Ó ṣe! Inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ la ti gbé òkú ọmọbìnrin ọdún mẹ́tàdínlógún kan lẹ́yìn tí 'ọmọ Yahoo' kan fipá bàa lòpọ̀ ní Ilorin

Bi eniyan ba jẹ ori ahun, yoo sunkun lori bi ọdọkunrin kan, Isaac Ọdunayọ, ṣe fipa ba ọdọbinrin kan lo, ti ẹmi si bọ lara rẹ.
Otẹẹli kan ni wọn lọkunrin ti wọn fura si pe o jẹ ọmọ 'Yahoo' ẹni ọdun mọkandinlogun ọun, ti fipa ki ọmọ ọlọmọ naa tọjọ ori rẹ ko ju mẹtadinlogun lọ mọlẹ, to fipa ba a laṣepọ ti iyẹn fi ku mọ ọ labẹ.
BBC Yoruba yọju si ile awọn obi oloogbe naa, Ọgbẹni ati Arabinrin Stephen Gbenga Makanjuola, ti wọn n gbe ni Pipeline ni agbegbe Gaa Akanbi ni ilu Ilorin lati mo bi iṣẹlẹ laabi naa se waye.
- Ṣé lóòótọ́ ni Ooni lọ ṣe àbẹ̀wò sí Emefiele lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?
- 'Orí ló kó èmi àti ìyàwó mi yọ, àwa náà ìbá kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí àwọn ọba mẹ́ta l'Ogbomoso'
- Wo ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Iléeṣẹ́ ológun ti ṣèsì ju àdó olóró sí àárin àwọn aráàlú
- Owó ìsákọ́lẹ̀ fa làásìgbò láàrín àwọn Hausa nílùú Babanla ní Kwara
"Ọna to lagbara ni mo fi bii, ko yẹ ko lọ bayi"

Iya ọdọbinrin naa n sunkun o si n kigbe pe ki ọmọ oun pada wa saye.
"Ọmọ meji ni mo bi, ọkunrin kan ati obinrin kan, sugbon eyi obinrin ti o jade laye yii ni mo bi ni ọna to lagbara nitori isẹ abẹ ni wọn fi gbẹbi ẹ.
“Fun bi ọjọ mẹta lẹyin ti mo bii tan, mo wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, awọn eniyan ko si mọ boya maa luula. Koda, a o mọ boya ọmọ naa yoo ye, diẹ loku ki baba rẹ fi sọ ọ ni, 'Kasi ma wo'. O jẹ ọmọ iyalẹnu.
"Gbogbo igba ni mo ma n sọ pe ọmọ naa ati ẹgbon rẹ ni yoo yọ wa kuro ninu iya, ti a o si maa gbe ninu igbadun ti a o le gbe bayi nitori ki oun ati ẹgbon rẹ le ni ẹkọ to yanranti, sugbon o se ni laanu wi pe aye da ẹmi rẹ legbodo.
"Lotitọ, o ti sẹlẹ, sugbon ohun ti a fẹ bayii ni idajọ ododo.”
"Mo kilọ fun oun ati iya rẹ ki wọn ma kuro nile lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ"

Ni tirẹ, Baba oloogbe naa sọ pe lati igba ti iṣẹlẹ naa ti sẹ ni oun ko ti mọ iwa hu mọ ti oun si n rin bi alailero.
Gẹgẹbi ọrọ to sọ,"ọmọ mi pade ọmọkunrin ọhun ni ibi ti wọn ti n ṣe lẹsini igbaradi fun idanwo Jambu, ni ọjọ to ku ọla ti yoo ku, wọn si gba nọmba ara wọn”.
Ọgbẹni Makanjuola ni "ti ko ba se ti iku, ọmọ mi i ba ti wa ni ile ẹkọ giga Kwara Poly lati kọ imo sayensi (Science and Lab Technology).
"Ni ọgbọnjọ oṣu kẹwa, mo kilọ fun oun ati iya rẹ wi pe ki wọn mase jade kuro nile, mo si lọ si ibi iṣẹ pẹlu ọmọ mi ọkunrin, sugbon ni ọsan, ọkan mi kobalẹ, mo si ni ki ẹgbon rẹ lọọ woo nile ti ko si baa nile.
“Iya rẹ naa sọ pe oun ko mọ ibi to wa bẹẹ si ni ẹrọ ibanisọrọ rẹ ko lọ, mo pa ohun ti mo n se ti, mo si gbera lọ sile sugbon a o rii.
"Ni deede aago meje abọ ni mo gba ipe lati ileeṣẹ ọlọpaa A Division. Igba ti mo debẹ ni wọn ṣalaye pe, wọn ṣeku pa ọmọ mi. Mo sọ wi pe mo fẹẹ rii, wọn si mu mi lọ ile igbokusi ti wọn tẹ ẹ si.
"Mo mọ wi pe kii ṣe oju lasan nitori, bawo ni ibusun foomu ati ilẹẹlẹ ṣe le kun fun ẹjẹ lori pe ọmọ ṣẹṣẹ n mọ ọkunrin?"
Adajọ ni ki Odunayo o maa gbatẹgun lẹwọn di ọjọ igbẹjọ
Ṣaaju, ni ọjọ Ẹti, ọjọ kini oṣu kejila, ni wọn wọ afurasi ọdaran naa, Isaac Ọdunayọ, wa sile ẹjọ Majisreeti kan to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, fun ẹsun ifipabanilopọ ati ipaniyan.
Agbefọba, Inpẹkitọ Abdullah Sanni, to ṣalaye bi ẹsun naa ṣe jẹ ni kootu ọhun sọ pe afurasi ọdaran yii huwa buruku naa, nipa titan ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọun lọ si ileetura kan, to si ki ọmọ naa mọlẹ, to fipa ba a laṣepọ titi iyẹn fi ku.
O tẹsiwaju pe lẹyin iṣẹju marundinlogoji to mu ọmọbinrin naa wọ yara otẹẹli naa lo sare jade to fẹ maa sa lọ ṣugbọn awọn oṣiṣẹ otẹẹli ọhun ra a mu ti wọn si tẹle wọ yara ṣugbọn ninu agbara ẹja ni wọn ba oloogbe yii to si ti ku patapata.
Sanni wi pe nigba ti iwadii n lọ lọwọ ni Ọdunayọ sọ fun awọn ọlọpaa pe lootọ loun ba ọmọbinrin naa laṣepọ ko to di pe ẹjẹ n jade loju ara rẹ ati pe iṣẹ ‘Yahoo Yahoo’ ni oun yan laayo.
Adajọ Mohammed Dasuki ni ko ti i saaye fun alaye kankan, oun o si le faaye beeli silẹ fun afurasi ọdaran naa.
O ni ki wọn taari ẹ si ahamo ijọba, ibẹ ni ko ti lọọ maa gbatẹgun titi di ọjọ igbẹjọ to kan lọjọ Kejila, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.














