Wo àwọn ọ̀nà to lè fi dá ààbò bo ilé rẹ lọ́wọ́ ejò lásìkò ọyẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àsìkò ọyẹ́ ti ń wọlé ní Nàìjíríà àti àwọn ẹkùn ìwọ oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Láàárín oṣù Kọkànlá sí oṣù Kẹta ọdún ni ọyẹ́ fi máa ń mú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè yìí.
Lásìkò yìí gbogbo nǹkan máa ń gbẹ́, tí eruku sì máa gba gbogbo nǹkan.
Yàtọ̀ sí àwọn àìlera tó máa ń sábà ṣe èèyàn lásìkò ọyẹ́, ó jẹ́ àsìkò tí ẹranko afàyàfà, ejò máa ń wọ́pọ̀ káàkiri agbègbè tó fi mọ́ ṣíṣe àwárí wọn nínú ilé nígbà mìíràn.
Kò sí àsìkò tí ejò kìí sán ènìyàn, tí oró rẹ̀ sì lè ṣekúpa ènìyàn tí wọ́n kò bá tètè rí aporó rẹ̀.
Oró ejò ti ṣekúpa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn pàápàá ní àwọn ìgbèríko ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìwádìí fi hàn pé bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn ni ejò máa ń sán ní Nàìjíríà lọ́dọọdún àmọ́ kò fi iye ènìyàn tó máa ń ba lọ múlẹ̀.
Lásìkò tí àwọn ènìyàn bá ń ṣiṣẹ́ nínú oko, dẹ̀gbẹ́ tàbí ṣàdédé tẹ ejò mọ́lẹ̀ tí wọ́n bá ń rìn lọ ni ejò máa ń sán àwọn ènìyàn jùlọ.
Àjọ ètò ìlera àgbáyé, WHO ní bí ènìyàn ọgọ́rùn-ún ló máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn sí oró ejò káàkiri àgbáyé ní ọdọọdún tí àwọn mìíràn sì máa ń tara rẹ̀ di aláàbọ̀ ara.
Àwọn oògùn aporó ejò ni ìwádìí fi múlẹ̀ pé ó lè kojú oró ejò jùlọ àmọ́ wọ́n ṣòro púpọ̀ láti rí.
Iléeṣẹ́ tó ń kó ìròyìn jọ fún Nàìjíríà ṣàlàyé ọṣẹ́ tí ejò ṣe ní ìpínlẹ̀ Gombe àti Plateau látàrí bí kò ṣe sí àwọn aporó ejò káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.
Báwo ló ṣe lè dá ààbò bo ilé rẹ lọ́wọ́ ejò?
Àwọn ejò kò fẹ́ràn ibi tó bá gbóná, ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń sá kúrò nínú igbó lásìkò ọyẹ́ láti wá ibi tó bá tutù ba sí.
Fún ìdí èyí ó ṣeéṣe kí ó máa bá ejò pàdé lọ́sàn-án gangan lásìkò ọyẹ́ nígbà tó bá ń wá ibi tí yóò fara pamọ́ sí.
Àwọn ejò máa ń wá inú ilé tí wọ́n lè sá sí fún ààbò lásìkò ọyẹ́.
Àwọn nǹkan to lè fi lé wọn nílé rẹ rèé:
- Gé gbogbo igbó tó bá wà ní àyíká rẹ nítorí ejò kò fẹ́ràn láti máa dúró sí ibi tó bá wà gbayawu.
- Ṣe àyẹ̀wò gbogbo tó bá lanu kalẹ̀ lára ògiri tàbí ní òrùlé kí ó sì dí gbogbo rẹ̀.
- Jìnà sí kíkó igi tàbí pákó jọ sí ibi kan, ejò fẹ́ràn láti máa fara pamọ́ síbi tó bá dí.
- Ṣọ́ra fún ṣíṣí ilẹ̀kùn àti fèrèsé rẹ sílẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ nítorí àwọn ejò lè gun òkè pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ pẹ̀lẹ́ tí ènìyàn kò sì ní gbọ́ ohùn wọn rárá.
- Kí o tó jókòó sábẹ́ igi, ṣàyẹ̀wò ibẹ̀ dáradára kí o sì ri dájú pé ejò kankan kò máa fi ara pamọ́ síbẹ̀.
- Wo abẹ́ ibùsùn rẹ dáradára kí o tó sùnle.
- Yé gbé ibùsùn rẹ sí ìta tó bá ti di ọjọ́ rọ̀.
- Ra àwọn oògùn tó máa ń lé ejò jìnà sílé.
Àwọn ìgbésẹ̀ tó o lè gbé rèé tí ejò bá sán ènìyàn
- Ẹ fún ẹni tí ejò bá sán ní oògùn aporó láti dín ìrora kù.
- Ẹ yọ gbogbo aṣọ tó bá fún lára ẹni náà kúrò.
- Kí onítọ̀hún tètè gba ilé ìwòsàn lọ fún ìtọ́jú tó péye.















