Ọlọ́pàá wa'kọ̀ pa akẹ́kọ̀ọ́ kan l'Ogun, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta míì farapa

Oríṣun àwòrán, getty/bbc
Akẹkọọ ile ẹkọ girama kan nipinlẹ Ogun ti padanu ẹmi rẹ nigba ti ọkọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ pa.
Akẹkọọ naa Adeleye Eniola la gbọ pe o jẹ akẹkọọ Mayigi Community High School Ilase ni ijọba ibilẹ Ipokia.
Iroyin sọ pe ọlọpaa to fi ọkọ tẹ mọlẹ pa jẹ oṣiṣẹ ẹka ọlọpaa to wa ni Ilaro.
Freedom ni wọn pe orukọ ọlọpaa naa.
Iṣẹlẹ yi mu kawọn ọdọ agbegbe naa kora jọ lati ṣe ifẹhonu han ti awọn to peju lati fẹhonu han si sọ pe ọlọpaa naa n le ọlọkọ kan to kọ lati fun lowo ni lasiko to fi ọkọ tẹ Eniola mọlẹ.
Olori ẹgbẹ ọdọ ladugbo Ipokia Adeyemi Sulaimon wa lara wọn.
O ni ''a gbọ pe ọlọpaa kan lati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ilaro ṣekupa akẹkọbinrin kilaasi SS1 kan ti o si ti na papa bora.''
O fikun pe awọn akẹkọọ kan to ṣe iwọde lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Idi Iroko ṣalabapade iya lọwọ awọn ọlọpaa to lu wọn ti wọn si tun yin afẹfẹ taj taju lu wọn.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun taa ba sọrọ lori ago fidi ọrọ mulẹ pe oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
Awọn ọlọpaa Ipokia ko ṣẹṣẹ maa han araalu leemọ-ẹgbẹ ọdọ Ipokia
Ẹgbẹ awọn ọdọ nilu Ipokia ti akọwe wọn Adeyemi Sulaimon fi atẹjade sita lorukọ wọn koro oju si iṣẹlẹ.
O ni ọjọ ti pẹ tawọn ti n fara da iwa aitọ lọwọ awọn ọlọpaa Ipokia toi ọpọ da lori aibọwọ fun ẹtọmọniyan.
''A ti fidi rẹ mulẹ laimọye igba pe awọn ọlọpaa Ipokia to n duro loju ọna bi igba pe wọn gba idanilẹkọ ọtọ lori ki wọn maa ṣekupa eeyan, maa gba owo lọwọ araalu lọna aitọ ki wọn si maa gba ẹtọ wa lọwọ wa gẹgẹ bi araalu Naijiria''
O ni ọlọpaa to hu iwa yi ti ọpọ mọ si 'Freedom' gbera kuro lati ''Ilaro to si wa hu iwa aburu yi ni Ipokia nitori awọn ọlọpaa ti a arawọn di ẹni ti ko ni onibawi ti wọn a si ma hu iwa to wu wn koda nibi to kọja aaye ti wọn fi wọn si''
O ni awọn ọlọpaa mu lara awn akẹkọọ to ṣe iwọde lọ si agọ ọlọpaa Idi Iroko amọ lẹyin ọpọ ẹbẹ wọn pada tu wọn silẹ.
A gbọ nipa iṣẹlẹ yi,iwadii si ti bẹrẹ-alukoro ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Ayọ̀ Arowojolu
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti akọroyin BBC ni pẹlu alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun Omolola Odutola,o sọ pe oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa amọ oun ko le sọ pato nipa nkan to ṣẹlẹ.
O ni oun naa n gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ lẹnu awọn akọroyin ni amọ o da ohun loju pe iwadii ti n lọ lati fi ma pato bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Nipa ọlọpaa to wakọ pa akẹkọọ yi, esi to fọ ko yatọ to si ni laipẹ awọn yoo jabọ faraalu ibi ti ọrọ de duro nipa iwadii.












