Èèyàn 422 ni a kó lọ síbi àpérò àyípadà ojú ọjọ́ COP28 ní Dubai, kíì ṣe 1,411 – Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, getty Images
Ijọba apapọ ti sọ pe eeyan 422 pere ni oun ran lọ sibi apero ayipada oju ọjọ COP28 to n lọ ni Dubai, kii ṣe 1,411 gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ.
Minisita fun eto iroyin ni Naijiria, Mohammed Idris lo sọ bẹe ninu atẹjade kan lẹyin ti awọn araalu atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ijọba lori ọpọ ero to ko lọ sibi apero naa.
Ọjọ kọkọnadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii ni Aarẹ Bola Tinubu tẹkọ leti lọ siluu Dubai fun apero ọhun, ti igbagbọ si wa pe yoo pada wale lọjọ kejila, oṣu Kẹjila.
Họwuhọwu ti kọkọ n waye lori iye ọmọ Naijiria to lọ sibi apero naa, to jẹ iye kan naa pẹlu orilẹ-ede China.
Eyii lo mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa binu pe kii ṣe asiko yii ti gbogbo nnkan le koko le yẹ ki ijọba apapọ maa fi owo ilu ṣofo.
Ṣaaju ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP ati Labour ti kọkọ ke si ijọba apapọ pe ko fi orukọ awọn to ṣagbatẹru wọn lọ sibi apero ọhun lede.
Amọ nigba ti minisita Mohammed Idris n sọrọ, o ni iye awọn to ṣoju Naijiria wa ni ibamu pẹlu ipo ti Naijiria wa nilẹ adulawọ ati ipa to n ko lori ọrọ ayipada oju ọju ọjọ.
O ni “Apapọ iye eeyan ti jọba apapọ ṣagbatẹru wọn lọ sibi apero naa jẹ 422, awọn eeyan naa ree.”
“Awọn ọmọ igbimọ lori ọrọ ayipada oju ọjọ = 32
“Ileeṣe ijọba to n ri si ọrọ ayika = 34
“Gbogbo awọn minisita = 167
“Awọn oṣiṣẹ Aarẹ = 67
“Awọn aṣoju lati ọọfisi igbakeji Aarẹ = 9
“Aṣoju lati ile igbimọ aṣofin = 40
“Aṣoju lati awọn ileeṣẹ ijọba apapọ = 73.”
O pari ọrọ rẹ pe awọn to lọ sibi ipade naa ko lọ ṣere tabi ṣe faaji rara, iṣẹ ilu ni wọn lọ ṣe nibẹ.
Wo owó gọbọi táwọn tó dípò ìjọba mú máa ń ná lórí ìrìnàjò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi ajọ Revenue Mobilisation Allocation and Fiscal Commission, RMAFC to jẹ ajọ to n se kokari ohun irinajo fun awọn oṣiṣẹ ijọba ni Naijiria sese agbekalẹ rẹ, minisita ati minisita ipilẹ ni ẹtọ si ẹẹdẹgbẹrun dọla ($900) ni orun ọjọ kan ti wọn ba rin irinajo.
Awọn oludamọran pataki ni ẹtọ si ẹgbẹriin dọla ($800) , ti awọn oludari ẹka ijọba, oluyẹwo ijọba, akọwe, olusiro owo ijọba, awọn akọwe agba ati awọn kọmisona eto idibo INEC ni ẹtọ si ẹẹdẹgbẹrun dọla ($900) fun oorun ọjọ kọọkan.
Pẹlu isiro yii, o tumọ si pe orilẹede n ko owo to le ẹgbẹrun mọkanla ($11,700) jade lori irinajo awọn minisita kọọkan to lọ ṣoju ni ilẹ okere; pẹlu owo to tun le ni ẹgbẹrun mẹwaa ($10,400) fun irinajo awọn onidamọran pataki si ijọba.
Ti a ba yi awọn owo naa pada si owo naira, iye owo fun irinajo awọn minisita yii fun ọjọ mẹtala yoo jẹ milọnu mẹwaa naira,
Owo yii le san owo oṣu osisẹ ijọba to wa ni ipele kẹjọ fun ọdun marun un tabi jubẹlọ.
Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria kó èró 1,411 lọ sí àpérò àyípadà ojúọjọ́, COP28 ní Dubai?

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Oniruuru ọrọ lo ti n lọ kiri nipa iye awọn aṣoju ti orilẹede Naijiria ko lọ si ibi apero ajọ iṣọkan agbaye lori ayipada oju ọjọ, COP28 ni Dubai.
Bi iroyin ṣe jade pe eeyan ẹgbẹrun kan ati irinwo o le mọkanla, (1,411), ni iye awọn to n ṣoju Naijiria nibi apero naa ni ọpọ ọmọ Naijiria ti fi igbe ta lori ayelujara pe ki ni gbogbo awọn eeyan naa n fẹ lọ ṣe nibẹ.
Ohun ti ọpọ ninu wọn n ke ibosi le lori ni iye owo ni ijọba Naijiria yoo na lati gbọ bukata awọn eeyan wọnyi.
Gẹgẹ bi akọsilẹ nipa ipa iye awọn aṣoju to wa nibi apero naa ṣe sọ, ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrun ati ọdunrun o le aadọrin ati meji, 97, 372.
Awọn miran ti iye wọn le ni ẹgbẹrun mẹta ni yoo maa darapọ mọ apero naa nipasẹ ayelura.
Eyi ja si pe, apero yii ni apero ti aṣoju ti pọ julọ ninu itan apero ajọ iṣọkan agbaye lori ayipada oju ọjọ.

