Ìdájọ́ ‘Supreme Court’ já ìrètí ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria kulẹ̀ – PDP

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu and Atiku Abubakar
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, eyii to sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ni ojulowo Aarẹ ti awọn ọmọ Naijiria dibo yan lọdun 2023 jẹ eyii to ja araalu kulẹ.
Ṣaaju ni Atiku Abubaka ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu LP ti kọkọ lọ sile ẹjọ naa lẹyin ti wọn ni idajọ igbimọ to gbọ awuyewuye to waye lasiko eto idibo ọhun ṣaaju ko tẹ awọn lọrun.
Amọ ile ẹjọ to ga julọ naa ti da ẹjọ wọn nu, to si sọ pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ.
Agbẹnusọ PDP, Debo Ologunagba sọ ninu atẹjade kan pe idajọ ile ẹjọ to ga julọ naa ja ireti ọpọ araalu kulẹ.
Ologunagba ni “Iyalẹnu nla ati ijakulẹ ni idajọ ile ẹjọ to ga julẹ jẹ ọhun fun ẹgbẹ oṣelu PDP, gẹgẹ bo ṣe ri fun pupọ ninu ọmọ Naijuiria...”
“O ṣeni laanu fun ijọba awawara pe ile ẹjọ to ga julọ naa kuna lati tẹle alakalẹ ofin, kaka ko ṣe bẹẹ, ni ṣe lo ja ireti araalu kulẹ.”
PDP tun fẹsun kan ile ẹjọ ọhun pe o lọwọ ninu iṣegbe lẹyin irọ.
Ologunagba ni idajọ naa yoo mu ko ṣoro fun awọn araalu lati tẹsiwaju lati maa fi ireti sinu ile ẹjọ Naijiria fun idajọ ododo.
Ọlọ́run la gbọ́kàn lé lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ - Labour Party

Oríṣun àwòrán, Peter Obi and Bola Tinubu
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti da ẹjọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour pe tako idajọ to ni Aarẹ Bola Tinubu ni ojulowo Aarẹ ti araalu dibo yan ninu idibo Aarẹ to waye lọdun 2023 yii.
Awọn olupẹjọ meji, Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour ni wọn pe ẹjọ pe ile ẹjọ gbọdọ wọgile ibo to gbe Tinubu wọle ninu oṣu keji ọdun 2023.
Ninu ẹjọ ti awọn mejeji pe ni wọn ti sọ pe ibo to gbe Tinubu wọle ko waye ni ilana to ba ofin mu, ati pe Tinubu ko lẹtọọ lati du ipo Aarẹ lasiko to jade lati du ipo ọhun.
Ọlọrun nikan ni a fi igbagbọ wa si - Ẹgbẹ oṣelu Labour
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu Labour ti sọ pe ninu Ọlọrun nikan ni igagbọ awọn wa bayii lẹyin idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria naa.
Agbẹnusọ fun ipolongo ibo Aarẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Kenneth Okonkwo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo X rẹ.
O ni “Ile ẹjọ to ga julọ ti da ẹjọ Peter Obi nu lori pe ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ, o si sọ pe ojulowo ni idajọ igbimọ to gbọ awuyewuye to waye lasiko eto idibo to kọja.”
“O jẹ ohun iyalẹnu pe ile ẹjọ naa ko mẹnuba owo itanran $460,000.00 ti ile ẹjọ gbẹsẹle, eyii ti awọn olupẹjọ fi sinu iwe ipẹjọ wọn.”

