Ìrọ̀lóyè Ghandi ti dá ògo àti orúkọ rere ìdílé wa padà – Ìdílé Laoye

Aworan Oba Ghandi Laoye

Idile Laoye niluu Ogbomos o ti sọrọ lori igbejọ ile ẹjọ to rọ Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye loye gẹgẹ bii Soun tuntun.

Ninu atẹjade ti akọwe idile naa, Ọmọọba Saka Olabode Olaoye fi lede fun awọn akọroyin lọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa sapejuwe idajọ naa gẹgẹ ohun to wu ni lori pupọ, to si ti da ogo ati orukọ rere idile naa pada.

Olaoye ni idajọ baa to waye ko jẹ ohun tuntun, to si tun kan sara si adajọ K.A Adedokun fun bi o ṣe ri pe idajọ ododo waye lori iyanisipo Soun Ogbomoso.

Atẹjade naa ni “Yiyọ Pasitọ Ghandi nipo ti da ogo, iyi ati orukọ rere idile wa pada, inu wa si dun si.

“Idajọ yii ko ki n ṣe ohun to jọ Pasitọ Ghandi loju tabi ya lẹnu.

"Ohun ti ko ye wa ni bo ṣe kuna lati tẹle asẹ ile ẹjọ ati idi ti ijọba ipinlẹ Oyo ṣe sure lati kede rẹ gẹgẹ bi Ọba saaju ki idajọ ana to waye.”

Idile Olaoye tẹsiwaju pe gbogbo ireti awọn ni pe ẹnikẹni to ba ti lo ọpọlọpọ ọdun loke okun ni ilẹ Amẹrika yẹ ko ṣe aponle fun ile ẹjọ ṣugbọn o jẹ ohun iyalẹnu fun awọn.

O wa fidi rẹ mulẹ pe idile Olaoye ko ṣetan lati tako asẹ ileẹjọ to gbe kalẹ lori ọmọ idile awọn.

"Ghandi kọ lati ṣe gbogbo etutu jijẹ Oba ni idilẹ Laoye"

Ọmọọba Saka wa jẹ ko di mimọ pe Ọba Ghandi Laoye kọ lati ṣe ohun to jọmọ etutu ti jijẹ Ọba dirọ mọ ni idile Laoye, to si jẹ pe ko sisẹ pọ pẹlu mọlẹbi rara ninu irinajo rẹ.

“Laoye kọ lati ṣe gbogbo ohun etutu ti a fi n yan Ọba ni idile Laoye, bakan naa lo kọ lati tẹle ilana idile, to si ro pe oun le lo ara ita lati gba ọna eburu pe ko jẹ pe oun ni idile Laoye tẹwọgba gẹgẹ bi aṣoju wa.

“O kuna lati tẹle asẹ ti ile ẹjọ gbe kalẹ.”

O tẹsiwaju pe awọn ti gbọ pe Pasitọ Ghandi ni anfani lati lọ si ile ẹjọ kọtẹmilọrun sugbọn o ya awọn lẹnu pe o fẹ lọ si ile ẹjọ ti o kọ lati tẹle asẹ rẹ saaju ko to jẹ Ọba.

Atẹjade naa ni asẹ ileẹjọ tumọ si pe ki Ghandi kuro ile Ọba laarin wakati mẹrinlelogun, ko si tun dẹkun lati ma safihan ara rẹ gẹgẹ bi Soun ti ilu Ogbomoso.

A kesi Makinde lati ṣe iwadii awọn afobajẹ to gba abẹtẹlẹ niluu Ogbomoso

Ọmọọba Saka Laoye ni bi Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ṣe ṣe ikilọ pe oun yoo ransẹ pe awọn ọtẹlẹmuyẹ lati ṣe iwadii lori afọbajẹ tabi ọmọ oye to lọwọ nini fifun tabi gbigba riba ninu yiyan ipo Ọba Alaafin niluu Oyo naa ni awọn araalu Ogbomoso n kesi lati wa ṣe iwadi awọn afọbajẹ niluu Ogbomoso.

“Bi Makinde ṣe fẹ ṣe iwadii awọn afobajẹ ati ọmọọba niluu Oyo lori iyansipo Alaafin naa ni a fẹ ko wa ṣe niluu Ogbomoso lẹyin ti a fi to wọn leti pe ko ki n ṣe ẹni ti a fa kalẹ ree.”

O ni ohun to waye nipa ikede Ghandi ati rirọ loye ti di ohun igbagbe ni idile Laoye.

“Idile Laoye ko ki n ṣe fun tita , a o ṣe ohun to tọ, ti a o si pese ọmọ oye to kaju rẹ eyi ti gbogbo mọlẹbi fọwọsi kalẹ, ti yoo tẹle aṣa ati ise idile wa, ti yoo si tun bọwọ fun ofin Naijiria.”