Èèyàn tó lé ní 700 ni àdó-olóró Israel pa lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Gaza - Ẹ̀ka ètò ìlera Hamas

Aworan awon eeyan ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileeṣẹ to n ri si eto ilera ti ẹgbẹ Hamas n ṣakoso rẹ ti sọ pe eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹrin ni orile-ede Israel fi àdó-olóró pa laarin ọjọ kan ṣoṣo.

Ileeṣẹ ọmogun Israel naa sọ pe awọn ti mu irinwo agbasunmọmi balẹ to fi mọ awọn ọgagun Hamas kan laarin ọjọ kan yii.

Ileeṣẹ ọmogun Israel tun sọ oun ko ni dẹkun yinyin ado oloro sí Gaza, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ Hamas ti fi meji silẹ ninu awọn ọmọ Israel ti wọn jigbe.

Ile iwosan mẹta ni Gaza ni ko le ṣiṣẹ daadaa mọ latari ai si ina mọnamọna, oogun at'awọn oṣiṣẹ eleto ilera to fi mọ ai sí omi pẹlu.

Israel bẹrẹ si ni yin ado oloro kọlu ẹgbẹ Hamas eleyii ti wọn ri ati ti orilẹ ede UK, Amẹrika at'awọn alagbara orilẹ ede mii gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi.

Ikọlu yii jẹ esi sí ikọlu ti o waye lọjọ keje oṣu Kẹwaa ninu eyi ti o kere tan eeyan 1,400 ti ku ti 222 si wa ni gbaga awọn ajinigbe.

O din diẹ ni eeyan 5,800 ni wọn ti ku bayii ni Gaza gẹgẹ bii ileeṣẹ to n ri si eto ilera ṣe sọ.

Aworan maapu

Orilẹede Israel yin awọn ado oloro kan lọganjọ oru s'awọn ibikan ni Gaza .

Ọpọ awọn eeyan to ku ni apa guusu nillu Khan Younis ati Rafah lo sa kuro ni apa Ariwa Gaza lẹyin ti ileeṣẹ ọm'ogun Israel kilọ pe ki wọn kuro fun aabo ẹmi wọn.

Mẹtala ninu awọn to ku yii wa lati idile kan niluu Gaza.

Ẹbi wọn kan ti ori ko yọ ṣalaye pe "a n sun lọwọ ni nigba ti a ṣadeedee gbọ iro ado oloro eleyii to ṣekupa gbogbo ẹbi mi."

Akọroyin BBC, Rushdi Abu Alouf sọ pe pẹlu ibanujẹ, ibẹru ati ibinu ni wọn fi n ko oku awọn eeyan jade lati ile mọṣuari niluu Gaza fún sinsin.

Aworan awon ile to dawo ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Pẹlu eeyan 704 ti ẹka eto ilera Hamas sọ pe wọn ku ni ọjọ kan ṣoṣo bayii, gbogbo eeyan to ti ku ni Gaza bayii ti di 5,791.

Ileeṣẹ ọmogun Israel ni oun ti fi ado oloro ba ọpọ ohun elo ẹgbẹ Hamas jẹ.

Ileeṣẹ naa sọ pe awọn fẹ wo ẹgbẹ Hamas palẹ patapata ni, at'awọn olori wọn tó fi mọ ẹka ileeṣẹ ologun wọn.

Olori ọmogun Israel, Ọgagun Herzi Halevi ni awọn ṣetan lati taa tan pẹlu Hamas ni gbogbo ọna.

Ọgagun Halevi sọrọ yii ki Hamas to fun awọn iyaagba meji ọmọ Israel ni ominira.

Aworan mama Israel to bo lowo Hamas

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹwẹ, igbe aye ko rọrun mọ fawọn ogunlende ni Gaza latari ọwọn ounjẹ, omi ati ibugbe fáwọn eeyan irinwo le ni miliọnu kan ti wọn ti sa kuro nile.

Ajọ iṣọkan agbaye UN ko ti le maa gbe ounjẹ wọ Gaza bo ti wù wọn nitori eto abo.

Ajọ WHO to n ri si eto ilera lagbaaye ti sọ pe awọn ohun elo ìtọjú awọn t'awọn gbe lọ sí Gaza kó tó lati lo.

Israel ti sọ pe ìwọnba nkan iranwọ ni ki wọn máa ko wọle tori ẹgbẹ Hamas le ji awọn nkan yii gbe ti wọn yoo si máa loo fawọn ọm'ogun wọn.