Ipò 120 ni Nàìjíríà wà nínú àwọn orílẹ́èdè tó ń tẹ̀lé òfin, ipò kejì nínú àwọn tí ètò àbò àti àtò rẹ̀ mẹ́hẹ

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/Facebook

Ajọ kan to n ri sí titẹle ofin lagbaaye (World Justice Project) lo fi ọrọ yii lede ni Ọjọru niluu Washington DC lorilẹ ede Amẹrika.

Iroyin naa tun sọ pe, ninu orilẹ ede mẹrinlelọgbọn lati apa ilẹ Afirika to maa n mooru, ti ajọ naa ṣe agbeyẹwo rẹ, ipo kẹtalelogun ni Naijiria tun wa.

Nipa eto abo ati ato, Naijiria lo ṣikeji orilẹ ede to fidi rẹmi julọ.

Ajọ WJP to jẹ aladaani sọ pe lati ọdun 2016 ni titẹle ko ti mulẹ mọ ni ọpọ orilẹ ede ti awọn ṣe agbeyẹwo rẹ.

Ajọ WJP ni oun ṣiṣẹ pọ pẹlu idile to le ni 149,000 ati awọn agbẹjọro 3,400 ki oun to gbe esi yii jade.

"Ni gbogbo agbaye, orilẹede Denmark ni wọn ti n tẹle ofin jùlọ"

Gẹgẹ bi akọsilẹ naa ṣe sọ, awọn nkan bii aisi agbara ijọba, àìsí iwa ajẹbanu, ẹtọ ọmọnìyàn, eto abo ati sisọ ododo wa lara ohun elo fun iwadii naa.

Ipo Naijiria tun já walẹ si ninu ayẹwo naa ni tori pe ipo 118 ni o wa ni ọdun 2022 ninu awọn orilẹ-ede 140 ti wọn ṣe ayẹwo lori wọn.

Ni gbogbo agbaye, orilẹede ti wọn ti n tẹle ofin jùlọ ni Denmark gẹgẹ bi akọsilẹ yii ṣe sọ.

Orilẹ ede Norway lo ṣe ipo keji, Finland lo wa ni ipo kẹta nigbati Sweden ati Germany wa ni ipo kẹrin ati ikarun ùn bakan naa.

Orilẹ ede ti wọn ko ti tẹle ofin jùlọ ni Venezuela, Cambodia, Afghanístàn, Haiti ati DR Congo tẹle e.

Rwanda lo ṣe daadaa julọ pẹlu ipo mọkanlelogoji ninu orilẹede mejilelogoje ti wọn ṣe àgbéyẹ̀wò wọn

Awọn orilẹ-ede apa ilẹ Afirika ti ajọ WJP ṣe àgbéyẹ̀wò wọn ní Angola, Benin, Botswana, Burkina Faso ati Cameroon.

Awọn yoku ni Côte d’Ivoire, Democratic Republic of the Congo, Ethiopia, Gabon, Gambia, Ghana, Guinea, Kenya, Liberia ati Madagascar.

Bakan naa ni ọrọ yii kan orilẹede Malawi, Mali, Mauritania, Mauritius, Mozambique, Namibia, Niger ati Nigeria.

Ayẹwo naa ko si tun yọ orilẹede Republic of the Congo, Rwanda, Senegal, Sierra Leone, South Africa, Sudan, Tanzania, Togo, Uganda, Zambia ati Zimbabwe silẹ.

Rwanda lo ṣe daadaa julọ pẹlu bi o ṣe gba ipo mọkanlelogoji ninu orilẹ ede mejilelogoje ti wọn ṣe àgbéyẹ̀wò wọn.

Namibia lo ṣe ipo keji ti Mauritius sí wa ni ipo kẹta.

Awọn orilẹ-ede Afirika mẹta to fidi rẹmi ni Mauritania, Cameroon ati Congo.