Olókèméjì, ọdún tó so Krìstẹ́nì, Mùsùlùmí àti oníṣẹ̀ṣe pọ̀ nílù Ikare Akoko

Kabiyesi Ọwa-Ale ti ilu Ikare, Ọba Adeleke Adegbite-Adedoyin, lo ti wi pe ori oke ti wọn ti n ṣe ọdun Olokemeji ko nii pẹ di oriko tawọn arinrinajo afẹ lagbaye yoo maa peju wa, paapaa julọ lakoko ọdun ọun.
Ọba Adedoyin lo sọ ọrọ yii nibi ayẹyẹ ọdun olokemeji takọ-tabo to waye lọjọ Abamẹta.
Lakoko to n ṣe alaye e pataki ọdun ọun fun BBC News Yoruba, Kabiyesi Ọwa-Ale wi pe “gbogbo aye lo maa n pe Ikare lọmọ Olokemeji takọ-tabo to tumọ si oke onibeji to ni akọ ati abo, ori oke ọun ni a wa yii.
“Itan fi ye wa pe ni igba iwaṣẹ, ogun awọn Tapa wọ ilu Ikare wa, leyi to mu ki awọn araalu o sa gun ori-oke yii lati maa gbe ti wọn si ṣẹgun awọn Tapa lati ibẹ.
“Lati igba naa wa ni a ti maa n gun oke yi ni iranti oore to ṣe fun wa.
“Lati origun mẹrẹrin agbaye ni awọn eeyan ti maa n waa bawa ṣe ọdun yi paapaa julọ lati ilẹ gẹẹsi ati ilẹ Amẹrika.
“To ba ti ku ọsẹ bii meji ni gbogbo ile itura ti maa n kun fun alejo, koda awọn miran ko lee wa lọdun yii tori ko si yara mọ ni ile itura lati de si.

Ọbalaye naa ni ọna ati pawo wọle lo jẹ fun awọn olugbe ilu Ikare ati fun ijọba.
“O ṣeni laanu pe a ko gbaju mọ awọn aṣa ajogunba wa daadaa lorilẹ ede Naijiria, ti ko si boju mu to.
“To ba di ọdun to n bọ, ileeṣẹ ijọba apapọ to n moju to aṣa ati irinajo afẹ yoo wa pẹlu wa nibi nitori pe o ni ibi taa ti ba ọrọ de lori gbigbe ọdun yii larugẹ ju bayi lọ.
“Ọpọlọpọ awọn to n gbe aṣa Yoruba ga bii Iba Gani Adams lo ran awọn aṣoju wa lati wo bi wọn yoo ṣe fi ọwọ sowọpọ pẹlu wa fun agbega ọdun yii ti yoo mu ko tunbọ yaayi sii.”
Awọn araalu ko fi ti ẹsin ṣe nibi ọdun Olokemeji

Awọn olugbe ilu Ikare lo tu yaya jade lati kopa nibi ọdun naa lai fi ti ẹsin ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹsin Kristẹni lo n lo ori oke naa fun ijọsin nitori pe o jẹ aaye ti Mose Orimolade Tunolase, to jẹ oludasilẹ ijọ Kerubu ati Serafu, ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ, ati musulumi ati oniṣẹṣe lo ba wọn peju sibi ọdun naa.
Imaamu adugbo Ọkọ̀run nilu Ikare, Muhammad Salis, juwe ọdun naa bii ohun to so gbogbo ojulowo ọmọ Ikare pọ.
Salis wi pe “awọn baba nla wa lo bẹrẹ ọdun yii, ti Kabiyesi Adedoyin si waa ba wa fẹẹ loju.

