7.6 mílíọ́nù ọmọdébìnrin ni kò láǹfàní àti kàwé ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES
Ajọ iṣọkan agbaye to n ri si ọrọ awọn ọmọde, UNICEF, ti sọ pe o le ni ida aadọta awọn ọmọdebinrin ni Najiria ti ko lọ ile ẹkọ.
Jutaro Sakamoto, to jẹ alakoso eto ẹkọ ni UNICEF lo sọ ọrọ naa nibi ipade kan niluu Abuja.
O ni 7.6 miliọnu ọmọdebirnin ni ko si nile ẹkọ ni Naijiria.
3.9 miliọnu ni ko si nile ẹkọ alakọbẹrẹ, nigba ti 3.7 miliọnu ko si nile ẹkọ girama akọkọ ninu apapọ awọn 7.6 miliọnu ọmọdebinrin naa.
Sakamoto sọ siwaju si pe ida mejidinlaadọta awọn ọmọdebinrin ti ko si nile ẹkọ naa lo wa lati iha Ariwa Naijiria.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ida mẹsan an pere ninu awọn ọmọdebinrin ti ko ri jajẹ lo wa nile ẹkọ girama, nigba ti ida mọkanlelọgọrin awọn ọmọbinrin to wa lati ile ọla lo wa nile ẹkọ girama.
Nigba to n sọrọ lori pe ida marundinlogun ọmọdebinrin ni ko si nile ẹkọ lagbaye, Sakamoto sọ pe ajọ naa ko ni lr tan iṣoro ọhun ni Naijiria.
O fi kun pe awọn to wa nile gan ko ri ẹkọ to dantọ gba, latari pe ko si awọn ohun idanilẹkọọ to tọ.
O pari ọrọ rẹ pe eto kan ti UNICEF gbe kalẹ n ṣe iranlọwọ fun awọn ọmọde ti ko lanfani lati lọ sile ẹkọ lati ri ẹkọ to peye gba.












