Èèyàn 5 kú, ọ̀pọ̀ farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní márosẹ̀ Eko sì Ibadan

Aworan ijamba ọkọ to waye ni opopona marosẹ Eko si Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adeniji Adejumo

Awọn arinrinajo marun un lo ti jẹ ipe Ọlọrun lasiko ti ijamba ọkọ kan waye ni agbegbe Kara lopopona marosẹ Eko si Ibadan lọjọ Aiku.

Bakan naa ni o le ni eeyan mẹdogun to farapa yanayana ninu ijamba yii, ti ọpọ si ti wa ni ile iwosan ni bi ti wọn ti n gba itọju.

Ọkọ akẹru nla pẹlu nọmba idanimọ KRD-12HGS ati ọkọ SUV akero lo kọlu arawọn ni opopona ọna to n kuro niluu Eko.

Ohun to sokunfa ijamba ni a ko ti le fidi rẹ mulẹ bayii.

Aworan ijamba ọkọ to waye ni opopona marosẹ Eko si Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adeniji Adejumo

Ijamba yii fa sunkẹrẹ fakẹrẹ yika opopona nipinlẹ Eko fun ọpọ wakati

Agbẹnusọ fun Ileeṣẹ Ijọba ipinlẹ Eko to n risi rina ọkọ, Adebayo Taofiq to ba Ileeṣẹ Iroyin abẹle The Punch sọrọ, fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si tun jẹ ko di mimọ iye eeyan to ba isẹlẹ naa ati awọn to farapa.

O ni, “Eeyan marun un lo ku nibi ijamba yii, to si le ni eeyan mẹdogun to farapa yanayana, ti wọn si ti wa ni ile iwosan fun itọju.

“Awa osisẹ LASTMA ati awọn osisẹ pajawiri mii ti wa ni bi ti ijamba naa ti waye.

“Lọwọ lọwọ bayii, a ko le fidi ohun to fa ijamba naa mulẹ, ohun akọkọ ti a kọkọ ṣe ni lati ṣe ni ki a dola ẹmi awọn eeyan, ka to gbe ọrọ naa lọ Ileeṣẹ ọlọpaa."

Ijamba yii fa sunkẹrẹ fakẹrẹ fun ọpọlọpọ wakati eyi to tan kakiri gbogbo agbegbe ipinlẹ Eko.

Aworan ijamba ọkọ to waye ni opopona marosẹ Eko si Ibadan.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adeniji Adejumo