A ó tiraka láti pèsè 20,000 mẹ́gáwáàtì iná mọ̀nàmọ́ná títí ọdún 2026 – Ìjọba àpapọ̀

Electricity

Oríṣun àwòrán, Emmanuel Ikwuegbu

Minisita fun ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu ti sọ pe ijọba apapọ ti bẹrẹ iṣẹ lati ri pe ohun pese ẹgbẹrun lọna ogun mẹgawaati ina mọnamọna ko to di ọdun 2026.

Adelabu lo sọ ọrọ naa niluu Osogbo lasiko abẹwo rẹ si ẹka ileeṣẹ apinaka Transmission Company of Nigeria (TCN).

O fi kun pe titi ọdun 2060, Naijiria yoo ti maa pese ina ti iye mẹgawaati rẹ ko ni din ni ẹgbẹrun lọna ọgọta.

Ninu ọrọ rẹ, o ni erongba ileeṣẹ ti oun n ṣakoso rẹ ni lati ṣe afikun iye ina ti Naijiria n pese, ati eyii to n pi ka fun awọn araalu.

O ni “Gẹgẹ bi mo ṣe sọ fun yin, afujusun ijọba Naijiria ni lati pese, o kere tan ẹgbẹrun lọna ọgọta mẹgawaati ina titi ọdun 2060, iyẹn ọgọta gigawaati...”

“Amọ bi mo ṣe ṣo ninu ọkan lara ọkan eto ti kan mo ti kopa, niwọn igba ti awọn orilẹ-de mii ba le tiraka lati pese ẹgbẹrun lọna ọgọrun mẹgawaati ina laarin ogoji ọdun si aadọta ọdun, yoo ṣeeṣe fun Naijiria naa.”

“A ti ni afojusun iye ina ti a fẹ pese ati eyii ti a maa pin kiri, titi ọdun 2026, o yẹ ki a le pese ẹgbẹrun lọna ogun mẹgawaati.”

Adelabu fi kun pe laarin oṣu poerete si asiko yii, ijọba yoo ṣagbekalẹ ibudo apinaka meji miran.

Minisita naa wa kilọ fun oṣiṣẹ eyikeyi to ba n ṣiṣẹ lati dena afojusun ijọba naa pe yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

O fi kun pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ṣe iwadii ohun to ṣokunfa ina to ṣẹyọ ni ni ibudo apinaka, TCN, to wa niluu Birnin Kebbi.

Ẹka ileeṣẹ TCN ilu Osogbo yii ni Adelabu kọkọ ṣabẹwo si lati igba ti Aarẹ Tinubu ti yan an gẹgẹ bii minisita.