Ẹ bẹ̀rẹ̀ síí tọ́jú àwọn tó ní ọgbẹ́ ìbọn lára láìrí ìwé ọlọ́pàá - Ọ̀gá ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Kayode Egbetokun/X
Ọga agba pata fun ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Kayọde Adeolu Ẹgbẹtokun ti gba gbogbo awọn ile iwosan lamọran lato bẹrẹ sii ṣe itọku awọn to ba ni ọgbẹ ibọn lara lai duro de iwe ẹri lati ọdọ ọlọpaa.
Ẹgbẹtokun lo sọrọ yii ninu atẹjade ti ileeṣẹ agbẹnusọ ọlọpaa, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi gbe jade laarọ oni, ọjọ Abamẹta lo ti sọ fun gbogbo dọkita lati bẹrẹ sii ṣe itọju awọn to ba ni ọgbẹ ibọn lara lai fi asiko ṣofo.
Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe ẹmi eeyan gbọdọ jẹ gbogbo awọn dọkita, paapaa awọn oṣiṣẹ eleto ilera kaakiri Naijiria logun ju ohunkohun lọ.
Ọga ọlọpaa naa sọ pe ọpọ ẹmi lo n ṣofo danu lori ẹsun wi pe wọn ni ọgbẹ ibọn lara, to si ni iwe ofin to de itọju awọn to ba ni ọgbẹ ibọn lara ti ọdun 2017 gbọdọ di mimu lo.
Ninu atẹjade naa, o sọ pe “Lati da ọrọ bi awọn eeyan ṣe n padanu ẹmi wọn lori iwa aimojuto awọn to ba ni ọgbẹ ibọn tabi ijamba, ọga ọlọpaa patapata lorileede yii, IGP Kayọde Adeolu Ẹgbẹtokun ti parọwa si gbogbo awọn eleto ilera kaakiri Naijiria lati maa ṣe itọju awọn eeyan wọnyi lai duro de esi lati ọdọ ọlọpaa.
“Aṣẹ lati ọdọ ọga ọlọpaa agba yii wa pẹlu ṣiṣe amulo ofin to de awọn to ba ni ipenija ọgbẹ ibọn tabi ijamba yoowu ti ọdun 2017, iyẹn ‘Compulsory Treatment and Care for Victims of Gunshot Act of 2017’, eyi pọn ọn ni dandan fun awọn eleto ilera lati mu ọrọ ẹmi ati itọju awọn eeyan lọkunkundun.”
Ọrọ ọga ọlọpaa yii lo wa lẹyin ti awọn araalu ti ke gbajare lori bi awọn eleto ilera ṣe n yera fun awọn to ba kagbako aṣita ibọn, paapaa l’awọn to n gbe ẹnubode orileede yii.
Bakan naa lo sọ pe bi itọju ba n lọ lori awọn eeyan wọnyi, wọn ni ẹtọ lati tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi wọn leti, lati le dide si iṣẹ iwadii lati mọ ohun to ṣokunfa ọgbẹ ibọn tabi ijamba naa.
Ẹgbẹtokun ni ọna abayọ kan ṣoṣo lati ni agbegbe tabi orileede to ni alaafia ati ilera pipe ni lati bẹrẹ daabo bo ẹmi ati dukia ara wa.
Bakan naa lo tun fidi rẹ mulẹ wi pe awọn yoo bẹrẹ ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn ileeṣẹ loriṣiriṣi lati rii pe ofin naa fi ẹsẹ mulẹ.















