Ikọ̀ agbébọn ẹlẹ́sìn Islam kọlu ibùdó ológun àti ọkọ̀ ojú omi ní Mali, èèyàn 49 kú

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba fidiẹ lorilẹede Mali ti kede pe awọn ọmọ ikọ alakatakiti ẹlẹsin Islam ti kọlu ọkọ oju omi kan lẹkun ariwa-ila oorun Mali, ti wọn si gbẹmi eeyan mọkandinlaadọta, o kere tan.
Bakan naa ni iroyin ọhun sọ pe awọn agbebọn ẹlẹsin naa tun kọlu ibudo awọn ologun, wọn pa sọja mẹẹdogun amọ ti agbebọn to le ni aadọta si jade laye.
Idi si ree ti ijọba orilẹede Mali fi kede ọfọ ọlọjọmẹta yika orilẹede naa.
Bi o tilẹ jẹ pe ikọ ologun aladani Wagner lati orilẹede Russia ti kede saaju pe oun ti bori ikọ alakatakiti naa amọ sibẹ kaka ki ewe agbọn wọn dẹ, ko ko lo n le si.

Oludari ọkọ oju omi naa ni ado oloro mẹta ni wọn yin mọ ẹnjini ọkọ oju omi naa
Lati ipari osu to kọja ni wọn ti ti ọna to lọ si Timbuktu, ti aimọye ikọlu mii si tun ti waye sawọn ọkọ to n rin loju popo.
Bakan naa ni awọn agbebọn yii tun kọlu ọkọ oju omi to n rinrinajo lori odo Niger lati ilu Gao lọ si Mopti.
Bẹẹ ni wọn tun kọlu ibudo awọn ologun kan to wa ni Bourem lagbegbe Gao.
Ileesẹ ologun lorilẹede Mali kede lori ayelujara pe deedee aago mọkanla alẹ lawọn alakatakiti ẹlẹsin Islam naa kọ lu ọkọ oju omi ọhun.
Oludari ọkọ oju omi naa, Comanav sọ funlesẹ iroyin AFP pe ado oloro mẹta ni wọn yin mọ ẹnjini ọkọ oju omi naa.
Ori odo Niger naa si ni wọn ti fọn ọkọ oju omi naa si wẹwẹ, tawọn ologun si lọ ko awọn ero ti ori ko yọ kuro nibẹ.















