Mo la iná kọjá – Ìyá ẹni ọdún 85 tó jàjàbọ́ ní àhámọ́ Hamas sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdáǹdè

Yocheved Lifschitz

Iya agbalagba, ẹni ọdun marundinlaadọrun nni, Yocheved Lifschitz, to wa lara awọn ti awọn agbebọn Hamas ti orileede Gaza ko si ahamọ, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ni igbekun awọn agbebọn naa.

O ni iṣẹlẹ manigbagbe ayeraye lo jẹ fun oun.

Lifschitz sọ pe ọkada alupupu ni awọn agbebọn Hamas naa gbe wa ba oun ninu ahere Kibbutz, ti oun sa pamọ si, nibẹ lo sọ pe wọn ti ji oun gbe salọ.

O ni ẹnu ibode kan ni wọn fi ọkada alupupu to gbe oun gba wọle si Gaza, to si ni bi wọn ṣe wa ọkada ọhun jẹ ki oun farapa, ti oun si ni ọpọlọpọ apa ni ara.

Iya agbalagba naa ṣalaye siwaju pe agidi ni oun fi n mi ni gbogbo asiko naa.

Yocheved Lifschitz ati ọkọ rẹ

"Igi ni wọ́n fi n lu àwọn tí wọ́n jígbé"

O sọ siwaju pe ọpọlọpọ owo to le ni biliọnu ni ijọba Israel na lati fi mọ odi ibode wọn, ṣugbọn to sọ pe odi ti wọn mọ naa ko da awọn Hamas duro lati wọle.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Lifschitz wa lara awọn obinrin meji ti awọn Hamas yọnda, awọn si ni wọn yoo jẹ ẹnikẹta ati ẹni kẹrin ti wọn fi silẹ latigba ti wọn ti ji awọn to le ni igba gbe salọ.

Sharone to jẹ ọmọ Yocheved Lifschitz naa ran mama rẹ lọwọ lati ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lasiko ikọlu awọn Hamas si wọn ni Israel.

O fidi bi wọn ṣe gbe mama rẹ sori ọkada alupupu lọ, ati bi wọn ṣe n da apa sii lara, o ni wọn tun n la igi mọ ọn.

Sharone sọ pe igba to ya, wọn tun sọ pe ki mama oun fi ẹsẹ rin kilomita diẹ lori ilẹ tutu.

"Awa marunlelogun ni Hamas ko nigbekun lasiko kannaa"

Aworan Yocheved Lifschitz

O ni ẹrọ alatagba abẹ-ilẹ nla, eyi to da bi owu alantakun ni awọn Hamas n lo lati fi ṣiṣẹ buruku wọn.

Lifschitz ni wọn sọ fun oun pe: 'A nigbagbọ ninu Kuraani. A ko nii ṣe yin leṣe'

Sharone, ọmọ Lifschitz nigba to n tunmọ ọrọ mama rẹ sọ pe niṣe ni wọn gba aago ọwọ ati awọn ẹṣọ ara rẹ lasiko ti wọn n gbe e lọ.

Nigba ti Lifschitz bọ silẹ lori ọkada alupupu, awọn to lọ pade ẹ sọ fun un pe ‘gbagbọ ninu Kuraani’, eyi ti ko nii jẹ ki wọn ṣe leṣẹ.

Mama rẹ ati awọn mẹrinlelogun miran ni wọn ko lẹru lasiko kan naa.

O ni lẹyin bii wakati meji si mẹta, wọn ya awọn marun-un kuro lara wọn ninu Kibbutz Nir Oz, wọn si ko wọn lọ si inu yara ọtọ

O ṣalaye siwaju pe ẹṣọ, dokita ati olutọju iṣẹ pajawiri ni wọn

"Ori ibusun ni awọn ti wọn ko, n sun si"

Yocheved Lifschitz nigba to n sọ bi ipo ti awọn to wa ko wọn ṣe fi wọn si, o ni wọn ṣe imọtoto fun wọn.

O ni ori ibusun ti wọn gbe silẹ ni awọn sun si nibi ti wọn ko awọn si ni Gaza, ati pe ọjọ meji si mẹta ni awọn dokita maa n yọju si wọn lati wo ilera wọn.

Wọn tun ṣe itọju ọkan lara awọn ti wọn digun ko, to si farapa yannayanna nibi ijamba ọkada alupupo loju ọna Gaza.

Lifschitz so pe awọn oṣiṣẹ eto ilera maa n yọju si wọn lati fun wọn ni oogun lo, bẹẹ ni wọn tun n fun wọn l’awọn ohun ti wọn n fẹ.

Yocheved Lifschitz

"Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni wọn n ṣe akọsilẹ rẹ"

Yocheved Lifschitz sọ pe ẹṣọ kan ni wọn fi si iṣakoso eeyan marun-un, to si ni pe awọn ẹṣọ naa ni wọn n bojuto ohun ti onikaluku ba nilo.

"Kukumba ati Cheese la n jẹ"

Lifschitz tẹsiwaju pe ni gbogbo asiko ti awọn fi wa ninu ahamọ, kukumba ati cheese nikan ni wọn nfun wọn jẹ.

Sharone naa tun fi kun un pe ounjẹ kan ṣoṣo yi naa ni awọn to ko wọn sinu igbekun n jẹ pẹlu wọn.