Wo ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Iléeṣẹ́ ológun ti ṣèsì ju àdó olóró sí àárin àwọn aráàlú

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIR FORCE HQ/FACEBOOK
Saaju ni ileeṣẹ ologun Naijiria sapejuwe ibu gbamu to waye gẹgẹ bi asise lẹyin ti ọpọ ẹmi sọnu nibi ajọdun Maulud Nabiyy to waye nipinlẹ Kaduna ni abule Tudun Biri lọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2023.
Ọpọ awọn onimọ nipa eto abo lo ti bu ẹnu atẹlu asise ileeṣẹ ologun fun bi wọn se n gbe ija to yẹ ki wọn gbe lọ koju Boko Haram lọ ja awọn araalu ti wọn ko mọ ohunkohun.
Ileeṣẹ BBC se agbekalẹ awọn isẹlẹ to ti waye sẹyin, ti asise ileeṣẹ ologun Nigeria ti gba ọpọlọpọ ẹmi.
Tudun Biri- Kaduna Ọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2023.

Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kaduna ni eeyan marundinlaadọruun lo ti jade laye lẹyin ibu gbamu to waye ni agbegbe Tudun Biri.
Awọn olujọsin kan lo ko ara wọn jọ lati se ajọdun Maulud Nabiyy, gẹgẹ bii olugbe agbegbe naa ati olukọ ni ile ẹkọ Madrasalatul Madinatul Ahbab, Belllo Shehu Ugara se salaye, sugbọn sa dede ni ọkọ ofurufu kan wa si ibẹ to si ju ado oloro si aarin wọn.
“A wa naa lọ sibẹ lati wa oku awọn eeyan to ku. A pariwo fun iranlọwọ fun awọn to si ni ẹmi lara , ti baalu naa si tun pada wa lati wa sọ ado oloro.”
O ni lara awọn to jade laye nipasẹ ibu gbamu naa jẹ obinrin ati ọmọde, paapa awọn agbalagba.
Aarẹ Bola Tinubu ti ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi awọn eeyan naa, to si palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ ni kiakia.
Buhari, Yobe, ọjọ kẹdogun oṣu kẹsan an ọdun 2021
Ileeṣẹ ologun ofurufu orilẹede Naijiria ni awọn ọmọ ologun wọn sesi kọlu agbegbe Buhari nijọba ibilẹ Yunusarin nipinlẹ Yobe, ti wọn si sekupa ọpọ eeyan.
Saaju ni ileeṣẹ ologun ofurufu ni awọn ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa.
Oṣojumikoro ni Baalu ileeṣẹ ologun n fo kiri agbegbe Kamadougou nipinlẹ Yobe lati sawadi awọn ikọ Boko Haram ati ISWAP.
“Awọn ologun Kai gbọ iroyin pe awọn janduku n sọsẹ ni agbegbe ẹnu ibode Naijiria ati Niger.
“Nigba ti baalu naa n fo kiri guusu Kanama, o kẹfin pe awọn kan wa ninu igbo, to si ro pe awọn ọmọ ogun Boko Haram ni.
“Lati ibẹ ni awabaalu naa ti ju ado oloro si aarin awọn eeyan naa.”
Rann-Borno, ọjọ kejidinlogun ọdun 2017

Oríṣun àwòrán, EPA
Awọn alasẹ ni o le ni ọgọrun un eeyan to padanu ẹmi wọn lẹyin ti Ileeṣẹ ologun sesi sọ ado oloro si ibudo Raan nipinlẹ Borno.
Ileeṣẹ ologun ni ibanujẹ ọkan ni isẹlẹ naa jẹ , ti wọn si bẹrẹ iwadii.
Ọkan lara awọn alasẹ sọ fun BBC pe eeyan 236 lo padanu ẹmi wọn, ti wọn si ti sin wọn ni abule Rann.
Sugbọn nigba to ya, alaga ijọba ibilẹ Kala-Baige ni eeyan 115 lo jade laye, to se pe awọn araalu lo se asise nipa iye eeyan to jade laye.
Bakan naa ni Ileeṣẹ ologun ni awọn kọlu awọn eeyan nitori pe awọn ro pe wọn jẹ ọmọ ologun Boko Haram.
Doma- Nasarawa, ọjọ kẹtalọgbọn oṣu kiin ọdun 2023

