Wo ohun tí Oluwo sọ nípa Soun Ogbomoso tuntun, Ọba Afolabi Ghandi Olaoye

Oluwo of Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ki Soun ti ilu Ogbomosho tuntun, Ọba Afolabi Ghandi Olaoye, ku oriire.

Oluwo lo fi ọrọ ikinni na lede ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Alli Ibraheem, fi lede, eyii to fi ṣọwọ si BBC Yoruba.

Gẹgẹ bii ohun ti Oluwo sọ, ibukun nla ni iyansipo Soun tuntun naa jẹ fun gbogbo awọn lọbalọba nilẹ Yoruba.

Oluwo tun rọ gbogbo awọn ọmọ ọba to n ba Ọba Afolabi Ghandi Olaoye du ipo naa tẹlẹ ki wọn gba fun Ọlọrun, ki wọn si fọwọsọwọpọ pẹlu ori ade tuntun naa fun ilẹsiwaju ilu Ogbomosho.

O ni “Mo ba Soun Ogbomosho tuntun, Oba Afolabi Ghandi yọ lori aṣeyọri rẹ lati gun ori itẹ awọn babanla rẹ.”

“Mo rọ awọn to n ba du ipo naa ki wọn gba fun Olodumare nipa fifọwọsowọpọ pẹlu Soun lọna ati mu itẹsiwaju ba ilu Ogomosho, nitori Ọlọrun nikan lo n fi eeyan joye.”

Oluwo pari ọrọ rẹ pẹlu ọrọ ikini si gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn afọbajẹ fun yiyan ẹni to tọ sori oye.

Lẹyin naa lo ṣadura pe ki Ọlọrun ran Soun tuntun naa lọwọ lati tukọ ilu Ogbomosho de ebute ogo.

Àwọn afọbajẹ fi Afolabi Ghandi Olaoye jẹ Soun Ogbomoso tuntun

Awọn afọbajẹ fi Ghandi jẹ Soun

Gbogbo etutu ti pari bayii nidi fifi ọba tuntun, Afolabi Ghandi Olaoye jẹ Soun tilẹ Ogbomoso tuntun.

Awọn igbesẹ fifi ọba tuntun jẹ naa lo waye ni aafin Soun nilu Ogbomoso.

Soun tuntun, to de si aafin Ogbomoso ni aarọ ọjọ ẹti, ni awọn afọbajẹ ki kaabọ si aafin naa, ti wn si bẹr igbesẹ fifi jẹ ọba.

Niwaju aafin naa ni wọn ti gbe ọwọ le lori, ti wọn si se awn etutu to yẹ.

Akọroyin BBC to wa ni aafin Soun salaye pe ọba tuntun naa ti kuro ninu aafin naa lati tẹsiwaju pẹlu awọn igbesẹ to ku.

Bakan naa, a gbọ pe ayẹyẹ ikije ọba tuntun naa yoo waye ni Ọjọ Alamisi to n bọ.

Lẹyin eyi, ayẹyẹ gbigba ọpa asẹ lo ku fun ọba Afolabi Ghandi Olaoye naa.

Aafin Soun
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin to n tẹ BBC Yoruba ni yajo yajo ti fi to wa leti pe Ọmọọba Afolabi Ghandi Olaoye ti wọnu aafin Soun ti Ogbomoso bayii.

Ọmọọba Ghandi lo de asinu aafin naa ni deede aago mẹsan abọ owurọ ọjọ Ẹti.

A gbọ pe dide rẹ sinu aafin lo wa lati bẹrẹ awn igbesẹ to yẹ ko se nilana asa ibilẹ Yoruba.

Amọ BBC ko tii fidi rẹ mulẹ boya Ọmọọba Olaoye yoo se etutu oye jijẹ ni ipebi ggẹ bi ilana ọba jijẹ nilẹ Yoruba.

Lopin ọsẹ to lọ ni gomina Makinde kede pe oun ti buwọlu iyansipo Ọmọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹgẹ bii Soun tuntun fun ilu Ogbomoso.

Bi gomina Makinde si se kede iyansipo oriade tuntun fun ilẹ Ogbomosos naa, ni awuyewuye ti n waye lati tako iyansipo ọhun.

Bẹẹ ba gbagbe, ile ẹjọ giga kan nilu Ibadan ti pasẹ ni Ọjọ pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ko gbọdọ pe ọpa asẹ fun Soun tuntun to sẹsẹ yan naa.

O ni asẹ ọhun gbọdọ mulẹ titi ti oun yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti ọmọọba miran, Kabiri Olaoye pe lati tako iyansipo Ghandi Olaoye bii Soun Ogbomoso tuntun.

Aafin Soun
Àkọlé fídíò, Kehinde Ahmed: Èdè Lárúbáwá ni mò ń kọ́ báyìí láti lọ fi kọ́ṣẹ́ dókítà ní Egypt

Kabir Olaoye pe Ghandi Olaoye lẹ́jọ́ lórí ipo ọba Soun Ogbomoso, iléẹjọ́ fòfin de ìwúyè

Aworan Afolabi Ghandi Olaoye

Oríṣun àwòrán, Afolabi Ghandi Olaoye/Facebook

Lẹyin ti gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti buwọlu iyansipo Ọmọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹgẹ bi Soun Ogbomoso tuntun, ile ẹjọ giga kan nipinlẹ naa ti paṣẹ pe Makinde ko gbọdọ gbe ọpa aṣẹ fun Ghandi gẹgẹ bi ọba.

Ile ẹjọ naa paṣẹ fun gomina ipinlẹ Oyo, agbẹjọro agba ati kọmiṣọnna ijọba ibilẹ ati oye jijẹ pe ki wọn semẹdọ naa titi ti idajọ ẹjọ to wa nile lori ọrọ oye yoo fi waye.

Ọjọbọ ni adajọ K.A. Adedokun paṣẹ yii nigba ti o n dajọ ti ọkan lara awọn to n du oye Soun Ogbomoso, Ọmọba Kabir Olaoye gbe wa sile ẹjọ.

Adajọ Adedokun ni ẹjọ ti pe lẹṣẹ nlẹ Ọmọba Kabir Olaoye

Bakan naa ni adajọ tun paṣẹ pe Ghandi gan an ko gbọdọ ri ara rẹ gẹgẹ bi Soun tuntun, bẹẹ ni ko gbọdọ lọ si ibi ayẹyẹ kankan lati gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi ọba titi idajọ yoo fi waye lori ẹjọ to wa nlẹ.

Adajọ Adedokun ni lẹyin ti oun ṣe agbeyẹwo awijare Abiodun Ogunjimi to jẹ agbẹjọro Ọmọba Kabir, oun ri pe ẹjọ ti onibara rẹ pe lẹṣẹ nlẹ.

Ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kejila oṣun kẹsan an ọdun yii.

Awọn miiran ti ẹjọ naa kan ni ajọ to n ri si ọrọ oye lapa ariwa ilu Ogbomoso, Ọmọba Amos Olaoye, Mogaji ẹbi Olaoye, Oloye S.O. Otolorin, Areago ilu Ogbomoso ti o tun jẹ alaga awọn afọbajẹ, Oloye Tijani Abioye, Baara ilu Ogbomoso, Oloye David Adeniran, Ikolaba ilẹ Ogbomoso ati Oloye Yusuf Rasaki Oladipupo, Abese ilẹ Ogbomoso.

Lopin ọsẹ to lọ ni gomina Makinde kede pe oun ti buwọlu iyansipo Ọmọba Ghandi gẹgẹ bii Soun tuntun ilu Ogbomoso