Wo ọ̀nà tí o lè gbà láti kópa níbi àpérò COP28 ní Dubai làí tẹ̀lé ìjọba

Oríṣun àwòrán, Presidency Nigeria
Ariwo ṣi n gbode kan kaakiri Naijiria nipa iye aṣoju to wa nibi ipade apero oju ọjọ (COP28) nilu Dubai lorukọ Naijiria.
Amọṣa ijọba Naijiria ti ṣe alaye pe okoolerinwo ati meji eeyan lo wa lọrun ijọba ninu eeyan ẹgbẹrun kan ati irinwo le mẹrinla to wa nibi apero naa lati Naijiria.
Awọn ọmọ Naijiria kan ṣi n beere boya eeyan le bawọn peju sibi ipade naa lai tẹle ijọba orilẹede kankan.
Ninu iwadi ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba, ohun ti a ri ni pe o ṣeeṣe fun eeyan lati kopa nibi apero naa lai tẹle ijọba.
Amọ, gbogbo awọn wọnyi naa ni wọn yoo kọ orilẹede ti wọn ti wa silẹ.
Yatọ si awọn adari ati oṣiṣẹ ijọba, to fi mọ gbogbo awọn tijọba orilẹede abi ilu kan ba ko lẹyin, oriṣiriṣi awọn ajọ aladani, ileeṣẹ idokowo, gbajugbaja oniṣowo, ajafẹtọ ayika ati oju ọjọ, akọroyin, atawọn miran bẹẹ ni wọn lee forukọ silẹ lati wa nibi ipade naa.
Nibi ipade COP28 to n lọ lọwọ, awọn oniṣowo pataki kọọkan kaakiri agbaye, awọn ileeṣẹ to lorukọ, awọn ileetaja, ọdọ, akọroyin ati ajafẹtọ lo wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe o loju ibi ti onikaluku ti lee kopa.
Ọpọ awọn lajọlajọ jakejado agbaye naa si ni wọn maa n fun awọn eeyan lanfani iforukọsilẹ pẹlu owo owo iranwọ lati lee wa nibi ipade ọhun.
Bii apẹẹrẹ, “Media for Environment, Science, Health and Agriculture (MESHA)” ati “Climate Tracker” n fun awọn akọroyin lanfani lati bawọn peju sibi apero naa lati lee jabọ nipa gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ nibẹ.
Bẹẹ naa ni awọn miran wa kaakiri ẹka miran to tun pese aaye ati iranwọ fun awọn eniyan lati lee wa nibi ipade ọhun.

Oríṣun àwòrán, CLIMATETRACKER.ORG

Oríṣun àwòrán, IJNET.ORG
Eeyan melo ni Naijiria n ko lọ si ipade yii tẹlẹ?
Ninu akọsilẹ kan ti StatiSense filede loju opo X, Naijiria ni ko tii ko ju ọgọfa eeyan lọ ibi ipade apero oju ọjọ lati ọdun mẹwa sẹyin.
Igba akọkọ ti Naijiria yoo si ko eeyan ọgọfa lo ni ọdun 2022 ti ipade naa waye lorilẹede Egypt.
Alaye ibi ti ipade naa ti waye laarin ọdun mẹwa sẹyin ati oye aṣoju ti Naijiria ran lọ ree:
2013 [COP19] ni Poland: Aṣoju mọkandilaadọta (49 )
2014 [COP20] ni Peru: Aṣoju aadọta (50)
2015 [COP21] ni France: Aṣoju mẹtadinlaadọta (87)
2016 [COP22] ni Morocco: Aṣoju mọkanlelọgọrin (81)
2017 [COP23] ni Germany: Aṣoju mẹrindinlaadọta (46 )
2018 [COP24] ni Poland: Aṣoju mẹtadinlaadọfa (107)
2019 [COP25] ni Spain: Aṣoju mẹtalelaadọta (53)
2021 [COP26] ni UK: Aṣoju mẹtadinlaadọrun (87)
2022 [COP27] ni Egypt: Aṣoju Ọgọfa (120)
2023 [COP28] ni UAE: ẹgbẹrun kan ati irinwo le mẹrinla (1,411) amọ ijọba apapọ Naijiria ti ṣalaye pe okoolerinwo ati meji (422) ni awọn ko lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












