Ọdún Orò wáyé nílẹ̀ Benin f'ọmọ Yorùbá, wọ́n bẹ̀bẹ̀ fún àgbéga Ìṣẹ̀ṣe

Àkọlé fídíò, Oro Festifal In Benin Republic: Àwọn Olórò bẹ̀ àwọn ọmọ Yorùbá láti tẹ́wọ́gba Ìṣẹ̀ṣe
Ọdún Orò wáyé nílẹ̀ Benin f'ọmọ Yorùbá, wọ́n bẹ̀bẹ̀ fún àgbéga Ìṣẹ̀ṣe

Ọjọ nla ni ọja ti wọn se ọdun Oro nilu Sakete, lorilẹede Republic of Benin.

Ọdun yii si lo maa n ko apapọ awọn ọmọ Yoruba to wa lorilẹede naa papọ lọdọọdun.

Ọdọọdun ni wọn maa n bọ oro nilu naa nibi ti wọn ti maa n sadura fun gbogbo awọn ọmọ ilu naa.

Bakan naa ni wọn tun maa n lo ọdun naa lati sọ awọn ohun ti wọn n fẹ fun ijọba, ti wọn si tun maa n ni asọyepọ gidi pẹlu rẹ.

Awọn Oloro

Lasiko ọdun Oro lọdun yii, se lawọn ero pe biba silu Sakete lati se ọdun naa.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ awọn Oloro naa ni asa Isẹse dara, ti ko si si idile ti Iṣẹṣe ko si.

Wọn wa rọ awọn ọmọ Yoruba nile loko lati mase kẹyin si asa ilẹ Yoruba, paapaa Isẹse.

Bi ọdun oro naa se lọ nilu Sakete ree: