oku to ya

Oríṣun àwòrán, Richard Kennady

Àkọlé àwòrán, Richard si fẹ tọju aṣa yiya fọto fun oku

Bayii ni Richard bẹrẹ si ni ya ọto ni ṣọọsi ati nibi ajọdun kaakiri.

Ravindran ni tiẹ n ya fọto nile ẹkọ ati lawujọ.

Ni bayii, awọn mejeeji ti le ni ọgọta ọdun, Ravindran n dupẹ lọwọ oku ọrun ti o ran lọwọ lati kọ iṣẹ fọto yiya fun oku.

Amọ, ko fẹ ki aṣa naa tẹsiwaju ti o ba papoda.

O ni ''mi o fẹ ki ẹnikẹni ya fọto mi ti mo ba ku.''

Ricahard ya fọta baba baba rẹ nigba ti o ku, koda o ni fọto awọn baba nla rẹ titi ti o fi de iran kẹta.

Ravindran ni tiẹ tun ni ọpọlọpọ fọto awọn oku lọwọ.

O ni idile oun maa n tọju fọto awọn baba nla awọn to ti ku.

Ravindran ṣalaye pe oun ti sọ fun ọmókunrin oun to kere ju lati ya fọto oun ti ọlọjọ ba ti de.