Awọn olugbe ilu Ikare lo tu yaya jade lati kopa nibi ọdun naa lai fi ti ẹsin ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹsin Kristẹni lo n lo ori oke naa fun ijọsin nitori pe o jẹ aaye ti Mose Orimolade Tunolase, to jẹ oludasilẹ ijọ Kerubu ati Serafu, ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rẹ, ati musulumi ati oniṣẹṣe lo ba wọn peju sibi ọdun naa.
Imaamu adugbo Ọkọ̀run nilu Ikare, Muhammad Salis, juwe ọdun naa bii ohun to so gbogbo ojulowo ọmọ Ikare pọ.
Salis wi pe “awọn baba nla wa lo bẹrẹ ọdun yii, ti Kabiyesi Adedoyin si waa ba wa fẹẹ loju.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Niran Adeyemo
Ipalẹmọ ti n de oju ogongo bayii nilu Ikare Akoko pẹlu bi ọdun Oloke Meji ti ṣe ku dẹdẹ.
Ajọdun yi to ṣe pataki si aṣa ati iṣẹṣe awọn araalu yi a maa waye lọdọọdun ti wọn a si maa fi ọjọ mẹrin ṣe ajọdun naa.
Ẹni ti ọdun yi ba ti ṣoju rẹ ri yoo ri bi awọn araalu ti ṣe n yayọ tilu tifọn ninu aṣ funfun ti gbogbo ilu a si maa rọ kẹkẹ.
Ọdun yi ṣe pataki si awọn araalu Ikare Akoko tori o jẹ ọna lati maa fi ṣe iranti itan bi awọn babanla wọn ti ṣe ṣẹ wa ati pataki ori oke ti wọn mu gẹgẹ bi aaye ti wọn tẹdo si.
Ki ni pataki ọdun yi, itan wo lo rọ mọ bawọn eeyan Ikare Akoko ti ṣe de aaye ibi ti wọn wa lonii ati pe awọn eewọ wo lo so mọ ọdun yi?
Gbogbo awọn nkan wọnyi la o gbe yẹwo ninu apilẹkọ yii.
Itan iṣẹdalẹ ilu Ikare Akoko
Gẹgẹ bi itan taa ri ka, Agba Ode ọmọ-ọba lati Ile Ife lo tẹ Ikare Akoko do.
O si jẹ ọkan lara awọn ọmọ ọmọ Oduduwa.
Nigba to ri pe oun ko ni le ri ade gba tori ọjọ ori rẹ lo ba fi gbera kuro lati lọ tẹ ilu tiẹ naa do.
O ṣidi kuro ni Ile Ife lto si mori le ọna pẹlu awọn Oloye rẹ bi Olona Olokoja Akuko,Oloyinmo ati awọn mii.
Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu itan wọn difa ki wọn to gbera ti Ifa si juwe ori oke kan pe ibẹ ni ki wọn tẹdo si.
Apejuwe kan pataki ti wọn fi n tọ aaye yi bọ wa ni pe bi wọn ba de ibi oke yi, o jẹ oke meji to wa lẹgbẹ ara wọn bi ọkọ ati iyawo.
Bẹẹ ni Ifa juwe fun wọn pe omi ṣiṣan kekere kan wa lori oke yi.
Titẹdo ti Owa-Ale ati awọn eeyan rẹ tẹdo si ori oke yi mu ki wọn maa pe oke naa ni ori oke Owa Ale.
Omi ṣiṣan to wa lori oke naa a si maa jẹ ''omi atan'' tori pe omi yi, tojo tẹrun ko si igba to maa n gbẹ.
Awọn eewọ to rọ ọdun Oloke Meji ni Ikare
Aaye ọwọ ni ori oke toko taya yi ti o si ni awọn ofin to de wiwa sibẹ.
Awọn eewọ kan wa lasiko ọdun yi to ṣe pataki ki awn to ba fẹ kopa ninu rẹ ṣe akiyesi wọn.
Ninu awọn eewọ wọn yi ni pe:
- Ma ṣe sunmọ ori oke yi ayafi to ba wọ aṣọ funfun lọjọ kọkanlelogun ti adura yoo waye lori oke yi.Eewọ ni lati mu ohunkohun to jẹ alawọ pupa wa sibẹ.
- Ma ṣe sunmọ ori oke yi to ba ni ibalopọ loru ọjọ to ṣaaju ọ́dun yi paapa ti o ko ba tii wẹ ẹgbin ibalopọ kuro lara rẹ.Ko si laburu lati ni ibalopọ.Wiwẹ ẹgbin kuro lara lo ṣe koko.
- Ma ṣe sunmọ ori oke yi to ba jẹ eeyan to n ba ọkọ tabi iyawo oniyawo lajọṣepọ.Bi o ba kundun iru iwa yi, ri wi pe o tọrọ aforijin kete ti o ba gbẹsẹ le atẹgun akọkọ ti o ma gun de ori oke yi ki o baa le ri oju aanu gba lori oke naa.
- Yago fun mimu ọti tabi oogun oloro to le mu ki ooyi maa kọ ẹ lori oke yi.
- Ri wi pe o wa si ori oke yi pẹlu ọkan mimọ ti ko ro aburu si ẹlomiran.Adura rẹ ko ni tete gba ti o ba ni ọmọlakeji rẹ sinu.
- Awọn igbimọ alakoso ori oke yi ko ni jẹ ki o gun ori oke hun too ba wọ aṣ mi yatọ si aṣọ funfun.
- Bẹẹ, bi wọn ba kẹfin pe o mu ọti lowurọ ọjọ yi, won o ni jẹ ki o ba wọn gun orioke adura yi












