Ọ̀pọ̀ àwọn tó wá ń ṣe àyẹ̀wò DNA ni ilé wọn máa ń dàrú – Onímọ̀ nípa àyẹ̀wò DNA
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si n jẹ ọrọ ayẹwo ọrọ DNA lẹnu.
Eyii ko ṣẹyin oniruru iroyin to n gbode kan nipa bi awọn obinrin kan ṣe n gbe ọmọ ale fun awọn ọkọ wọn.
Ṣugbọn ọrọ naa milẹ titi lẹyin iku gbajugbaja olorin takasufe, Mohbad, ati lẹyin eto ori ẹrọ redio kan, nibi ti wọn ti ni obinrin kan gbe ọmọ ale mẹrin fun ọkọ rẹ niluu Ibadan.
Eredi ree ti ikọ ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba fi kan si onimọ nipa DNA, Babatunde Odedele lati tu pẹrẹpẹrẹ nipa ohun gan to n jẹ DNA.
Baba ati iya lo n da DNA jọ fun ọmọ wọn
Odedele ninu alaye rẹ ni DNA jẹ nnkan ti awọn eeyan n fi silẹ lati irandiran.
O ni “Ti atọ baba ati iya ba ti pade ara wọn, wọn ti maa fi ‘DNA material’ kan sibẹ to jẹ pe yoo gbe gbogbo nnkan to jọ mọ ti baba ati iya yẹn pade ara wọn.”
“Awọn mejeji lo jọ n bun ọmọ wọn ni ẹya DNA naa, bo dẹ ṣe maa wa niyẹn titi lati irandiran.”
Yatọ si awọn eeyan, o ni awọn kokoro aifojuri naa maa n ni ẹya DNA lara.
Eredi ti awọn fi n ṣe ṣayẹwwo DNA

Oríṣun àwòrán, getty images
Odedele ṣalaye pe ọpọ eeyan lo maa n ṣayewo DNA fun ibalẹ ọkan ninu idile wọn.
Yatọ si eyi, o ni awọn mii maa n ṣe ayẹwo naa nigba ti ọrọ ile ẹjọ ba ṣẹlẹ.
“Ẹlomiran maa n ṣe ayẹwo ti wọn ba fẹ pe awọn ọmọ wọn wa lati Naijiria silẹ UK... wọn le sọ pe ki wọn ṣe DNA ti ọmọ lati fi mọ boya ọmọ wọn ni ẹni ti wọn fẹ pe wa.”
Bawo ni wọn ṣe n ṣe ayẹwo DNA?
Gẹgẹ bii ohun ti Odedele sọ, oniruru ọna ni wọn fi n ṣe ayẹwo DNA.
“Nigba miran ti a ba fẹ ṣe ayẹwo fun baba ati ọmọ, kọrọ ẹrẹkẹ wọn ni a maa ko... a maa ko ti baba ati ọmọ sinu apo ọtọtọ”
O fi kun pe lọpọ igba ti awọn eeyan ba ṣe ayẹwo DNA naa ti esi rẹ ko si lọ bi wọn ṣe fẹ, niṣe ni ile wọn maa n daru ti tọkọtaya to ṣe ayewo ọhun si maa tuka.
Amọ nigba ti ayẹwo naa ba lọ bi idile to ṣe ayẹwo ṣe fẹ, niṣe ni inu awọn to ṣe ayẹwo naa maa n dun.
Wo fidio oke yii fun alaye lẹkunrẹrẹ nipa awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa DNA ati ayẹwo rẹ.



