Ọkọ àti ìyàwó ọ̀sìngín dàwátì bí omíyale ṣe gbé ilé ìgbafẹ́ lọ leti òkun

Àkọlé fídíò, Greek floods: Drone footage shows scale of destruction

Ọkọ atiyawo aṣẹṣẹgbe kan ti wọn n ṣe isinmi igbadun lẹyin iyawo ti di awati nilẹ Greece lẹyin ti ojo arọọrọda kan eyi to di omiyale gbe odidi ile ti wọn wa ninu rẹ lọ.

Ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri sọ fun BBC pe awọn n wa awọn lọkọ-laya ọhun ati ọpọlọpọ eeyan mii to dawati pẹlu.

O le ni dọsiini eeyan ti wọn ti kede pe wọn gbẹmi mi lati igba ti Iji lile ti wọn n pe akanṣe orukọ rẹ ni “Storm Daniel” kọlu Greece, Turkey ati Bulgaria ni ọsẹ yii.

Awọn ọkọ ati iyawo ara ilẹ Austria naa pinu lati lọ jẹ igbadun lẹyin eto igbeyawo wọn ninu ile onilẹ kan ti wọn gba lẹyin eyi si ni ojo lile wọ gbogbo aarin gbungbun Greece lọ, onile naa, Thanasis Samaras sọ bẹẹ.

Amọ, ile igbafẹ naa to wa ni eti omi okun Potistika, lẹgbẹ oke Pelion fara kasa omiyale to wọ ọ lọ sinu okun, o sọ fun BBC.

Onile yii atawọn mii ti kuro lọ si apa ibi to ga soke wọn si tun gba awọn tọkọ taya naa nimọran lati ṣe ohun ti awọn naa ṣe.

“Iṣẹlẹ naa buru jai. O le gan lati pinu ohun ti eeyan yoo ṣe niru akoko bayii,” Ọgbẹni Samaras sọ bẹẹ.

O fi kun un pe awọn ọkọ ati iyawo yii to wa lati ilu Graz ni ilẹ Austria ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo ko i pẹ ni ti wọn si wa fun isinmi nibẹ.

Omiyale ni Greece

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ki ni ijọba ti ṣe?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ikọ adoola pajawiri ni awọn ni awọn oṣiṣẹ awọn ni agbegbe naa to n wa awọn eeyan to dawati to fi mọ awọn to ṣẹṣẹ gbeyawo yii.

Awọn agbegbe kan ni ilẹ Greece ni iriri ojo to to 800mm (31.5 inches) laipẹ yii – eyi to ju ohun ti wọn tii ri ri lọ ni gbogbo ọdun kan.

Olootu ilẹ Palamas, Giorgos Sakellariou rawọ ẹbẹ alagbara kan lori ẹrọ amohunmaworan Greek TV pe “awọn eeyan ti ha sinu ile wọn ti wọn si n koju ewu lọwọlọwọ to fi mọ awọn to n ku sinu omi.”

Fọnran kan ṣafihan ọkọ baalu ikọ adoola pajawiri to n gbe awọn eeyan to ha sinu omi ati ori orule ile.

Awọn apa ibomi ti ikọlu yii ba ni Athens ati Erekusu Skiathos nibi ti ọpọ awọn arinrinajo igbafẹ naa ha si.

Adari ilẹ naa, Kyriakos Mitsotakis ti wọgile eto ijọba kan to yẹ ko waye ni opin ọsẹ gẹgẹ bi wahala naa ṣe tun n peleke sii. O ti n ṣeto lati ṣe ibẹwo si awọn ibi ti ikọlu de ba bayii.

Omiyale alagbara yii, Storm Daniel ti n kọlu Greece, Turkey ati Bulgaria lati ọjọ Aje ọsẹ yii to si le ni eeyan dọsiini kan ti a gbọ pe o ti ba iṣẹlẹ naa lọ, mẹrin ninu wọn wa ni Greece.

Awọn onimọ nipa sayẹnsi oju ọjọ ti kilọ pe ayipada oju ọjọ lagbaye n peleke sii ki awọn orilẹede si ṣọra.

Maapu Greece