Wo obìnrin àkọ́kọ́ ní South Africa tó jẹ́ olúkọ́ni nípa wíwẹ́ dé ìsàlẹ̀ odò
Zandile Ndhlovu dagba niluu Soweto, lorilẹede South Africa ni bi ẹnikẹni kolero lati rin irin ajo lọ ẹgbẹrun ọna jinjin lati lọ ma wẹ lodo. Ko si adagun omi gan ni agbegbe naa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu Ileeṣẹ BBC, Zandile Ndhlovu salaye bo ṣe bẹrẹ irin ajo rẹ to fi di akọnimọse ati bio ṣe tayọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ pẹlu bi o ṣe jẹ obinrin ti eeyan dudu.
“Igbagbọ kan wa pe, Eeyan dudu ko ki n wẹ odo, a ki n ṣe nnkan bayẹn,” O salaye.
Fun idi eyi. Zansile ni oun ko gbaradi fun irin ajo rẹ akọkọ niluu Bali, nigba to wa ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn.
“Ọga sọ fun gbogbo wa pe ka dira,” o ranti.

Oríṣun àwòrán, CRAIG KOLESKY
“N ko mọ itumọ mohun ti wọn sọ, n ko mọ ibi ti awọn ohun igbaradi naa wa . Nigba ti mo bẹ somi, ẹru bẹrẹ si ni ma bami. Mo ro pe mo ti n mu omi yo ni.
Sugbọn Ndhlovu ni igba ti ogun ri di joko tan, ọ ri ifọkanbalẹ.
“Mo sọ fun ara mi pe se suuru. Mo n wo oke omi, ohun ti mo ri ya mi lẹnu bi oju sanmọ ṣe ri, ati awọn ẹjẹ odo. O jẹ ohun to rẹwa ti mo ri ni igbesi aye mi.”
Ẹ wo fọnran ifọrọwerọ Zandile pẹlu Ileeṣẹ BBC ni bi to ti salaye bi o ṣe bẹrẹ.

















