Wáá gbọ́ ohun tí àwọn èèkàn ìlú n sọ nípa àdó olóró tó pa ọ̀pọ̀ ní Tundun Biri

Aworan Sheikh Dahiru, Muhammadu Sanusi II ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, BBC Hausa

Awọn araalu, oloṣelu ati adari ẹsin Islam lorilẹede Naijiria lo ti tẹsiwaju lati maa sọrọ nipa ikọlu ado oloro ti ọmọgun ori ilẹ lorilẹede Naijiria ju si Tudun Biri, nijọba ibilẹ Igabi, nipinlẹ Kaduna.

Akọlu ọhun, ti ajọ ologun ilẹ naa pe ni aṣiṣe, lo mu ọpọlọpọ ẹmi lọ ti awọn miran si n gba itọju nileewosan.

Bo tilẹ jẹ pe ajọ to n moju to iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria (NEMA) wi pe awọn marundinlaadọrun lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa, awọn oṣiṣẹ ajọ Amnesty International to ṣe abẹwo silu naa wi pe, o kere tan, ọgọfa eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Wo diẹ lara awọn to ti mẹnuba ọrọ naa ati ohun ti wọn sọ.

Ẹ gbọdọ tuṣu iṣẹlẹ yii de isalẹ ikoko – Tinubu

Aworan Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, State House

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, lo ti paṣe ki wọn wadii ohun to ṣokunfa aṣiṣe ti ajọ ologun ṣe to mu ki wọn ju ado oloro saarin ilu.

Ninu atẹjade kan latọwọ agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale, Tinubu juwe iṣẹlẹ naa bi ohun to buru jai to si bani lọkan jẹ.

Aarẹ kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi to fara ba ninu iṣẹlẹ naa, to sii paṣẹ iwadi ni kiakia lati mọ ohun to fa aṣiṣe ọhun.

A lero pe ijọba yoo wadii ohun to ṣẹlẹ – Khalifa Muhammadu Sanusi II

Aworan Muhammadu Sanusi II

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ sawọn olugbe ilu ti akọle naa ti waye, ọba awọn ẹgbẹ Musulumi ti n jẹ Tijjaniyya ni Naijiria, Muhammadu Sanusi II, wi pe irufẹ iṣẹlẹ yii lo waye ni Nassarawa lọdun diẹ sẹyin, amọ ti abọ iwadii tawọn alaṣẹ ṣe nigba naa ko jade lati igba naa wa.

Sanusi rọ awọ alaṣẹ lati ṣe ohun to tọ lati ri pe iru iṣẹlẹ naa ko waye mọ.

Bakan naa lo rọ awọ eeyan agbegbe naa lati ṣe suuru, ki wọn si ṣe atilẹyin to jọju fun ijọba lati lee ri kulẹkulẹ ọrọ naa.

Ẹ gbe igbesẹ lati dena aṣiṣe miran – Atiku

Aworan Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar

Igbakeji aarẹ tẹlẹ ri ni Naijiria, Atiku Abubakar, naa fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to fi soju opo X , atiku bbere fun iwadi tojinlẹ latọwọ ijọba lojuna a ti pinwọ wiwaye iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

O wi pe aṣiṣe akọlu jẹ ohun to n kọnilominu loriẹede Naijiria.

O yẹ ki awọn to fara ba ninu iṣẹlẹ naa o gba owo ‘gba ma binu’ – Dahiru Bauchi

Aworan Dahiru Bauchi

Oríṣun àwòrán, Buhari Prayers

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC, adari awọn Tijjaniyya ni Naijiria, Dahiru Bauchi, wi pe ohun iyalẹnu ni pe iru akọlu yii lee waye pẹlu aṣiṣe.

O ni o yẹ ki ijọba o jade lati waa ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ki wọn si san owo ẹmi awọ ti wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.

Bauchi wi pe “ohun taa fẹ ni pe ki wọn waa sọ bi wọn ṣe fi baluu dana sun awọn to n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi anọbi”.

Ẹni ba ṣeeṣi paayan maa n san owo itanran – Abdullahi Bala Lau

Aworan Bala Lau

Oríṣun àwòrán, Jibwis

Olori ẹgbẹ Izala ni Naijiria, Abdullahi Bala Lau, wi pe “a mọ pe o ṣe pataki ki ijọba fopin si igbesunmọmi, amọ o sẹ koko ki a daabo bo ẹmi awọn araalu, ka ma baa gbabẹ bọ sinu wahala miran”.

O ni o di dandan ki ijọba san owo itanran tori pe “ẹni to ba ṣeeṣi paayan maa n sanwo itanran ni, amọ ẹni to ba mọọmọ paayan ni lati foju wina ofin”.

Bala Lau waa fikun pe, lẹyn iwadii ijọba, ohunkohun yowu ti won i baa ri, wọn ni lati sanwo itanran fun awọn ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Idajọ ododo ni lati waye – Kwankwaso

Aworan Rabiu Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, @Kwankwasorm

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ loju opo X, oludije sipo aarẹ lẹgbẹ NNPP lọdun 2023, Sẹnetọ Rabiu Musa Kwankwaso, wi pe ohun to n ko ipalara gidi ba awọn alaiṣẹ ni iṣẹlẹ yii, leyi to yẹ ki awọn ẹṣọ abo o pese abo to jọju fun awọn araalu.

O ni awọn alaṣẹ ni lati ṣe ohun to tọ lati rii pe idajọ ododo waye lati lee dena irufẹ iṣẹlẹ yii lọjọ iwaju.