Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàìjíríà tó kú ní Philippines, Nidcom, NANs yarí

Aworan Ikem, akẹkọọ Philipinness

Oríṣun àwòrán, X/@michaeljuola

Akẹkọọ ọmọ orilẹede kan ti orukọ rẹ n jẹ Ikem, to n ka iwe lorilẹede Philippines lo pade iku ojiji lasiko ti awọn ẹgbẹ ọmọ orilẹede China ṣekọlu si, ti wọn gba ẹmi rẹ.

Ọrẹ oloogbe lo gbe ọrọ sori ayelujara to si salaye ohun ti oloogbe naa lakọja ko to jade laye

Lọjọ Aiku, ọjọ Kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2023, ni ọkunrin kan loju opo ayelujara X, @michaeljuola gbe fọnran kan sita, eyi to safihan oku akẹkọọ ti ẹgbẹ ọmọ orilẹede China ṣekupa.

Michael ni awọn ẹgbẹ yii ti wọn sisẹ ni ile ounjẹ kan niluu Philippines, ti wọn si ṣekọlu si oloogbe naa, ti wọn fi nnkan di lẹnu, so ọwọ rẹ pọ, ki wọn to wa lu ni alubami, titi ẹmi fi bọ lara rẹ.

@michaeljuola yii lo ni oun jẹ ọrẹ timọtimọ fun oloogbe wa kesi ajọ NiDCON ati ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria lati da si ọrọ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

"Imọ isegun ni ọrẹ mi n kọ ni fasiti, ki awọn ọmọ China to de e lọwọ, fi nnkan di ni ẹnu, lu u titi to fi ku"

“Iwa buruku ni eyi, ti a ko si le tẹwọgba rgẹgẹ ẹgbẹ akẹkọọ. A n fi ki ijọba China lati fun ọla igbẹyin fun oloogbe naa.

“Wọn ni lati fi iku oloogbe ransẹ si orilẹede Naijiria lati fun ni ọla ikẹyin.”

”Ọrẹ mi, akẹkọọ ilera ara ti orukọ rẹ n jẹ Ikem, to n ka iwe rẹ ni Philippines ni awọn ẹgbẹ ọmọ China kan ṣekupa.

“Wọn de ọwọ rẹ papọ, fi nnkan fi ẹnu rẹ, ti wọn si lu ni alubami titi ẹmi fi bọ lara rẹ.

“A ko gbọdọ jẹ ki eyi lo bayii nitori ibaṣepọ to wa laarin Philippines ati orilẹede China.”

NiDCOM ni oun yoo ṣe iwadii iku akẹḱọọ Naijiria ní Philippines

Ajọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria loke okun NiDCOM, ti kede pe awọn yoo ṣe iwadii lori iku akẹkọọ Naijiria kan to n ka iwe lorilẹede Philippines.

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria ti n pe fun idajọ ododo lori iku oloogbe naa, ti orukọ n jẹ Ikem.

Lasiko to n sọrọ lori isẹlẹ naa, agbẹnusọ fun NiDCOM, Abdul-Rahman Balogun ni ajọ naa ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii lori ohun to fa iku akẹkọọ naa.

“Ọrọ to ti de ọdọ ajọ aṣoju Naijiria ni Philippines, sugbọn a ti kesi ọrẹ oloogbe to gbe ọrọ naa sita lori ayelujara lati kan si wa, ko si fun wa ni ẹkunrẹrẹ ohun to waye.

“Ajọ yii yoo bẹrẹ iwadii ni kiakia, ti gbogbo ohun to sokunkun yoo di han si gbogbo wa,”

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

A ko le foju fo ọrọ yii, a fẹ idajọ ododo- NANS

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiri NANS ti jẹ ko di mimọ pe o ṣe koko ki ijọba ṣe iwadii lori iwa nitori o jẹ to nuru jai, ti ko si ṣe foju fo rara.

Ninu ọrọ rẹ, igbakeji adari ile ẹgbẹ akẹkọkọ NANS, Elvis Ekudina kesi ijọba apapọ ati ẹka ijọba to n risi ọrọ oke okun lati dasi ọrọ naa, ki wọn si ri pe wọn fi oju aṣebi han sita.

“Iwa buruku ni eyi, ti a ko si le tẹwọgba rgẹgẹ ẹgbẹ akẹkọọ. A n fi ki ijọba China lati fun ọla igbẹyin fun oloogbe naa.

“Wọn ni lati fi iku oloogbe ransẹ si orilẹede Naijiria lati fun ni ọla ikẹyin.”