Oríṣun àwòrán, others
O to eeyan mejidinlọgbọn lo padanu ẹmi wọn nibi ikọlu ado oloro ọkọ ofurufu ni agbegbe Rukubu nijọba ibilẹ Doma nipinlẹ Nasarawa, to wa ni ẹnu ibode pẹlu ipinlẹ Benue.
Ikọlu yii waye lẹyin ti awọn darandaran da ẹran lọ si ọdọ awọn alaṣẹ ipinlẹ Benue, ti wọn fi wọn silẹ lọ ṣe nnkan mii.
Gẹgẹ bi iroyin ṣesọ, Ileeṣẹ ologun gbọ iroyin pe awọn janduku ti yabo agbegbe ẹnu ibode Nasarawa ati Benue.
Lẹyin ti wọn se ọfintoto, wọn gbera lati kọlu awọn janduku naa sugbọn oṣeni laanu pe awọn darandaran to da ẹran ni wọn si ibọn bole fun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgbọn lo ba ikọlu naa lọ, sugbọn iwe iroyin kaakiri orilẹede Naijiria ni iye naa pọ jubẹ lọ.
Maize Quarter – Borno, ọjọ kejidinlọgbọn ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIRFORCE/FACEBOOK
Ọpọ araalu lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti ado oloro ti wọn si ransẹ si awọn ọmọ ologun ISWAP ni abule Kutar Daban Masara lo kọlu awọn araalu.
Ileeṣẹ iroyin AFP ni o o ogun pẹjapẹja to padanu ẹmi wọn sugbọn ninu iwadi ileeṣẹ BBC, ileeṣẹ ologun ofurufu ni eeyan kan loku, ti eeyan mẹfa mii si farapa.
Ẹwẹ, awọn iroyin mii ni to aadọta si ọgọta eeyan to padanu ẹmi wọn nibi ikọlu naa.
Mainok- Borno, ọjọ karundinlọgbọn ọdun 2021
Ikọlu ileeṣẹ ọmọ ologun sekupa ọpọ ọmọ ologun ninu ikọlu to waye ni Mainok, kilomita marundinlọgọta si Maiduguri.
Botilẹ jẹpe ileeṣẹ ologun ko safihan iye ọmọ ologun to ba ilẹese naa lọ sugbọn iwadii BBC fihan pe o to ọgbọ ọmọ ologun to padanu ẹmi wọn.
Nigba to ya ni ileeṣẹ ologuin kede pe awọn ti bẹrẹ iwadii awọn fọnran ati aworan kan to tẹ wọn lọwọ nipa isẹlẹ naa.
Mutumji- Zamfara, ọjọ kọkandinlogun ọdun 2022.
Nipinlẹ Zamfara, ọkan lara awọn ipinlẹ to koju ikọlu Janduku ni apa ariwa, baalu to n gbe ado oloro sekupa eeyan mẹrinlelọgọta ni agbegbe Mutumji nijọba ibilẹ Maru.
Awọn araalu salaye fun awọn akọroyin pe ọpọlọpọ janduku naa ba isẹlẹ naa lọ.
Sugbọn eeyan mejila ni bugbamu naa sesi sekupa.
Kunkuman Bayen Dutse-Katsina, ọjọ keje oṣu keje ọdun 2022
Nipinlẹ Katsina bakan naa, irufẹ ikọlu yii waye ninu oṣu keje ọdun 2022 ni bi tii eeyan kan ti padanu ẹmi rẹ , ti eeyan mẹrinla mii si farapa.
Isẹlẹ naa waye lasiko ti ileeṣẹ ologun n gbe ogun ti awọn janduku to n da agbegbe ijọba ibilẹ Safana.
Nachade – Orilẹede Niger, ogunjọ oṣu keji, ọdun 2022.
Ninu isẹlẹ miiran, ileeṣẹ ologun Naijiria sesi sekupa ọmọde meje , ti eeyan marun un si farapa ninu ikọlu to waye ni agbegbe Maradi lorilẹede Niger , gẹgẹ bi Gomina agbegbe ṣe sọ fun Ileeṣẹ iroyin Faranse.
Gomina Maradi, Chaibou Aboubacar ni ado oloro ti ileeṣẹ ologun Naijiria sọ si agbegbe sekupa awọn ọmọde ni abule Nachade.
Gomina ni oun ro pr awọn ọmọ ogun Naijiria sesi sọ ado oloro si aarin awọn ọmọde ninu igbinyanju wọn lati kọlu awọn janduku to kọja ni ẹnu ibode orilẹede mejeeji.















