Àwọn ọmọ Naijiria 180,000 tó fẹ́ wá sílẹ̀ wa la ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún lọ́dún yìí – Ìjọba Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Faceboo/Joe Biden
Ijọba ilẹ Amẹrika ti sọ pe ko din ni 180,000 ọmọ Naijiria ti wọn ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun lọdun yii latari igbesẹ wọn lati lọ silẹ naa.
Oluṣakoso ọọfisi ijọba ilẹ Amẹrika ni Naijiria, Ọgbẹni David Greene lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria, NAN, niluu Abuja.
O ni “Ohun ti awọn eeyan ko mọ ni pe lọdun yii nikan ṣoṣo, a ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun 150,000 eeyan.
“Mo n sọ nipa awọn to fẹ lọ silẹ wa yatọ si awọn 30,000 mii to fẹ lọ kẹkọọ nibẹ.
“Ẹgbẹgbẹrun awọn akẹkọọ lo ti lanfani lati gba iwe irinna lati ọwọ ijọba ilẹ Amẹrika.
“A n ṣe iwọn ti a le ṣe lati faye gba gbogbo awọn to fẹ tẹkọ leti lọ silẹ wa lẹyin ti a ko le da ọpọ eeyan lohun latari ajakalẹ arun Covid-19.
“A ti ṣe awọn aṣeyọri kan, ninu oṣu Kẹta la ṣe agbekalẹ iwe irina ọlọdun marun un fun awọn arinriniajo si Amẹrika.”
Greene fi aridaju lede pe gbogbo awọn kudiẹkudiẹ to n waye loju ọna ati gba fisa lawọn yoo bojuto.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, laipẹ laijina ni awọn kudiẹkudiẹ naa yoo di ohun atijọ nitori awọn yoo jawe sobi igbiyanju wọn.
Lẹyin naa lo rọ awọn to ba fẹ rinrinajo lọ silẹ Amẹrika ki wọn tete maa gba fọọmu wọn.
O ni “A rọ awọn ti wọn ba fẹ lọ si Amẹrika ki wọn tete fi orukọ wọn silẹ, ki wọn si ri daju pe wọn ni ohun pato ti wọn n fẹ lọ ṣe nibẹ.”














