Kó ọ̀rọ̀ tí o sọ jẹ, tọ̀rọ̀ àforíjìn tàbí kí o fipò akọ̀wé àgbà àjọ UN sílẹ̀ - Israel fọnmú

Aworan Antonia Guterres

Oríṣun àwòrán, EPA

Orilẹ ede Israel ti sọ pe ki akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye UN, Antonio Guterres ko ọrọ to sọ nipa ogun to bẹ sílẹ̀ ni Gaza jẹ, ki o si tọrọ aforijin.

Lọjọ Isẹgun ni Ọgbẹni Guterres bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu Hamas sí Israel ni bii ọsẹ meji sẹyin nigba to n sọrọ nibi ipade awọn alaṣẹ eto abo ajọ UN.

Amọ, Guterres fikun ọrọ rẹ níbẹ pe ikọlu ọhun ko ṣadeedee waye.

Eleyii lo jẹ ki aṣoju ijọba Israel, Gilad Erdan fẹsun kan Guterres pe o n wi awijare fun igbesunmọmi ti o sí ni ki o kọwe fipo silẹ.

Ọgbẹni Guterres kọ eti ikun si ọrọ yii ni Ọjọru.

Guterres kọminu lori bi Israel ṣe n yin ado oloro ni mẹsan an, mẹwaa si Gaza, ti ọpọ eeyan si n ku

Amọ, aṣoju orilẹ ede Israel tun dahun pe Guterres ti yi ọrọ to sọ pada, o sí tun rọ ọ pe ki o kọwe fipo silẹ.

Ni ọjọ keje oṣu Kẹwaa ni Hamas ṣe ikọlu sí apa guusu Israel nibi ti o kere tan eeyan 1,400 ti ku ti wọn sí ji eeyan 222 gbe lọ.

Ẹwẹ, ẹka eto ilera Hamas sọ pe ko dín ni eeyan 6,500 to ti ku ni Gaza lati igba ti Israel ti bẹrẹ si ni yin ado oloro sibẹ.

Nigba ti o n sọrọ nibi ipade awọn alaṣẹ eto abo ajọ UN niluu New York l'Amẹrika, Guterres rọ awọn igun mejeeji to n ja pe ki wọn daabo bo awọn araalu.

Guterres tun sọ pe oun n kominu lori aibọwọ fun ofin agbaye lori ẹtọ ọmọnìyàn pẹlu ohun to n ṣẹlẹ lọwọ ni Gaza.

Guterres tun kọminu lori bi Israel ṣe n yin ado oloro ni mẹsan an mẹwaa si Gaza ti ọpọ eeyan si n ku.

Bakan naa lo sọ pe lilo awọn eeyan lo lati maa fara wọn gba ọta ko tumọ si didaabo bo wọn.

O sọrọ yii lai darukọ ẹgbẹ Hamas.

Aworan iparun ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Photoshot

Akọwe agba ajọ UN tun bẹbẹ pe ki wọn jẹ ki ogun o mi ki àwọn èèyàn le ni anfaani lati mu iranwọ lọ sí Gaza, ati lati jẹ ki awọn ti wọn jigbe gba ominira.

Amọ, aṣoju ijọba orilẹ ede Israel, Ọgbẹni Erdan ni ìtiju lo jẹ fun ajọ UN pe akọwe agba rẹ ko ko ọrọ rẹ jẹ ati pe o tun kọ lati tọrọ aforijin.

Erdan ni akọwe agba UN ti ko mọ ìtumọ siṣekupa awọn alaiṣẹ kii ṣe akọwe agba gidi.