Agbẹjọ́rò tó ń ṣ'ẹ̀wọ̀n gbére fún pípa ìyàwó rẹ̀ tún ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún 27 he fún ẹ̀sùn ìkówójẹ

Oríṣun àwòrán, US POOL
Agbẹjọro ni South Carolina lorilẹ-ede America, Alex Murdaugh, to ti wa lẹwọn tẹlẹ lori ẹsun pipa iyawo ati ọmọ rẹ lo ti gba afikun ọdun mẹtadinlọgbọn lori ẹsun ikowojẹ.
Ọkunrin naa lo gba pe lootọ lohun jẹbi ẹsun mejilelogun ti wọn fi kan oun lori iwa jẹgudujẹra ati ṣiṣu owo loṣuka.
Awọn ti Murdaugh ti lu ni jibiti lo waa koju rẹ nile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun ti wọn si bii boya o tilẹ lọkan rara.
Awọn agbefọba ni wọn wi pe ọkunrin naa rawọ ẹbẹ “mo jẹbi” lori ẹjọ mọkanlelọgọrun to nii ṣe pẹlu ọrọ owo ati ipadanu miliọnu mẹjọ to le ẹsun mẹjọ dollr.
Bakan naa ni Murdaugh ji ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dollar nileeṣẹ agbẹjọro rẹ, to si kuna lati san owo-ori to yẹ fun ijọba.
Pupọ ninu awọn owo yii ni Murdaugh na funra rẹ bii ko fi san gbese ati ẹyawo ori kaadi ile-ifowopamọ.
Ninu ọkan ninu awọn ẹjọ ọhun ni awọn agbefọba ti wi pe Murdaugh rin irin afẹ kan to si gba owo rẹ lọwọ onibara rẹ kan.
Owo ti ileeṣẹ adojutofo fẹẹ san fun awọn onibara rẹ ni Murdaugh n gba lọna alumọkọrọyi
Lara ọgọọrọ awọn ti ọkunrin naa lu ni jibiti to wa nile-ẹjọ naa ni awọn mọlẹbi olutọju-ile Murdaugh to ku lẹyin to ṣubu lulẹ.
Olutọju-ile naa, Gloria Satterfield, ni o yẹ ki akọbii rẹ ọkunrin o gba owo ẹmi rẹ lọwọ ileeṣẹ adojutofo.
Awọn agbefọba wi pe owo naa to to miliọnu mẹta abọ dollar ni Murdaugh dari rẹ sinu asunwọn ara rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe Tony, to jẹ akọbi arabinrin naa wi pe igbagbọ oun ti mu ki oun fori ji Murdaugh lẹyin to paro, jale, to si tun yan idile oun jẹ, aburo rẹ obinrin, Ginger Harriot Hadwin, wi pe, bi Murdaugh ko ṣe ro ti ifẹ ati ifarajin iya awọn fun mọlẹbi rẹ ni ko ye oun to.
Obinrin kan naa wi pe igba meji ọtọọtọ ni Murdaugh yan idile oun jẹ. Igba akọkọ ni ọdun 2010 ti ọmọ oun ko lee rin mọ lẹyin ijamba ọkọ ati nigba ti ọmọ naa ku.
Ọkunrin kan naa wi pe owo tawọn adojutofo san lẹyin ti oun farapa ninu ijamba ọkọ to mu ẹmi iyawo oun lọ ni 2011 ni Murdaugh gba lẹyin oun to si naa.
'Mi o ri iru ẹda bii Murdaugh ri'
Lakoko igbẹjo lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan ọkunrin naa ni awọn agbẹjọro ti wi pe awọn funra pe niṣe lo pa iyawo ati ọmọ rẹ lati fi boju iwadi iwa jẹgudujẹra rẹ ati lati fi waa aanu latọwọ awọn araalu.
Lẹyin ti wọn ti daa lẹbi ẹsunipaniyan naa ni Murdaugh ti n koju oniruuru ipẹjọ latọwọ awọn to lu ni jibiti ti wọn si ni awọn fẹẹ gbowo awọn pada.
Ṣaaju idajọ rẹ lọjọ Iṣẹgun, Onidajọ Clifton Newman lo wi pe ẹda to yatọ to si lọkan ni Murdaugh nitori awọn iwa to hu ni koo ṣee ro lọkan ati pe oun ko ri irufẹ ẹda bẹẹ ri.