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Inu mi dun si idajọ ile ẹjọ naa – Tinubu
Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, Aarẹ Bola Tinubu sọ pe inu oun dun si idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria naa, nitori idajọ ọhun waye lai si ojuṣaju kankan.
O ni “Ile ẹjọ to ga julọ naa ṣe agbeyẹwo gbogbo ohun to yẹ ko gbeyẹwo ni ilana ofin lai si ibẹru tabi ojuṣaju kankan.”
“Lai si aniani, idajọ to waye lonii fi han pe ẹka eto idajọ wa mọ ohun ti wọn n ṣe, paapaa pẹlu bi adajọ to ṣedajọ naa ṣe ṣiṣẹ rẹ.”
“Bo tilẹ jẹ pe idajọ oni fi han ni gbangba ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye lọdun 2023, mo fẹ fi da awọn araalu loju pe igbagbọ wa ninu ẹka eto idajọ Naijiria ko yẹ.”
Tinubu fi kun pe idajọ naa fun oun ni iwuri lati tẹsiwaju lati maa sin awọn ọmọ Naijiria.
Lẹyin naa lo ke si gbogbo araalu lati tẹsiwaju lati maa gbe ni isọkan ati alaafia lai si ikunsinu kankan.
Atiku àti Obi lulẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ilé ẹjọ́ Supreme ní ẹ̀bẹ̀ wọn kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Collage
Igbẹjọ to tako esi ibo Aarẹ lorilẹede Naijiria ti waye lonii niluu Abuja.
Awọn olupẹjọ mejeeji, Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ati Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni wọn pe fun pe ileẹjọ wọgile ibo to gbe Tinubu wọle ninu oṣu keji ọdun 2023, pe ko waye ni ilana to ba ofin mu.
Ẹgbẹ mejeeji ni Tinubu ko lẹtọ lati dije fun ipo aarẹ lasiko to jade dupo.
Atiku lo n rọ ile ẹjọ Supreme lati tẹwọgba awọn ẹri to gba lati ile ẹkọ Fasiti Chicago State University wọle, eyi to safihan iwe ẹri Tinubu.
Ile ẹjọ to ga julọ naa si ti wọgile ipe oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, o ni pe ko le gbe ẹri tuntun mii, eyi to tako Aarẹ Bola Tinubu wa sile ileẹjọ.
"Ile ẹjọ to ga julọ ko ni asẹ lati tẹwọgba ẹri tuntun ti Abubakar Atiku gba ni fasiti Chicago State University (CSU)"
Igbimọ ẹlẹni meje to n gbe idajọ naa kalẹ, eyi ti Adajọ John Okoro ko sodi, salaye pe ipe Atiku lodi si iwe ofin idibo ilẹ wa.
Adajọ Okoro wa mu ẹjọ naa lẹsẹẹsẹ, to si n kede ohun ti ile ẹjọ to ga julọ naa fẹnu ko le lori.
Okoro ni ko seese lati fi ẹri tuntun si ẹbẹ olupẹjọ lẹyin ti ileẹjọ to n gbọ awuyewuye ba ti gba ẹri rẹ tan, a tun ṣe si eyi ko gbọdọ waye.
"Ile ẹjọ to ga julọ ko ni asẹ lati tẹwọgba ẹri tuntun ti Abubakar Atiku, tii se oludije fẹgbẹ oselu Labour gbe wa siwaju wọn lati fasiti Chicago State University (CSU)."
“Ẹri nipa idibo ni ipenija tirẹ. Ile ẹjọ to wa ni isalẹ ti padanu anfani lati fọhun lori ẹri yii, gbedeke ọjọ mejilelọgọsan lati gbe ẹjọ tako esi ibo ti kọja lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan an.
Ileẹjọ yii ko le ṣe nnkan ti ileẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo kọ lati ṣe ni ilana pẹlu ofin orilẹede Naijiria,” Adajọ Okoro salaye siwaju.
Ileẹjọ Supreme si n wa awọn ọrọ mii to n fa awuyewuye ti awọn olupẹjọ pe ati eyi to jẹ mọ ti Aarẹ Tinubu.
Paapa eyi to ni ajọ eto idibo kọ lati n tẹle ofin ati ilana ti wọn gbe kalẹ ninu eto idibo, ti wọn si kede ẹni to bori.
"Ko pọn dandan ki oludije sipo aarẹ ni ida mẹẹdọgbọn ibo nilu Abuja"
Bakan naa ni ileẹjọ to ga julọ nilẹ wa kede pe ko pọn dandan ki oludije sipo aarẹ ni ida mẹẹdọgbọn ibo nilu Abuja, tii se olu ilu ilẹ wa, ko to wọle sipo aarẹ.
Adajọ Okoro ni oun faramọ ipinnu ileẹjọ Kotẹmilọrun lori ọrọ yii.
O fikun pe ti oludije sipo aarẹ kan ba ni ipo to pọ kaakiri awọn ipinlẹ , ti ko si ni ida mẹẹdọgbọn ibo nilu Abuja.
O ni eyi ko yẹ ko sediwọ fun iru oludije bẹẹ lati di aarẹ Naijiria.
Ile ẹjọ yi ẹbẹ Peter Obi danu, o ni idajọ to wa fun Atiku, naa lo wa fun Peter Obi
Bakan naa ni Ile ẹjọ wọgile ẹbẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, to si ni ko lẹ nlẹ rara.
Adajọ Okoro, lẹyin to kede idajọ rẹ lori ẹbẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lo bọ si ti Peter Obi.
Ileẹjọ jẹ ko di mimọ pe pupọ awọn ẹbẹ ti Obi gbe wa sile ẹjọ to ga julọ naa, ni ko yẹ ki ileẹjọ da si lẹyin ti Ile ẹjọ kotẹmilọrun to gbọ awuyewuye lori esi idibo ti gbe idajọ rẹ kalẹ.
Adajọ Okoro ni; “Igbesẹ Ileẹjọ lori ẹsun mẹrin ti Obi fi kan igbakeji aarẹ, Kazzim Shettima lori pe wọn fa kalẹ ni ẹẹmeji, ileẹjọ yii ko le fi aye gba ka jiroro lori ẹbẹ yii.”
Ileẹjọ wa yii ẹjọ naa danu, to si ni idajọ to wa fun Atiku, naa lo wa fun Peter Obi
Gbogbo awọn adajọ yoku ni ile ẹjọ Supreme ni awọn faramọ idajọ Adajọ Okoro lori bo se yi ẹbẹ Peter Obi danu.
















