Babalawo tó di pásítọ̀ fún ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn pa l’Ekiti, ó dèrò àtìmọ́lé

Prison

Oríṣun àwòrán, Pexels/Kindel Media

Pasitọ kan, Abiodun Sunday, ti dero atimọle ọlọpaa niluu Ido-Ile, nipinlẹ Ekiti lori ẹsun pe o ṣekupa iyawo rẹ.

Iroyin ni pasitọ naa ti fi akoko igba kan jẹ babalawo ri, ko to bẹrẹ si n ṣiṣẹ oluṣọ agutan ninu ọkan lara awọn ijọ CAC, ni ori oke Ido, to wa ni ijọba ibilẹ iwọ oorun Ekiti, ki ijọ naa to gba iṣẹ lọwọ rẹ.

A gbọ pe lẹyin ti ijọ CAC da duro lo wu iwa laabi naa.

Ibatan oloogbe iyawo rẹ to ṣekupa, Samuel Ibironke sọ fun awọn akoroyin pe “Lẹyin to pa aburo mi tan, o ke si iyawo mi to jẹ oṣiṣẹ eto ilera lati wa ran oun lọwọ.”

“Igba ti iyawo mi de ibẹ lo ṣakiyesi pe o ti fun aburo mi lọrun pa.”

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn ka oku oloogbe naa mọ afurai ọhun lọwọ lasiko to n gbe jade kuno ninu ilu naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, olori ilu ti iṣẹlẹ naa ti waye, Ọba Aderemi Obaleye bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.

Obaleye sọ pe “Iṣẹlẹ naa buru jai to si ku diẹ ko da ilu wa ru nitori awọn ọdọ fẹhonuha lodi si pasitọ naa.”

“Mo fẹ ki awọn agbofinro ṣe iwadii to peye ki afurasi ọhun si foju wiman ofin ko le kọ awọn ẹlomiran lọgbọn.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣe ọlọpaa Ekiti, DSP Sunday Abutu, to fidi iroyin naa mulẹ fun BC Yoruba ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Abutu ni “O ti wa ni ahamọ wa, a si ti bẹrẹ iwadii, yoo foju bale ẹjọ ni kete ti a ba ti pari iwadii wa.”