Bí Lateef tó jẹ́ Mùsùlùmí ṣe wọlé sí àwọn òbí mi lára tí wọ́n gbà kó fẹ́ mi rèé – Bimpe Adedimeji

Oríṣun àwòrán, The Nzes
Tọtọtaya gbajugbaja oṣere, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Adedimeji ti sọ ọrọ jade lori ohun ti oju awọn mejeji ri lọdọ awọn obi Adebimpe ki wọn to gba ko fẹ ẹ gẹgẹ bi aya rẹ.
Idi si ni wipe ẹsin ọtọọtọ ni awọn oṣere mejeji yii n ṣe ṣaaju ki wọn to yo ifẹ ara wọn ti wọn si gba lati fẹ ara wọn.
Lateef ati Adebimpe n fọrọ jomi toro ọrọ lori eto igbohunsafẹfẹ kan, "The Nzes" lori ayelujara nibi ti wọn ti n dọwẹkẹ pẹlu iranti didun nipa asiko ti wọn pade ara wọn.
Gbogbo eeyan n ki mi, amọ Bimpe duro, o n wo lai ki mi – Lateef

Oríṣun àwòrán, The Nzes/Youtube
Lateef Adedimeji ni ori itage ere kan ni oun lọ ti ọpọ eeyan to wa nibẹ n ki oun amọ ti Adebimpe kan n wo oun bii pe ta leleyii, “lẹyin naa ni mo bere pe ta ni ọmọbinrin to duro ti ko le kii’yan yii, lo ṣẹ wa ki mi”.
Lateef ni lẹyin igba akọkọ yii ni Bimpe kan si oun pe o fẹ ki oun kopa ninu fiimu rẹ toun si ni “ni tani, ṣe ọmọ ti ko le ki eeyan yẹn, ẹgbẹrun lọna igba naira ni yoo san”, bo tilẹ jẹ pe o ni owo naa pọ amọ oun yoo san an.
Awọn obi mi yari bi wọn ṣe gbọ orukọ ẹni ti mo fẹ mu wale lati fẹ - Adebimpe
Ki lawọn ipenija tẹẹ koju?
“Nigba ti Lateef ni ṣe mi o ni fẹ iwọ ọmọ yii bayii, mo sọ fun pe rara o, iwọ too jẹ musulumi, emi si ti jẹ Kristẹni ni gbogbo aye mi, mi o tilẹ ni ọrẹ musulumi kankan”.
O lagbara gan pẹlu awọn obi mi ni o, nigba ti mo sọ fun mama mi pe o fẹ fẹ mi, haa, wọn ni lailai.
Iya mi ko si ni Naijiria nigba naa, baba mi ko tilẹ ni gba, tori naa o jẹ ipenija nla fun mi.”
Adebimpe ṣalaye pe awọn obi ti Lateef ko tilẹ yari rara amọ baba oun ni “laye laye, ọmọ musulumi yẹn, rara o, oo le fẹ o.
Bawo lẹ ṣe wa mu ori wọn walẹ?

