Mọ́ṣọ́láṣì ìlú Inisa jẹ́ ṣíṣí lẹ́yìn ọdún mẹ́ta

Niṣe ni idunnu ṣubu layọ fun awọn Musulumi ilu Inisa ni ijọba ibilẹ Odo-Otin, ipinlẹ Osun bi wọn ṣe ni anfani lati tun ki irun Jimọ ni Mọṣalaṣi nla ilu naa lẹyin ọpọ ọdun.
Ọdún Kẹta ree ti Mọsalasi ìlú Inisa ti wa ní títì pa latari ifanfa kan to waye nibẹ.
Iwadii BBC News Yoruba ṣafihan pe lákòókò tí wọn fẹ yan Imam agba Mọsalasi naa iyẹn Chief Imam ni awuyewuye bẹ silẹ laaarin awọn to fẹ jẹ oye ọhun.
Èèyàn Márùn-ún, gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, lo díje fún ipo Chief Imam lákòókò náà.
“Èmi lo tọ si” ni nnkan ta gbọ pe o fà ìjà láàárín wọn.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe àwọn méjì ninu àwọn márùn-ún to ń dùn ipo náà ti pàdánù ẹ̀mí wọn bayii.
Ifanfa yii to bẹrẹ lọdun 2020 mu ki igbimọ mọṣalaṣi naa pinnu lati ti mọṣalaṣi naa fun igba kan na titi ti wọn fi maa wa ojutuu si laasigbo to n waye naa.
Lati igba naa ni mọṣalaṣi naa ti wa ni titi pa ti wọn ko si kirun nibẹ.
Ta ni ipo Chief Imam Inisa tọ si gan?
Gẹgẹ bi iwadii ti fidi rẹ mulẹ, kii ṣe wi pe idile kan lo maa n jẹ oye Chief Imam ni ilu Inisa.
Wọn ni bi awọn Alfa to wa ninu ilu ba ṣe ni imọ si ni wọn fi maa n yan wọn si ipo naa.
Wọn ni ọba ilu naa yan ẹnikan lọdun 2020 ṣugbọn awọn eniyan ilu ọhun ni awọn ko faramọ onitọhun.
Eyi lo si mu ki awọn Alfa miiran to wa ninu ilu naa dide pe ipo naa tọ si awọn nitori awọn naa ni imọ ati amuyẹ lati dipo naa mu.
Bi awọn eniyan naa si ti jade ni ikunsinu ati awuyewuye bẹrẹ lori ipo ọhun ti wọn si wọ ara wọn lọ si ile ẹjọ.
Lati igba naa ni igbẹjọ ti n waye lori ọrọ naa ti wọn ko si tii fi ẹnu rẹ gun ibi kan.
Amọ lẹyin ti Alfa kan atawọn olori ẹsin kaakiri da si ọrọ naa, awọn igbimọ mọṣalaṣi naa pinnu lati bẹrẹ si ni kirun ninu mọṣalaṣi titi igbẹjọ maa fi pari ni ile ẹjọ giga Osogbo ti ile ẹjọ maa kede ẹnikan bii ẹni to maa jẹ Imam.
Eyi lo mu wọn ṣi mọṣalaṣi naa ọjọ́ Kìíní oṣù Kejìlá ọdún 2023 ti awọn musulumi ilu naa si kirun Jimọ nibẹ.

Ẹni to jẹ agbenuso fún ẹgbẹ Musilimu ni Ìpínlẹ̀ Osun, Malam Abdulganiyu Olaide sọ fun BBC News Yoruba pe Imam Agba tí ìlú Osogbo, Alhaji Animasahun tí fi ìgbà kan yan ẹni ti yoo maa kirun ni Mọṣalaṣi naa ṣùgbọ́n ko tan iṣoro to wa nilẹ.
Olaide sọ afọmọ rẹ pe loootọ ni meji ninu awọn to n wa ipo naa ti jade laye amọ kii ọrọ oye ni wọn pàdánù ẹ̀mí wọn si.
O ni ọrọ naa ṣi wa nile ẹjọ́ gíga tí Osogbo bayii ati pe ile ẹjọ́ ni yoo sọ ẹni to tọ si ipo Chief Imam ṣùgbọ́n báyìí irun kiki tí bẹ̀rẹ̀ pada.
O fi kun pe awọn ti pinnu lati maa fi Imam ranṣẹ si ilu naa lati awọn ilu to sunmọ ibẹ titi ti ile ẹjọ yoo fi pari igbẹjọ lori ẹni ti Imam naa tọ si.
Lati ilu Ede ni wọn ti yan ẹni to ṣe Iman fun wọn bi wọn ṣe ṣi mọṣalaṣi naa lọjọ Ẹti.
Imam Abdullahi Olorunlomoerue, to kirun naa ni ko si ìjà mọ rárá, ṣùgbọ́n àwọn yoo fi orikori láti yan ẹnikan tí yoo jẹ́ adari irun ni Mọsalasi Inisa ki ẹjọ to pari.
O ni kí se pe ìjọba tí Mọsalasi náà pa ṣùgbọ́n ki àlàáfíà le jọba nilu Inisa àti láàárín àwọn Musulumi nilu náà ni ó jẹ ko wa ni tiiti pa lati ọdun 2020.















