Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí ní Mauritius r'ẹ́wọ̀n ọdún márùn ùn he lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ

Aworan aarẹ tẹlẹ Mauritania

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile ẹjọ kan ni Mauritania ti ran aarẹ tẹlẹ Mohamed Ould Abdel Aziz lẹwọn ọdun marun un lori ẹsun ajẹbanu.

Ileẹjọ ni o jẹ bi ẹsun yi ati lilo ipo rẹ lọna ti ko tọ lati fi da ararẹ lọla ṣugbọn wọn ni ko jẹbi awọn ẹsun mii.

Ileẹjọ naa tun ni ki wọn gba gbogbo ọrọ to ko jọ lọna ti ko tọ.

Aziz ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin ni wọn yan sipo aarẹ lọdun 2009 lẹyin to yẹ aga nidi Sidi Ould Cheikh Abdallah ninu iditẹgbajọba.

Lati igba naa lo si ti n dari Mauritania titi di ọdun 2019.

O n ṣẹjọ lolu ilu ilẹ naa Nouakchott, lati oṣu kini pẹlu awọn eekan mẹwaa mii to fi mọ olotu ijọba tẹlẹ meji ati awọn minisita mii to jijọ ṣe ijọba pẹlu rẹ.

Gbogbo wọn ni wọn fẹsun orisi kan to fi mọ aṣilo ipo kiko owo jẹ lilo ọrọ ilu lati fi da ara wọn lọla ati lilo ipo lati fi ri oju rere gba.

Ile ẹjọ to gbẹjọ wọn yi jẹ eyi to da lori ajẹbanu ati iwa jgudujẹra.

Lọjọ Aje lo si da awọn ti wọn fẹsun kan pẹlu aarẹ lẹwọn ti wọn naa bo ti lẹ jẹ pe ti wọn ko to ti aarẹ Aziz.

Olootu ijọba meji ati awọn Minisita ti wọn jijọ n gbẹjọ wọn ni ileẹjọ ni ki wọn tu silẹ.

Aziz ko sinmi lati maa sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan lasiko ti igbẹjọ n waye.

O ni awọn ẹsun ti wọn fi kan oun lọwọ oṣelu ninu.