Oríṣun àwòrán, The Nzes
Emi kẹ, emi lọ sile wọn o, mo lọ sibẹ, nigba to sọ fun mi pe awọn obi sọ pe kini kan, mo ni ni kini, ṣe mo le ri wọn, jẹ ki n lọ sọ nnkan ti wọn fẹ fun wọn.”
Lateef ati Adebimpe ni koda igbeyawo ṣọọṣi ati ti Musulumi lawọn ṣe ti awọn Pasitọ ati Imaamu ṣe ohun to yẹ amọ ọjọ kan ṣoṣo naa ni awọn ṣe e, idi si ni wipe, ẹsin jẹ ohun ti eeyan ti ṣe fun gbogbo ọjọ aye rẹ latẹyin wa.
Bawo wa ni iriri igbeyawo pẹlu bi awọn kan ṣe ro pe ẹ n dibọn pẹlu ere ifẹ yin ni?
Lateef Adedimeji ati iyawo rẹ pa ẹnu pọ sọ pe ko si igbeyawo ti ko ni ipenija tirẹ o tori pe kii ṣe abẹ obi kan naa ni eeyan mejeji ti jọ dagba pọ.
“Igbeyawo dara pupọ, mi o mọ idi ti awọn eeyan fi maa n bẹru igbeyawo. Ohun to ṣẹlẹ ni pe bi awọn eeyan ba ri igbeyawo to dara, wọn kii gbagbọ, wọn ma n ro pe ẹ n ṣe e tori oju aye ori ayelujara ni, wọn maa ni irọ ni tabi ki wọn tilẹ maa reti nnkan aburu ko ṣẹlẹ, bii ki igbeyawo naa tuka. Adebimpe sọ bẹẹ, o ni o kan jẹ pe nnkan aburu lo maa n tan ka ju nnkan rere lọ.
Ọkọ rẹ fi kun un pe ko si igbeyawo ti ko lee yọri si rere, amọ eeyan kan ni lati kọ bi wọn ṣe n ba ara ẹni gbe pọ ni.
“Ọpọ ọdọ ni ko tilẹ le fara daa fun ọrẹ wọn depo depo ẹni ti wọn ma maa ba gbe lojoojumọ gẹgẹ bi iyawo tabi ọkọ. Igba mii waa wo iyawo rẹ pe ṣe emi ni mo fẹ ẹ ṣa pẹlu awọn iwa kọọkan amọ waa mọọmọ sọ fun ara rẹ ati ẹnikeji rẹ pe ko si bo ṣe fẹ buru to, a o ja ija to le, a o si jọ pari rẹ, ko si ibi kankan ti a n lọ, a jọ lẹpọ ni”.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Fun igbeyawo to ti le ni oṣu mejidinlogun bayii, bawo lẹ ṣe n bori ija?
“Ni aarọ ọjọ igbeyawo wa, nigba ti a n gba idanilẹkọ, wọn ni ki awa mejeji kọ ohun ti a n reti lọdọ ara wa ki a si ṣe pasiparọ rẹ ka jọ wo o, wọn wa sọ fun wa pe, iṣẹ akanṣe tirẹ niyẹn, iṣẹ akanṣe tirẹ naa niyẹn, ẹ maa yẹ ẹ wo loorekoore, bi ẹ ba wa ri i pe ẹni kan ko ṣe ohun to jẹ ireti to wa ninu iwe naa, ẹ pe akiyesi ara yin sii lati wo o pe “wa o, iwọ lo fi ọwọ ara rẹ kọ ọ, wa wo o, mi o fẹ wahala o!” (Gbogbo wọn ati atọkun bu sẹrin).
Lateef ni: “Igba ti iyawo mi ba ti ṣe ohun ti mi o fẹran, maa bii lere pe igba wo lo yẹ beba rẹ wo gbẹyin, a si beere pe ki ni oun tun ṣe o, maa ni ko mu beba jade maa si ni ka nọmba bayi bayi koo wo o nibẹ, a wa ṣe yẹyẹ pe “ṣe ọrọ niyẹn”.
Ẹsin Islam ati Kristẹni
“Ni temi, ko yẹ ki nnkan to le wa ninu ọrọ ẹsin. Ko si nnkan to n jẹ mimu ni pẹlu ipa ninu ẹsin Islam.
Too ba nifẹ eeyan kan pẹlu gbogbo nnkan to n ṣe ati ẹsin rẹ, ko saburu nibẹ bi o ba fi ṣe ọkọ tabi aya.
Musulumi ni mi ṣugbọn mi o lodi si ẹsin kankan, nitori o o nilo rẹ. Ni temi ẹsin to dara ju ni ero ọkan rẹ, tori naa too ba ni o ko le fẹ eeyan kan tori ẹsin rẹ, wa a ko ara rẹ sinu wahala o, tori naa, kii ṣe dandan. Nnkan too ni lati gbe yẹwo nipa eeyan too fẹ fẹ pọ, ọkan ninu rẹ lasan ni ẹsin tori naa too ba ti wo gbogbo nnkan to tẹ ọ lọrun, ẹsin yoo tẹle e.”
Lateef ni adehun ni, tẹẹ le jọ joko lati sọ eyi to wu ẹ lati ṣe.

Oríṣun àwòrán, Emiralty Africa















