Yánpọnyánrin bẹ́ sílẹ̀ níbi àjọ̀dùn àbáláyé, bàbá olóyè ṣíná ìbọn fún àwọn ọ̀dọ́

Aworan ọkan lara awọn ọdọ to fara gbọta

Oríṣun àwòrán, frcnpositivefm

Orin aa ri iru eyi ri lo gbẹnu t'ọmọde t'agba nilu Ọgbagi Akoko lẹyin ti baba oloye kan yin awọn ọdọ to n ṣe ọdun Ajagbo ninu ilu naa nibọn.

Ọdun Ajagbo ni awọn ọdọ maa n kopa ninu rẹ nipa kikọ orin lati fi bu abi tu aṣiri ẹnikẹni ninu ilu naa lai wo ipo abi aaye ti ẹni naa ba wa.

Orin yii ni awọn ọdọ n kọ lọ ti oloye kan, Moses Adeyemo, to jẹ Sajọwa ilu naa fi ṣina ibọn bolẹ.

Ọkan lara awọn ọdọ naa to fi ara pa to si n gba itọju nile iwosan, Eniola Jacob, wi pe ori lo yọ oun ti ibọn naa ko gba ẹmi oun.

Eniola ṣe alaye pe orin Ajagbo ni awọn kọ kọja lojude Oloye Sajowa to si yin awọn nibọn.

Eniola ti ko le moribọ ninu akọlu ibọn naa lo farapa pẹlu Timilehin Ogunyemi ni bi ọta ibọn ti oloye naa yin ṣe mu wọn lẹsẹ.

Ọlọpaa ni baba oloye naa ti wa ni ahamọ fun iwadii

Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba wi pe niṣe ni Oloye Sajowa yọ ibọn ati ada meji si awọn ọdọ naa lakoko ti wọn lọ ile ọba, ti meji ninu wọn si ṣeṣe.

Omisanya wi pe “ibọn agbelẹrọ mẹrin, ada meji ati ike ọta ibọn ‘cartridge’ mẹfa ti wọn ti yin ni a ri ko nibi ti Oloye Sajowa ti ṣe akọlu naa.

“Oloye Sajọwa ti wa lagọ wa ti iwadi kikun si n lọ lori iṣẹlẹ naa.”