Oríṣun àwòrán, carbon.org
Awọn orilẹede wo lo ni aṣoju to pọ julọ?
Gẹgẹbi akọsilẹ awọn to n ṣe agbatẹru apero naa, ati bi carbonbrief.org ṣe fi sita, orilẹede United Arab Emirates to n gba alejo eto naa lo ni aṣoju to pọ julọ.
Ẹgbẹrun mẹrin ati ẹirinwo o le mẹsan an aṣoju lo wa lati UAE.
Lẹyin wọn ni Brazil tẹle pẹlu ẹgbẹrun mẹta ati mọkanlelọgọrin, (3,081).
Lẹyin eyi ni China ati Naijiria ti ọkọọkan wọn fi ẹgbẹrun kan ati irinwo o le mọkanla, (1,411) ranṣẹ

Oríṣun àwòrán, carbonbrief.org
Ki ni àwọn adari ẹgbẹ alatako n sọ?
Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria, lẹyin to fẹsun kan an pe o ko ero 1,411 lọ sibi apero COP28, ni Dubai, United Arab Emirates.
Peter Obi lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo X rẹ lopin ọsẹ.
Obi sọ pe Iye ero kan naa ti ijọba China ko lọ naa ni ijọba Naijiria ko lọ si ibi apero ọhun bo tilẹ jẹ pe aye dẹrun fun awọn eeyan China ju Naijiria lọ.

Oríṣun àwòrán, x/peter obi
O ni “Mo fẹ ki Naijiria ku oriire fun bo ṣe ko iye ero kan naa pẹlu orilẹ-ede China lọ si ipade COP28 to n lọ lọwọ ni Dubai, United Arab Emirates.
“Iye ero to lọ sibi apero ọhun lati Naijiria jẹ 1,411, eyii to jẹ iye eeyan ti China ko lọ.
Obi tẹsiwaju pe China ṣe daadaa ju Naijiria lọ ninu eto iṣuna rẹ fun ọdun 2023 lẹyin to ya $2,860 fun ori kọọkan lorilẹ-ede nigba ti Naijiria, ninu eto iṣuna tirẹ ya $165 kalẹ fun ẹnikọọkan ninu eto iṣuna ọhun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ ọmọ Naijiria lo n gbe ninu iṣe ati iya nigba ti awọn ọmọ China n gbadun, kii si ṣe asiko yii lo yẹ ki ijọba Naijiria maa fi obitibiti owo ṣofo lasiko ti ọpọ araalu n pariwo ebi.
O ni “Ero ti Naijiria ko lọ si apero naa ti pọ ju lasiko yii ti ara n ni ọpọ ọmọ Naiiiria to si ṣoro fun wọn lati jẹun.
“Gẹgẹ bi a ṣe n sọ tẹlẹ, ijọba wa ni lati dẹkun bo ṣe n fi owo ṣofo, a ni lati din iye owo ti a na lori ijọba ku, ki a si ko owo naa lori awọn ohun ti yoo sun Naijiria siwaju.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń bèèrè fún ìfarajìn lọ́wọ́ àwọn tó dipò òṣèlú mú
Bi oṣuwọn afikun ti de ida 27.3% ni oṣu Kẹwa ọdun 2023, eyi to jẹ pe ohun lo ga julọ lati Oṣu Kẹjọ ọdun 2005.
Opọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti n pe fun ifarajin lọwọ awọn oloṣelu to dipo ijọba mu.
Ọpọ idile ko ni anfani lati jẹ ounje to kere ju. Awọn ọlọkọ ti fopin si wiwa ọkọ ayọkẹlẹ ti ara wọn ọ si ibi iṣẹ nitori ọwọngogo iye owo bẹtirool.
Sibẹsibẹ, awọn eeyan n sọ pe ijọba ko ṣe afihan ipele ifarajin ninu dindin bi wọnṣe n na owo ku, paapa awọn awọn owo ti ko ni anfani
Ijọba orilẹede Naijiria nilo idoko oke okun bu eto ọrọ aje GDP orilẹede ggboro si.
Ọpọ n fi ẹhonu han lori ayelujara X ati niluu Dubai. Awọn ọmọ orilẹede Naijiria n reti pe awọn ipade COP28 to waye ni UAE, yoo jẹ ki orilẹede wọgile ofin ti wọn fi de orilẹede awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
Ki ni ijọba Naijiria sọ?

Oríṣun àwòrán, x/bola ahmed tinubu
Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbẹnusọ Aarẹ Bola Tinubu, Temitope Ajayi, ti fesi pe ọrọ naa ko ri bi Obi ṣe sọ.
Ajayi lo fi esi ọhun lede ninu atẹjade kan.
Bo tilẹ jẹ pe ko jiyan pe lootọ ni eeyan 1,411 lọ ṣoju Naijiria nibi apero naa, o ni kii ṣe ijọba Naijiria lo ṣagbatẹru gbogbo eeyan to lọ.
O ni “O ṣe pataki lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe awọn aṣoju lati gbogbo orilẹ-ede, yala lati ọdọ ijọba ni o tabi ileeṣe aladani tabi awọn ẹgbẹ ajafẹtọ to wa nibi ipade COP forukọ sile lorukọ orilẹ-ede wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Wayi o, iroyin ni eeyan 590 ni ijọba Naijiria ṣagbatẹru wọn lọ sibi apero naa, nigba ti Amẹrik ko eeyan 159 lọ, Japan ko ero 255, India ni ero 725 nigba ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ko eeyan 75 pere lọ.
“Eyii ko tumọ si pe gbogbo wọn ni ijọba ko lọ sibi ipade apero naa.
Ipade COP28 ọhun ni awọn olori orilẹ-ede lagbaye ti n jiroro lona ati dojukọ iṣoro ti ayipada ou ọjọ n fa, atawọn nnkan mii.














